Jump to content

FESTAC 77

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A replica of this ivory mask was used as a symbol for Festac '77.

Festac '77, tí a tú mọ̀ sí ayẹyẹ kejì ti àwọn aláwọ̀ dúdú tó jẹmáṣà àti iṣẹ́-ọnà lágbàáyé (àkọ́kọ́ rè wáyé ní Dakar, ní ọdún 1966). Festac'77 fìgbà kan jẹ́ àjọ̀dún ilẹ̀ ọ̀kèrè tí wọ́n máa ń ṣe ní Ìpínlẹ̀ Èkó láti ọjọ́ kẹ̀ẹ́dógún oṣù kìíní ọdún 1977 wọ ọjọ́ kejìlá oṣù kejì ọdún 1977.[1] Ayẹyẹ olóṣù kan náà máa ń ṣàfihàn àsà ilẹ̀ Africa àti orin, iṣé-ọnà, ìtàn àròsọ, eré-oníṣe, ijó àti ẹ̀sìn. Iyè ènìyàn tó ń lọ bí i ẹgbàá lọ́nà mẹ́jọ tó ń sojú orílẹ̀-èdè Africa mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni ó máa ń kópa nínú ayẹyẹ náà.[2][3] Àwọn òṣèrè tó ṣeré níbi ayẹyẹ náà ni Stevie Wonder láti United States, Gilberto Gil láti ilẹ̀ Brazil, Bembeya Jazz National láti Guinea, Mighty Sparrow láti Trinidad and Tobago, Les Ballets Africains, South African Miriam Makeba, àti Franco Luambo Makiadi. Lásìkò tí wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ náà, ó jẹ́ ayẹyẹ tó tóbi jù lọ ní Africa.[4]

Ààmì ìdánimọ̀ ayẹyẹ náà jẹ́ èyí tí Erhabor Emokpae ṣe.[5] Ètol ayẹyẹ yìí ló bí ìdásílẹ̀ Nigerian National Council of Arts and Culture, ní Festac Village àti National Theatre, Iganmu, ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[6] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayẹyẹ náà ni wọ́n máa ń se ní agbègbè mẹ́rin ọ̀tọ̀tọ̀ tí ń ṣe: National Theatre, National Stadium, Surulere, Lagos City Hall àti Tafawa Balewa Square.[7]

Àwọn àwòkọ́ṣe fún àpéjọ FESTAC ni a lè wá lọ sípa ìdàgbàsókè àwọn ìmọ̀ràn lórí Négritude àti Pan-Africanism. Ní àwọn ọdún 1940s, Aimé Césaire àti Léopold Sédar Senghor, tí Pan-Africanism ti W. E. B. Du Bois àti iṣẹ́ àtinúda Alain Locke ti New Negro jẹ́ ìwúrí fún bẹ̀rẹ̀ ìwé àkọsílẹ̀ àti ilé-ìtẹ̀wéjáda ní Paris tí wón pè ní Présence Africaine; Césaire àti Senghor náà jé ọmọ-ẹgbẹ́ Société africaine de culture.[8] Àwọn olùkópa ẹgbẹ́ náà jẹ́ òǹkọ̀wé ìtàn àti ohun ìní ilè Africa bíi Alioune Diop, Cheikh Anta Diop, Léopold Senghor, àti Jacques Rabemananjara, Richard Wright, Césaire, George Lamming, Horace Mann Bond, Jacques Alexis, John Davis, William Fontaine, Jean Price Mars, James Baldwin, Chester Himes, Mercer Cook àti Frantz Fanon.[9]

Wọ́n kọ́ ilé-ìgbé kan tí a mọ̀ sí Festac Village, tí ó ní ààyè láti gba èèyàn 17,000. Àmọ́, àfojúsùn ilé-ìgbé yìí ni láti mú ìdínkùn bá ìṣòrò ilé-ìgbé wíwá.[10] Wọ́n dábàá láti kọ́ ilé-ìgbé náà láàárín ọdún méjì, kí wọ́n sì gbà àwọn ogójì alágbàṣe láti ṣiṣẹ́ lórí ilè náà. Lápapọ̀, yàrá 5,088 ni wọ́n kọ́ ṣáájú ayẹyẹ náà, pẹ̀lú àfikún yàrá 5,687 ní ìparí ọdún 1977. Lásìkò ayẹyẹ àjọ̀dún náà, ilé-ìgbé náà jẹ́ ibi tí àwọn òṣèré máa ń ṣe ìgbáradì fún eré wọn, lọ́sàn-án àti lóru.

