Òjíṣẹ́ Ìṣẹ̀dálẹ̀
Ìrísí
Olubunmi Olukanni tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Òjíṣẹ́ Ìṣẹ̀dálẹ̀ jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, òǹkọ̀wé, onílù, olórin, alágbàwí[1] àti òṣẹ̀rékùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà láti dẹ́kun ìlọwọ́sí àwọn aláwọ̀ funfun, tí ó sì tún nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan ìbílẹ̀ lọ́nà ìgbàlóde.[2]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó ṣiṣẹ́ lórí ìtúpalẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ewì Wọlé Sóyinká, èyí tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Àbíkú".[3][4] Látàri jíjẹ́ alágbàwí, wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu kíkó ọkàn àọn ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lẹ́rú. Ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ògbufọ̀ àti tapítà fún bí i ogún ọdún, bẹ́ẹ̀ sì ni ó lọ́wọ́sí ìgbé àṣà àti èdè Yorùbá lárugẹ.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Nation, The (2018-07-24). "Yoruba lecture holds at OAU". The Nation Newspaper. Retrieved 2024-10-24.
- ↑ urbanlifeng.com https://urbanlifeng.com/default_main/index.php/society/2231-meet-ojise-isedale-us-based-yoruba-cultural-champion-to-storm-oau-as-keynote-speaker-august-14. Retrieved 2024-10-24. Missing or empty
|title=
(help) - ↑ "Idi ti mo fi ṣatupalẹ ewi Wọle Soyinka, Abiku si ede Yoruba- Ojiṣẹ Iṣẹdalẹ". BO SE RI (in Èdè Latini). 2024-10-14. Retrieved 2024-10-24.
- ↑ "Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba.". GBELEGBỌ. 2024-10-14. Retrieved 2024-10-24.
- ↑ Diary, Africa (2024-10-14). "Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, 'Abiku' si ede Yoruba". a. Retrieved 2024-10-24.