Ọdẹ
Ọdẹ ni orúkọ tí a ń pe àwọn àkàndá ènìyàn kan tí wọ́n yan iṣẹ́ pípa ẹranko ìgbẹ́ ,dídẹ Odò, pípa ẹyẹ oríṣiríṣi lọ́pọ̀ ìgbà.
Ọdẹ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní àwùjọ Yorùbá láyé àtijọ́, Ọdẹ ṣiṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ abiyì láàrín tí ọ̀pọ̀ àwọn Òbí ma ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ó kọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ àti iṣẹ́ òòjọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ Yorùbá, wípé iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, wọ́n ma ń pọọ́n ní dandan fún ara wọn láti ní iṣẹ́ lọ́wọ́. Ọdẹ ṣíṣe tún jẹ́ iṣẹ́ ìdílé àwọn ẹbí kan tí wọ́n si ma ń jẹ́ orúkọ tí ó jọ mọ́ iṣẹ́ yí. Wọn a máa jẹ́ Ọdẹ́jìnmí,Ọdẹ́wálé, Ọdẹ́gbèmí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀wẹ̀, àwọn Ọdẹ náà tún ma ń ṣọ́de òru léte àti dáàbò bo ìlú, ẹ̀mí, àti dúkìá pátá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ògbójú Ọdẹ ni wọ́n ma ń lọ sójú ogun láti dábò bo ìlú wọn.[1][2]
Ọ̀nà tí iṣẹ́ Ọdẹ pin sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lára àwọn ọ̀nà tí iṣẹ́ Ọdẹ pin sí ni:
- Ọdẹ Apẹran. Àwọn irúfẹ́ Ọdẹ tí ó wà ní ọ̀wọ́ yí ni wọ́n ma ń dẹ̀gbẹ́, dẹ tàkúté láti pẹran wẹ́wẹ́ àti ẹran abìjàwàrà nínú igbó tàbí aginjù yálà fún títà tàbí jíjẹ.
- Ọdẹ Adẹdò. Irúfẹ́ àwọn wọ̀yí ni wọ́n ma ń ṣíṣe dẹdò, dẹ̀gèrè sórí alagba-lúgbú omi láti pa ẹja oríṣiríṣi yálà fún títà tàbí tàbí fún jíjẹ nínú Ilé.[3]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Utilisateur, Super (2018-03-02). "Present Day Hunter’s Festival in Yorubaland and Their Music". IFRA Nigeria. Archived from the original on 2019-12-15. Retrieved 2019-12-15.
- ↑ Temidayo, Mustapha (2017-01-17). "Spiritual, moral lives of hunters". The Nation Newspaper. Retrieved 2019-12-15.
- ↑ "ÒGBÓJÚ ỌDẸ - THE GREAT HUNTER". YO'BA MO'ODUA: ÒGBÓJÚ ỌDẸ (in Èdè Latini). 2013-01-10. Retrieved 2019-12-15.
- ↑ "Spiritual, moral lives of hunters". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2017-01-17. Retrieved 2019-12-15.