Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin
Queen Mother Pendant Mask- Iyoba MET DP231460.jpg
Ìwòjú t́ ó wà ní ilé pọnà Metropolitan àti ti ilé ọnà Bìrìtikó.
Idia mask BM Af1910 5-13 1.jpg
MaterialÌho ẹfọ̀n
Createdọ̀rundún mẹ́rìndínlógún
Present locationIlé pọnà Metropolitan, Ilé ọnà Bìrìtikó.

Ẹ̀gbà ọrùn bí ìbòju tí Benin jẹ́ ẹ̀gbà ọrùn tí wọ́n gbẹ́ lére tí ó sì jẹ́ àwòrán akọni obìrin tí a mọ̀ si ìyá wa Olorì Idia ti ọ̀rundún mẹ́rìndínlógún ṣẹ́yìn. Ọmọ rẹ̀ Esigie tí ó jẹ́ ọba  ti Benin maa ń wọ́ èyí tí ó jọọ́ fún àwọn ọmọ ogun ẹ̀yìn ìya olorì. Ibojú yìí pé méjì tí ó jọ ara wọn: Ìkan wà ní Ilé ọnà ti a mọ̀ sí British Museum ní ìlú London tí ìkejì sì wà ní ilé ọnà tí a mọ̀ sí Metropolitan Museum of Art ní ìlú New York.[1][2]

Àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ lórí àkọ́lé kan náà wà ní Seattle Art Museum[3] àti Linden Museum,[4] tí ìkan ná sì wà ní ilé ibi tí wọ́n kò gba òpò eniyan láyè láti wọ̀,[5][6] gbogbo rẹ̀ ní wọ́n kó nígbà ìwádí lọ sí ìlú Benin ní ọdún 1897.

Ìbojú yìí ti di àmì ìdánimọ̀ lóde òní ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ìgbà ìpéjọ-pọ̀ kan tí a mọ̀ sí FESTAC 77 tí ó wáyé ní ọdún 1977.

Ìrísí àti Ìwúlò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ó ní ìrísí èyí tí ó jọ Ìbojú Ìbílẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ībòjú kékeré òhún tí kò gígùn rẹ̀ kò ju ìwòn 24cm lọ kìí ṣé fún wíwọ̀ sójú, Ọba lè wọ̀ọ́ sọ́rùn (tí ó sì maa bá mu[7]) tàbí bi "ìlẹ̀kẹ̀ ìbàdí" (èyí tí ó sì maa bá ayẹyẹ tí ó fẹ́ sẹe mu). Èyí tí ó wà ní ilé ọnà Met àti èyí tí ó wà ní ilé ọnà British fẹ́ jọ ara wọn, méjèèjì ni ó jẹ́ àwòràn Olorì Idia.

Wọn dárà ìlẹ̀kẹ̀ si lórí,lọ́rùn,ègbẹ́ níwájú orí àti gbígbẹ́  èyí tí ó fàyè ọ̀nà méjì tí wọ́n lè fi ẹ̀gbà kọ́.

Lóde òní àwọn ènìyàn máa ń gbé onírú irú àworan tí ó jọ́ọ níbi ayẹyẹ láti lé ẹbọra búrúkú, ṣùgbọ́n ní bí ọrundún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn, wọ́n lè maa lòó fún ayẹyẹ ìya ọba.[8]

Ó dàbí wípé ní bí ìbẹ̀rẹ̀ ọrúndún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn ni wọ́n gbẹ́ àwọn Ìbòjú méjèèjì, bóya ní ọdún 1520,[9] nígbà tí Olorì Idia, ìyá ọba Oba Esigie, jẹ́ aládájọ́ ní ilé ẹjọ́ ti Benin.

Akọni obìnrin[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Irú àwòrán yìí kò wọ́pọ̀ ní iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Benin, àti pé ipò Idia, tí iṣẹ̀ṣe àwọn Edo mọ̀ sí "obìnrin kan ṣoṣo tó lọ sógun", tí ó da yàtọ̀, tí wọ́n sí dá oyèIyoba tàbí Ìyá Olori ̀́n sílẹ̀ fun[10] Ìwérí rẹ̀ jẹ́ ara irú irun tí wọ́n ń pè ní ukpe-okhue ("ẹnu àparò"), tí a lè rí dáadára ní àfihàn orí edẹ Olorì Idia. Ìwérí rẹ̀ tí ó rẹwà àti ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ̀ bí ìlẹ̀kẹ̀ roboto ("ọlà"), tí wọ́n fún ìya wa olorì láàfàní láti máa wọ̀, léyí tí ó jẹ́ pé olóyè ni ówà fúnwhich.[11][12][13][14] Ìlẹ̀kẹ̀ pupa yìí àti aṣọ pupa, ti fìgbàkan wà fún àwọn olókìkí, tí wọ́n sì ti ri lóde òní gẹ́gẹ́ bi ara imùra ìbílẹ̀ ní Edo.

Arábìrin ọmọ Edo tí ó wọ́ ìlẹ̀kẹ̀ ìgbàlódé.

Ní iwájú orí ìbòjú méjì yìí, ìlà mẹ́rin wà níbẹ̀, tí ó sì dúro ṣangílítí sí òkè ojú kànkan, irin méjì sì ṣe àpèjúwe ilà yìí.[15] Irin ni wọ́n fi ṣe ibi ojú rẹ̀.