Fún ìgbàlejò àwọn ìṣe lóríṣiríṣi àti ẹ̀kọ́, wọ́n kọ́ theatre kan, tí ó jẹ́ ààyè fún iṣẹ́-ọnà àti àṣà Africa. Wọ́n kọ́ theatre náà ní ìbámu pẹ̀lú Palace of Culture and Sports ní Varna, Bulgaria. Èka náà ní gbọ̀gbán ìṣàfihàn méjì, gbọ̀gán mìíràn fún ayẹyẹ, tí ó le gba èèyàn 5,000, gbọ̀gán àpérò kan tó le gba èèyàn 1,600 àti gbọ̀gán méjì fún eré Sinimá.[10]

Èròńgbà ayẹyẹ náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Láti ríi dájú pé ìsọjí, ìsọdọ̀tun, ìtànkálẹ̀ àti ìgbéga ti àṣà àwọn adúláwọ̀, Africa àti àwọn ìdíyẹlé àṣà adúláwọ̀ kí ọ̀làjú ba lè dé bá wọn;
  • Láti ṣe àfihàn àṣà adúláwọ̀ àti Africa ní àyè àti agbègbè tí ó ga jù lọ;
  • Láti mú àwọn ìlowọ́sí onírúurú tí àwọn ènìyàn aláwọ̀dúdú àti Africa wá sí ìmọ́lẹ̀ láti pasẹ̀ iṣé-ọnà lóríṣiríṣi;
  • Láti ṣe ìgbélárugẹ àwọn òṣèré, òǹkọ̀wé aláwọ̀dúdú àti Africa, kí wọ́n ba lè di ìtẹ́wọ́gbà káàkiri àgbáyé, kí wọ́n sì lè ráàyè wọlé sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù;
  • Láti mú kí ìbáraẹniṣepọ̀ àti òye tó dán mọ́rán wà láàrin àwọn orílè-èdè àgbáyé;
  • Láti pèsè ìdápadà ìgbàdéìgbà sí orísun ilẹ̀ Africa láti ọwọ àwọn oṣèré aláwọ̀dúdú, òǹkọ̀wé, àti òṣèrè lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn.[3][8]

Ayẹyẹ àjọ̀dún náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Visual and performing arts

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. R, Jonathan C.; al; R, Jonathan C.; al (14 February 2014). "FESTAC: Upbeat Finale" (in en-US). The Washington Post. ISSN 0190-8286. https://www.washingtonpost.com/archive/lifestyle/1977/02/14/festac-upbeat-finale/e97a144d-bd6a-4e03-ba18-e0be4217d057/. 
  2. Gray, Karen (1 May 1977). "Festac: A Festival of Arts". Ebony Magazine. https://books.google.com/books?id=Ob4DAAAAMBAJ&q=ebony+magazine+festac&pg=PA44. 
  3. 3.0 3.1 Falola, Toyin (2002). Key Events in African History: A Reference Guide. Greenwood Press. pp. 281. ISBN 9780313313233. https://books.google.com/books?id=1u0VDodtuJ0C&q=festac&pg=PA288. 
  4. Mwalimu J. Shujaa, Kenya J. Shujaa (13 July 2015). The SAGE Encyclopedia of African Cultural Heritage in North America. Sage Publishers. ISBN 9781483346380. https://books.google.com/books?id=ooVNCgAAQBAJ&q=miriam+makeba+second+world+black+and+african+festival+of+arts+and+culture&pg=PA845. Retrieved 22 August 2015. 
  5. "World Black and African Festival of Arts and Culture". Historical Dictionary of Nigeria. Scarecrow Press. 1 July 2009. p. 369. ISBN 978-0-8108-6316-3. https://archive.org/details/historicaldictio0000falo. 
  6. Apter, Andrew (2005). The Pan-African Nation: Oil and the Spectacle of Culture in Nigeria. University of Chicago Press. 
  7. Foundation for Research in the Afro-American Creative Arts, "Festac '77", The Black Perspective in Music, Vol. 5, No. 1 (Spring 1977), pp. 104–117.
  8. 8.0 8.1 Enahoro, Ife (1977). "The Second World Black and African Festival of Arts and Culture: Lagos, Nigeria", Black Scholar, Vol. 9, No. 1. September, pp. 27–33.
  9. Ratcliff, Anthony (February 2014). "When Négritude Was In Vogue: Critical Reflections of the First World Festival of Negro Arts and Culture in 1966.". Journal of Pan African Studies 6 (7). https://www.questia.com/library/journal/1G1-367421046/when-negritude-was-in-vogue-critical-reflections. 
  10. 10.0 10.1 Moore, Sylvia (1977). The Afro-Black Connection: FESTAC 77. Amsterdam: Royal Tropical Institute.