Ìlù Sàtọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
African drum with Sekere

Ìlù Sátọ́ jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ pàtàkì ní ìlú Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Ó jẹ́ ìlú kan tí ó gbajúmọ̀ jùlọ láwùjọ àwọn ẹ̀yà Ògù ní Badagry. Ìlú Sátọ́ jẹ́ ìlù méjì tí ó tóbi tí gíga rẹ̀ ju Ènìyàn lọ ní ìdúró. Ó jẹ́ ìlú tí wọ́n fi ń ré ibi dànù láyé àtijó. Ṣùgbọ́n lóde òní, wọ́n tí ń lu ìlù Sátọ́ níbi àwọn ayẹyẹ pàtàkì. [1] Ìlù Sátọ́ jẹ́ ìlú tí ó ga jùlọ ní àgbáyé. [2]

Pàtàkì Ìlù Sátọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sátọ́ jẹ́ ìlú tí wọ́n fi ń ṣe ètùtù láyé àtijó. Wọ́n gbàgbọ́ pé dídún ìlù Sátọ́ máa ń ré ibi dànù. Àwọn onílù yìí gbàgbọ́ pé ìró ìlú yìí máa ń jẹ́ kí àwọn èmi burúkú tí ó máa ń fa àjàkálẹ̀ àrùn. Láyé àtijó, ó ṣọ̀wọ́n kí ìlù Sátọ́ tó jáde, àyàfi tí wọ́n bá ní ètùtù tàbí ọdún ìbílẹ̀ kan láti ṣe, ṣùgbọ́n lóde òní, wọ́n tí ń lu ìlú Sátọ́ ní ibi ayẹyẹ lóríṣiríṣi.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]