Jump to content

Ọdún Kwame Nkrumah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọdún Kwame Nkrumah Pan-African Intellectual Cultural tí a tún mọ̀ sí ọdún Kwame Nkrumah Festival (KNF) jẹ́ ọdún tí Alága Kwame Nkrumah ṣètò ní Institute of African Studies ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti University of Ghana.[1]

Ọdún náà náà di ṣíṣe ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2010 láti ṣe àyẹ́sí ìfọkànsìn Kwame Nkrumah sí ìṣe àṣà àti ọgbọ́n tí ó dá lórí ilẹ̀ Áfíríkà.Àdàkọ:Cn

Ọdún kẹta ti Kwame Nkrumah

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún kẹta ti Kwame Nkrumah[2] di ṣíṣe àkóso láti ọwọ́ Alága kẹrin ti Kwame Nkrumah, Amina Mama.[3] Ó jẹ́ ìṣàkóso ti ìsọdọ̀kan ti ìdàkejì àṣà, èrò àti àwọn ọ̀nà mìíràn láti ṣe ìdúnàdúrà. Àfojúsùn rẹ̀ ni láti ṣe ìlọsíwájú ọ̀rọ̀-ajé àṣà ìsọdọ̀kan tuntun àti ìlàlójú tí ó máa ní ìfẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Afíríkà lọ́kàn. Ọdún náà wáyé gẹ́gẹ́ bí àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19 gbá Áfíríkà èyí sì ni àkọ́kọ́ tí ìṣàkóso rẹ̀ wáyé ní orí ẹ̀rọ ayélujára, tí ó wáyé ní orí ìtàkùn ayélujára tí ó sì di gbígbé àgbáyé. Ọdún náà di gbígbà gẹ́gẹ́ bí àǹfààní fún Ìgbésẹ̀ tòótọ́ láti gbé àti láti tún bọ̀ fún lókun àpapọ̀ ìsọdọ̀kan wa àti láti ṣe ìlọsíwájú ayélujára ìsọdọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àjọ̀dún ìsẹ̀m̀báyé Kwame Nkrumah.

Ní àkókò ìṣeré ọjọ́ mẹ́wàá, ó di ṣíṣe àbẹ̀wò sí láti ọwọ́ ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àlejò láti orílẹ̀-èdè mẹ́talélọ́gọ́rùn-ún, èyí tí ó lé ní ìdajì wọn wá láti méjìdínláàádọ́ta nínú mẹ́rinléláàádọ́ta orílẹ̀-èdè Áfíríkà. Ọdún náà láti ìgbà náà ti di ohun ìselọ́sọ̀ọ́ orí ayélujára láti dúró gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìmọ̀ ìsọdọ̀kan. Àkóónú rẹ̀ kún fún ìtàkurọ̀sọ òṣèlú àti ọgbọ́n ti àsìkò láàárín àwọn asègbèfábo ìsọdọ̀kan, àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àlàyé ẹgbẹ́ orí mìíràn àti ìgbésẹ̀ tí ó di fífi sọrí mímú àyípadà rere wá.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "IAS to hold 3rd Kwame Nkrumah Pan-African Intellectual and Cultural Festival". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-09-07. Archived from the original on 2023-09-28. Retrieved 2021-09-14. 
  2. "Home - Kwame Nkrumah Festival". kwamenkrumahfestival.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-05-19. Retrieved 2022-07-09. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "Current Occupant | Institute of African Studies | University of Ghana". ias.ug.edu.gh. Retrieved 2022-07-09.