Ẹ̀fọn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ẹ̀fọn
Mosquito 2007-2.jpg
A female Culiseta longiareolata
Conservation status
Secure
Scientific classification
Kingdom: Animalia
Phylum: Arthropoda
Class: Insecta
Order: Diptera
Suborder: Nematocera
Infraorder: Culicomorpha
Superfamily: Culicoidea
Family: Culicidae
Subfamilies

Anophelinae
Culicinae
Toxorhynchitinae

Diversity
41 genera

Ara àwon kòkòrò tí ó n fò ni èfọn. Wón tún máa ń pè é ní yànmùyánmú. Àwọn ẹ̀fọn burú gan-an ni nítorí pé wọ́n máa ń tan àìsàn ká. Ẹ̀fọn tí ó bá jẹ́ akọ kò léwu. Ẹ̀fọn tí ó bá jẹ́ abo ni ó máa ń fa ẹ̀jẹ̀ ènìyàn tàbí ti ẹranko mu. Ibi tí ó ti ń fa ẹ̀jẹ̀ mu yìí ni ó ti máa ń tan àìsàn ká. Àwọn ẹ̀fọn kan máa ń tan malaria ká. Àwọn kan máa ń tan ibà apọ́njú ká.

Orí omi ni àwọn ẹ̀fọn máa ń yé sí. Lẹ́yìn òṣẹ̀ kan sí márùn-ún, ẹyin yìí yóò pa yóò di ‘larvae’, eléyìí ní yóò di ‘pupae’ kí ó tó wá di ẹ̀fọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.

A le fín oògùn sí ẹ̀fọn láti pa á tàbí kí a máa jẹ́ kí ó rí omi yé sí tàbí kí a máa sin àwọn ẹja kan tí ó máa ń jẹ ẹyin wọ̀nyí. Ti a ba fe sun, a le fi neeti yi beedi wa po ki efon ma baa je wa.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]