Ọwọ́
Ọwọ́ | |
---|---|
Ẹ̀yìn ọwọ́ (òsì) àti iwájú (ọwọ́) ọ̀tún ènìyàn tí ó jẹ́ ọkùnrin. | |
X-ray of human hand | |
Details | |
Vein | Dorsal venous network of hand |
Nerve | Ulnar, median, radial nerves |
Latin | Manus |
Anatomical terminology |
Ọwọ́ ni a lè pè ní ẹ̀ya ara tí fi ń di nkan mú tí ó si ni ọmọ-ìka púpọ̀ ní ìparí rẹ̀, òun ni ó sì kẹ́yìn ọrùn ọwọ́. A lè ṣalábàá-pàdé ọwọ́ lára àwọn ẹranko elégungun bíi: Ènìyàn, Ọ̀bọ Ìnàkí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[1] Ọwọ́ ènìyàn sábà máa ń ní ìka mẹ́rin tí àtànpàkò sì ṣ'ìkarùn ún wọn. [2][3] Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ ìka yí ni a ń pè ní ọwọ́.[2][4][5] Ọwọ́ tí a ń sọ yí ní egungun mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n(ọwọ́ kan), ọwọ́ méjéjì lápapò ní egungun mẹ́rìnléláàdọ́ta [6], èyí tí kò sí egungun sesamoid , èyí tí kìí jẹ́ iye kan náà lára ènìyàn kan sí ìkejì. Egungun mẹ́rìnlá nínú àwọn egungun ọwọ́ jẹ́ àkójọ egungun ìka pẹ̀lú àtànpàkò. Àwọn egungun àtẹ́lẹwọ́ (metacarpals) ni ó di egungun ìka pẹ̀lú egungun ọrùn ọwọ́ mú. Ọwọ́ ènìyàn kan a máa ní egungun àtẹ́lẹwọ́ márùn-ún pẹ̀lú egungun ọrùn ọwọ́ mẹ́jọ.
Ọwọ́ kọ́ ipa pàtàkì lára ènìyàn ní ṣíṣe itọ́ka sí àti àpèjúwèé aláìlo gbólóhùn. Bákannáà, a máa ń lo ọmọ ìka mẹ́wẹẹ̀wá pẹ̀lu àwọn egungun ọmọ ìka làti ṣe ohunkà àti fún ìṣirò.
Àgbékalẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Pùpọ̀ nínú àwọn ẹranko onírunlára àti àwọn ẹranko míràn ní ẹ̀ya ara tí wọ́n fi ń di nkan mú, ṣùgbọ́n ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò kà wọ́n kún ọwọ́. Ọwọ́ ni a lè rí lára ipín àwọn ẹranko tí ó jọ ọ̀bọ àti ìnànkí. Kí a tó lè ka ẹ̀ya ara kún ọwọ́, ó gbọdọ̀ ní àtànpàkò tí ó dojúkọ àwọn ìka mẹ́rin míràn.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Thomas, Dorcas MacClintock; illustrated by J. Sharkey (2002). A natural history of raccoons. Caldwell, N.J.: Blackburn Press. p. 15. ISBN 978-1-930665-67-5.
- ↑ 2.0 2.1 Latash, Mark L. (2008). Synergy. Oxford University Press, USA. pp. 137–. ISBN 978-0-19-533316-9. https://books.google.com/books?id=640UDAAAQBAJ&pg=PA137.
- ↑ Kivell, Tracy L.; Lemelin, Pierre; Richmond, Brian G.; Schmitt, Daniel (2016). The Evolution of the Primate Hand: Anatomical, Developmental, Functional, and Paleontological Evidence. Springer. pp. 7–. ISBN 978-1-4939-3646-5. https://books.google.com/books?id=R1nSDAAAQBAJ&pg=PA7.
- ↑ Goldfinger, Eliot (1991). Human Anatomy for Artists : The Elements of Form: The Elements of Form. Oxford University Press. pp. 177, 295. ISBN 9780199763108.
- ↑ O'Rahilly, Ronan; Müller, Fabiola (1983). Basic Human Anatomy: A Regional Study of Human Structure. Saunders. p. 93. ISBN 9780721669908.
- ↑ "Anatomy: Hand and Wrist". BID Needham. Retrieved 2022-03-08.