Toyin Falola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Toyin Falola
Ìbí 1 January 1953
Ibadan, Nigeria
Ará ìlẹ̀ Nigeria
Ọmọ orílẹ̀-èdè Nigerian
Ẹ̀yà Yoruba
Pápá Ìtàn Afrika
Ilé-ẹ̀kọ́ University of Texas, Obafemi Awolowo University
Ó gbajúmọ̀ fún Historiography in Africa

Toyin Omoyeni Falola ( a bi ni ojo kini osu kini odun 1953 ni ilu Ibadan). Falola je Olukotan omo ile Naijiria ati ojogbon ninu eko imo Alawodudu (Afrika). Lowolowo, o je oludari Jacob and Frances Sange Monssiker chair nipa inu rere si eniyan (Humanitarian) eyi ti o wa ni ile-eko giga yunifasiti ti Austin ti o wa ni ilu Texas. Falola gba oye akoko ti yunifasiti (B.A). O tun gba oye imo ijinle (Ph.D) ni odun 1981 ninu iwe itan (History) ni ile -eko giga yunifasiti ti Obafemi Awolowo ti o wa ni ile-ife, orile ede Naijiria. Falola je omo egbe ajumose ti o ga julo nipa iwe itan ati ti ile-eko giga nipa iwe kiko si eniyan ti orile ede Naijiria. Iwe ti o koja egberun kan ni Falola ti ko ti o si tun ti se fun tite, ati wipe ohun ni oluse iwe fun tite agba fun Cambria African studies series.

Awon Ise Ikeko ati Awon Ami Eye[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iwadi ti Ojogbon Toyin Falola ni ife si ju ni itan alawo dudu lati bi odun 19th century nipa ti isebaye ile eko ti ilu Ibadan; awon agbegbe ti o ni ife si pelu ni Africa, Latin America ati orile ede Amerika. Lara awon eko ti Ojogbon Falola ti ko ni Ifihan(Introduction) si Isebaye(Traditional) Afrika, eyi ti a pile se fun awon akeko ni orisirisi ipinle ninu eko imo Afrika.ati Epistemologies ti Afrika.

Falola bere ise olukoni re ni Pahayi niodun 1970. Nigbati o ma fi di odun 1981, Falola ti di olukoni ni ile eko giga yunifasity ti o fidi kale si ile ife nile Nigeria. O darapo mo eka ikowe ti o wa ni yunifasity ti Texas ti o wa ni Austin ni odun 1991. O tun gba ise oluko alakoko die in yunifasity ti Cambridge ni orile ede England.

Ojogbon Falola ti gba orisirisi awon oye ibuyinfun ti dokita ati awon ami eye ni orisirisi agbegbe ni agbaye, lara won ni ami eye ti Lincoln, ami eye ti Cheikh Anta Diop, ami eye ti Amistad, ami eye ti SIRAS fun iranlowo ti o tayo fun ikeko lori Afrika, ami eye fun Distinguished Africanist, ami eye ti Jean Holloway ti ile eko giga yunifasity ti Texas ti o wa ni ilu Austin fun olukoni ti o tayo julo, ami eye olukoni ti o dara julo ti Chancellor's Council ati ami eye ti tayo lori Career Research. Falola tun gba honorari iyi ti dokita leta (doctors of letter) lati owo ile eko giga yunifasity ti ekose ogbin ni ilu abeokuta.(FUNAAB) ni odun 2018.


TOFAC

Ni orile ede Nigeria, apero kan wa ti awon akojopo egbe Ibadan cultural studies group so ni oruko Toyin Falola. Ojogbon Ademola Dasylva ni oludari akojopo egbe yi. Apero ti a pe oruko re ni Toyin Falola International Conference on Africa and the Africa Diaspora (TOFAC), ni o koko waye ni ile eko giga yunifasity akoko ni ile Nigeria ni ilu Ibadan. Apero keji waye ni ilu eko nipase Centre for Black African Arts and Civilization (CBAAC), labe iso alakoso agba, ojogbon Tunde Babawale.