2face Idibia
2Baba | |
---|---|
2Baba attending the album release party for his sixth studio album, The Ascension. | |
Background information | |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | 2face Idibia |
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹ̀sán 1975 Jos, Plateau, Nàìjíríà |
Occupation(s) |
|
Instruments |
|
Years active | 1994–present |
Labels | |
Associated acts |
Innocent Ujah Idibia (tí a bí sí ìlú Jos, ìpínlẹ̀ Plateau State, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ 2Baba, jẹ́ olórin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, akọrin sílẹ̀, agbọ́rin jáde àti onísẹ́ àdáni. Ní oṣù keje Odun 2014, ó yan 2face Idibia gẹ́gẹ́ bí orúkọ ìtàgé rẹ̀.[1] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin ilẹ̀ Áfíríkà tó ń kọ orin Afro pop tí ó lọ́lá jùlọ tí ó sì gbayì.[2] Ó ti lé lógún ọdún tí 2Baba tí ń kọrin tí ó sì ń dánilárayá ó sì jẹ́ ògbóǹtarìgì síbẹ̀.
Ó tún jẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ.
Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Innocent Idibia sí ìlú Jos, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Idoma ní apá gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó lọ sí Mount Saint Gabriel's Secondary School ní ìlú Makurdi, ìpínlẹ̀ Benue. Ó tún lọ sí Institute of Management & Technology (IMT) ní ìpínlẹ̀ Enugu níbi tí ó ti gboyè National Diploma nínú Business administration and management. Nígbà tí ó wà ní IMT, ó máa ń kọrin níbi ayẹyẹ àti àwọn ilé-ìwé gíga bíi University of Nigeria Enugu State University of Science & Technology. Kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó kúrò nilé-ìwé ó sì gbájúmọ́ orin kíkọ. Ní ọdún 1996, ó yan "2face" gẹ́gẹ́ bíi orúkọ ìtàgé rẹ̀. [3]
Ní ọdún 2016, ó yí orúkọ ìtàgé rẹ̀ sí 2Baba.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Njoku, Benjamin (27 July 2014). "2face changes name to 'Tu-baba'". Vanguard. Retrieved 30 July 2014.
- ↑ "Know Your Naija: 10 Nigerian Stars To Watch". MTV Iggy.
- ↑ "2Face Idibia Live in London". Retrieved 11 March 2012 – via YouTube.
- ↑ "2face ‘officially’ changes name to 2baba". Music In Africa. Retrieved 14 January 2016.