Àmì fún okùn òwò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ibi funfun ìwò ẹ̀fọ̀ tí wọ́n fi ṣe ìwòjú yìí jẹ́ àpẹẹrẹ òòṣà Olokun. Bí ó ṣe rí yìí, kò wọ́n nìkan nítórí wọ́n lọ ìwo ẹfọ̀ tí ó wúlò tí ó sì ṣeétà lówó gọbọhi, ṣùgbọ́n àwọ̀ rẹ̀ tún jẹ́ àpẹ́ẹrẹ òòṣà tí ó ní ṣ pẹ̀lú olá Oba Benin.[16]

Ihò tí ó wà ní ibi oun ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àti ibi ọrùn rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí àwọn ọkùnrin Àgùdà maa ń fi ṣẹ̀ṣọ́, tí ó sì jẹ́ wípé àwòrán mọ́kànlá bẹ́ẹ̀ wà ní ilé ọnà ìbòjú tí Bìrìtìkó àti pé mẹ́tàlá wà ní ilé ọnà Met tí ó ṣe àfihàn àwọn ọkùnrin Àgùdá tí wọ́n múra bí àwọn ènìyàn dúdú. Orùn ìwòjú tí ó wà ní ilé ọnà Metropolitant (Met) jọ mọ́ èyí tí wọ́n fi  àwọn ọkùnrin Àgùdà ṣẹ̀ṣọ́ rẹ̀ (ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́ díẹ̀), Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọrùn ìwòjú èyí tí ó wà ní ilé ọnà Bìrìtìkó jẹ́ èyí tí wọ́n fi igi tàbí irin gbẹ́.

Àọn Àgùdà jẹ́ oníṣòwò pẹ̀lú àwọn Benin nígbàyẹn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣàpèjúwe rẹ̀, ó jẹ́ àpẹrẹ́ àjọṣepọ̀ láàrin omi àti ilẹ̀.[17]

Àwọn àkíyèsí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Ivory mask - Google Arts & Culture" (in en). Google Cultural Institute. https://www.google.com/culturalinstitute/beta/asset/ivory-mask/YwEcUb_gRSUFrw. 
 2. Metropolitan Museum Collection Queen Mother Pendant Mask: Iyoba, MetMuseum, retrieved 1 November 2014
 3. "Collections - SAM - Seattle Art Museum". www1.seattleartmuseum.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-02-22. 
 4. Lindenmuseum. "Linden-Museum - Afrika". www.lindenmuseum.de (in Èdè Jámánì). Retrieved 2017-02-22. 
 5. "Sotheby’s to auction ‘Oba’ mask". Financial Times. Retrieved 2017-02-22. 
 6. "Sotheby's cancels sale of 'looted' Benin mask" (in en-GB). The Independent. 2010-12-29. http://www.independent.co.uk/arts-entertainment/art/news/sothebys-cancels-sale-of-looted-benin-mask-2171125.html. 
 7. Ezra, Kate (1992-01-01) (in en). Royal Art of Benin: The Perls Collection in the Metropolitan Museum of Art. Metropolitan Museum of Art. ISBN 9780870996337. https://books.google.com/books?id=Q8PDPDRgO4sC&pg=PA153. 
 8. Ezra, the Metropolitan Museum of Art ; introductions by Douglas Newton, Julie Jones, Kate (1987). The Pacific Islands, Africa, and the Americas. New York: Metropolitan Museum of Art. p. 84. ISBN 0870994611. https://books.google.com/books?isbn=0870994611. Retrieved 1 November 2014. 
 9. Hansen, Valerie; Curtis, Ken (2016-01-01) (in en). Voyages in World History. Cengage Learning. ISBN 9781305888418. https://books.google.com/books?id=VckaCgAAQBAJ&pg=PA478. 
 10. Bortolot, Author: Alexander Ives. "Idia: The First Queen Mother of Benin | Essay | Heilbrunn Timeline of Art History | The Metropolitan Museum of Art". The Met’s Heilbrunn Timeline of Art History. Retrieved 2017-02-24. 
 11. Smith, Bonnie G. (2008-01-01) (in en). The Oxford Encyclopedia of Women in World History: 4 Volume Set. Oxford University Press, USA. ISBN 9780195148909. https://books.google.com/books?id=EFI7tr9XK6EC&pg=PA527. 
 12. Ezra, Kate (1992-01-01) (in en). Royal Art of Benin: The Perls Collection in the Metropolitan Museum of Art. Metropolitan Museum of Art. ISBN 9780870996337. https://books.google.com/books?id=Q8PDPDRgO4sC&pg=PA41. 
 13. (in en) The Art of Benin. British Museum Press. 2010-01-01. pp. 13. ISBN 9780714125916. https://books.google.com/books?id=Vm9JAQAAIAAJ. 
 14. Meade, Teresa A.; Wiesner-Hanks, Merry E. (2008-04-15) (in en). A Companion to Gender History. John Wiley & Sons. ISBN 9780470692820. https://books.google.com/books?id=ZtQP5why918C&pg=PA267. 
 15. (in en) Africa. Prestel. 2001-01-01. pp. 74. ISBN 9783791325804. https://books.google.com/books?id=F3VJAQAAIAAJ. 
 16. Asante, Molefi Kete; Mazama, Ama (2008-11-26) (in en). Encyclopedia of African Religion. SAGE Publications. ISBN 9781506317861. https://books.google.com/books?id=uMv0CAAAQBAJ&pg=PT689. 
 17. Clarke, Christa; Arkenberg, Rebecca (2006-01-01) (in en). The Art of Africa: A Resource for Educators. Metropolitan Museum of Art. ISBN 9781588391902. https://books.google.com/books?id=6s6QN-rVWcIC&pg=PA119.