2024 Chicago Marathon
Àdàkọ:Infobox sports competition event
2024 Chicago Marathon ni eréèje ọlọ́dọdún ẹlẹ́kẹrìndínláàádọ́ta ti Chicago Marathon, tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kẹwàá ọdún 2024 (October 13, 2024). Eré-ìje yìí jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹfà irú rẹ́ ti World Marathon Majors tí wọ́n ṣe lọ́dú 2024, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ eréèje àgbáyé ti platinum label.[1][2]
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún ọgọ́fà ni wọ́n f'orúkọ silẹ láti kópa nínú rẹ̀ lọ́dún 2024. Àwọn 52,150 ni wọ́n kópa járí nínú ìdíje náà,[3] èyí tí ó ju akópa 48,398 tí wọ́n kópa lọ́dún 2023. Kíyèsí, l'óṣù kẹfà ọdún 2024, ní àwọn aṣètò eréèje náà kéde pé àdínkù fún iye àkókò ìpegede kàn-án-pá tí ìdíje náà fún ọdún 2025.[4]
Wọ́n ṣe ìdákẹ́ rọ́rọ́ ìṣẹ́jú kan ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje náà láti bọlá fún olùborí ìdíje náà tí ọdún 2023, tí ó tún jẹ́ ẹni tí ó pegede julọ ninu itan ìdíje náà,Kelvin Kiptum,l'óṣù kejì ọdún 2024.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Chicago Marathon's illustrious history recognised with Heritage Plaque | Heritage News | Heritage | World Athletics". worldathletics.org. Retrieved 2024-10-08.
- ↑ "Majors". www.worldmarathonmajors.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-10-08.
- ↑ Staff • •, NBC Chicago (2024-10-14). "Beyond the world record finish, the 2024 Chicago Marathon set another major record". NBC Chicago (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-10-17.
- ↑ Ormond, Cameron (2024-07-02). "Chicago Marathon qualifying times just got ridiculously fast". Canadian Running Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-10-08.