Aṣọ Òfì
Aṣọ Òfì tàbí Aṣọ Òkè jẹ́ aṣọ olówùú tí a fọwọ́ hun láti ọwọ́ ẹ̀yà Yorùbá ti ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Aṣọ òkè túmọ̀ sí aṣọ ìléké ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ọkùnrin ni ó sáábà máa ń hun-ún, wọn a máa fi ṣe ẹ̀wù tí à ń pè nì agbádá, ìró obìrin tí à ń pè ní ìró, àti àkẹtẹ̀ ọkùnrin tí à ń pè ní fìlà
Láti inú àṣà ìpínlẹ̀ Òǹdó,Ìpínlẹ̀ Ògùn, Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ìpínlẹ̀ Èkó àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Ọ̀nà tí àń gbà hun aṣọ òkè kòyípadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àmọ́ ọgbọ́n àti ọ̀nà ìgbọ́jàjáde ti rí sí yíyí wíwúwo àti nínípọn aṣọ òkè àti kí ó ṣe é wọ̀n fún ìgbafẹ́
ORÍSIRÍSI AṢỌ ÒKÈ Àwọn ọ̀nà mìíràn tí àwọn ahunṣọ ń lò láti fi lè jẹ́ kí aṣọ ìbílẹ̀ ayé àtijọ́ yìí di ti ìgbàlódé ni síṣe àlùmọ̀kọ́rọ́hí àti àlòpọ̀ àwòrán ọnà ẹranko àti òdòdó fún yíyọ àwọn igun àti jiọmẹ́tíríkà kan, tí ó dára fún iṣẹ́ ọnà nípa ẹ̀rọ ayára-bí-àsá. Ìpìlẹ̀ ọnà ìbílẹ̀ yóò ṣe bí ẹni wá láti ara ààlọ́ àti ìtàn àròsọ. • Orísi Sányán: a hun-ún láti ara sílíkì ánáfíì àti òwú yáǹsì • Orísi Àláàrì: A hun-ún pẹ̀lú yálà òwú òkèrè tàbí ti ìbílẹ̀ àti okùn dídán, ìgbàmíràn pẹ̀lú ihò ní fífi ṣe ọnà. • Orísi Ẹtù: máa ń ní àwọ̀ dúdú pẹ̀lú ìlà funfun tín-ín-rín-tín tí a mọ̀ fún àìní ìnira Wọ́n máa ń sáábà wọ aṣọ àrán pẹ̀lú àrán, fẹ́lẹ́tì aláwọ̀ ilẹ̀ẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹwà àpilẹ̀ṣe
AṢỌ OBÌNRIN Tí àwọn èyèàn bá sọ̀rọ̀ aṣọ òkè, wọn a tọ́ka sí aṣọ ìbílẹ̀ Yorùbá àwọn obìnrin. Ọ̀nà mẹ́rin ni ó pín sí; • Bùbá: Ẹ̀wù Yorùbá • Ìró: ìlọ́dìí tòbí • Gele: ìwérí • ìborùn tàbí tòbí: Sọ́ọ̀lù tàbí ìsẹ́léjìká
AṢỌ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé máa ń wọ aṣọ òkè fún òde pàtàkì lára rẹ̀ ni ayẹyẹ ìsinmi, ìgbéyàwó, òkú àgbà, àti oyè jíjẹ. Gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Yorùbá náà máa ń wọ aṣọ òkè àti fìlà