Ẹgbẹ́ Oòduà (OPC)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Oòduà Peoples Congress tí a ń pè ní Oòduà Peoples Congress (OPC) jẹ́ agbaríjọ pọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n jẹ́ ajìjàngbara ilẹ̀ Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Àwọn ọmọ Yorùbá ló jẹ́ pé wọ́n wà ní apá Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àti ní púpọ̀ọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè bíi Benin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn sì ń sọ èdè Yorùbá. OPC ni a tún mọ̀ sí Oòduà Liberation Movement (OLM) tàbí Revolutionary Council of Nigeria (RCN).[2]

Ìtàn OPC[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́ lààmì-laaka ni wọ́n dá ẹgbẹ́ Oòduà sílẹ̀. Ẹni tí ó dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ ni ọ̀gbẹ́ni Frederick Fáṣeun. Ó dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ láti lè mú Alábà àti ìran Ìbò òṣèlú tí wọ́n di yan olóògbé olóyè M.K.O Abíọ́lá ní Ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà ọdún 1999, amọ́ tí ìjọba ológun ìgbà náà tí ọ̀gágun Ibrahim Babangida dárí rẹ̀ dànù bí omi ìṣànwọ́.[3] Lóòtọ ni Fáṣeun jẹ́ Alága gbogbo gbo fún ẹgbẹ́ Oòduà, ṣùgbọ́n ní ọdún 1999 ọ̀gbẹ́ni Gani Adams yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ tí ó sì lọ dá dúró àmọ́ tí ó sì ń gbé orúkọ ẹgbẹ́ náà ga. Ṣáájú ikú ọ̀gbẹ́ni Fáseun ní ọdún 2018, òun ni gbogbo ọmọ Yorùbá gbà wípé ó jẹ́ adarí ẹgbẹ́ Oòduà. Lẹ́yìn ikú Fáseun, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Oòduà yan Ọmọba Òṣíbọ́tẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alága àti adarí tuntun fún ẹgbẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Fà ṣeun ṣe fi lọ́ọ́lẹ̀ kí ó tó kú.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "OPC blasts Northern group over comment on Amotekun - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2020-01-11. Retrieved 2020-01-12. 
  2. "O'odua Peoples Congress (OPC)", globalsecurity.org, 16 February 2003.
  3. Noble, Kenneth B. (24 June 1993). "Nigerian Miitary Rulers Annul Elections". The New York Times. https://www.nytimes.com/1993/06/24/world/nigerian-military-rulers-annul-election.html. 
  4. "IRIN-WA Update 618 [19991218]". UN Office for the Coordination of Humanitarian Affairs Integrated Regional Information Network. 1999-12-18. Retrieved 2010-04-02.