Abacavir

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Oògùn Abacavir tí a ń lò fún kòkòrò àìfojúrí HIV/Aids
Àwòrán bí oògùn náà ṣe ń ṣíṣe sí lára ènìyàn


Abacavir (ABC) jẹ́ oògùn kòkòrò àjẹsára tí ó ń dáàbò bo àwọn ọmọ ogun ara tí ó sì tún ń pa kòkòrò àìfojúrí HIV/Aids run nínú àgọ́ ara ènìyàn .[1][2] A lè lo oògùn yí gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń lo àwọn oògùn tí ó ń gbógun ti àrùn àìfojúrí HIV/Aids, ba kan náà ni a sí lè da lò lóun nìkan pẹ̀lú ìtọ́ni Dókítà. Wọn a máa fi omi lòó tàbí fi omi pòó mu tí wọ́n sì lè lòó fún ọmọdé tí ó ju oṣù mẹ́rin lọ.

Àgọ́ ara wa kìí lòdì sí oògùn abacavir. Àwọn ohun tí ó lè wáyé láìrò tẹ́lẹ̀ látàrí lilo oògùn yí ni èébì, àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru<, àìsàn ibà, àti kí ènìyàn Ma lè Mi kanẹ̀. Àwọn ohun mìíràn tí ó tún lè wáyé láìrò tẹ́lẹ̀ látàrí lilo oògùn yí tí ò lè lágbára ni kí àwọn ọmọ ogun ara máa ṣiṣẹ́ ju bí ó ti yẹ lọ, ìjànbá lè ṣe ẹ̀dọ̀ fóóró àti ìdíkù sí pH látàrí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lactate. Àyẹ̀wò DNA lè jẹ́ ki a mọ̀ bóya ènìyàn ní àǹfàní tópọ̀ láti ní ààrùn tí ó lè fa ki 9m9 ogun ara máa ṣiṣẹ́ ju bótiyẹ lọ. [3] Abacavir wà lára àwọn oògùn tí ó máa ń pagi dínà ìdàgbàsóke kòkòrò tí ó ma ń pa àwọn ọmọ ogun ara (NRTI), tí wọ́n sì máa ń fa ìdíwọ́ fún DNA láti di RNA, tí èsì rẹ̀ máa ń mún ìpeleke bá kòkòrò apa sójà ara. Nínú ẹ̀yà oògùn NRTI yìí, abacavir jẹ́ carbocyclic nucleoside.

Abacavir di ifihàn nígbangba ní ọdún 1988 tí wọ́n sì fi oùntẹ̀ tẹ̀ẹ́ fún lílò ní orílè ède Àmẹ́ríkà ní ọdùn 1998.[4][5] Ó jẹ́ ìkan lára àwon oògún tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣàkójọ ẹ̀ sí oògún tó wúlò jùlọ fún ìlera, oògùn tí ó gbóná ko, tí ó sì wúlò fún ètò ìlera. Ó jẹ́ oògùn tí a lè rí káàkàkiri. Ní bíi ọdún 2014, òṣùwọ̀n owó rẹ̀ lójú pálí ní àwọn ìlú tí ó ń dàgbàsókè kúsí US$ 0.36–0.83 fún ọjọ́ kan. Ní bíi ọdún 2016, òṣùwọ̀n owó rẹ̀ lójú pálí kúsí ni Amẹ́ríkà jẹ́ $70.50 fún oṣù kan . A máa ń ri abacavir rà pẹ̀lú àwọn  oògùn kòkòrò apa sójà ara míràn bíi abacavir/lamivudine/zidovudine, abacavir/dolutegravir/lamivudine, and abacavir/lamivudine.

Ìṣèto rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìṣèto abacavir:[6]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Abacavir Sulfate". The American Society of Health-System Pharmacists. Archived from the original on 21 August 2017. Retrieved 31 July 2015. 
  2. "Drug Name Abbreviations Adult and Adolescent ARV Guidelines". AIDSinfo. Archived from the original on 2016-11-09. Retrieved 2016-11-08. 
  3. Yuen, GJ; Weller, S; Pakes, GE (2008). "A review of the pharmacokinetics of abacavir.". Clinical pharmacokinetics 47 (6): 351–71. doi:10.2165/00003088-200847060-00001. PMID 18479171. 
  4. Fischer, Janos; Ganellin, C. Robin (2006) (in en). Analogue-based Drug Discovery. John Wiley & Sons. p. 505. ISBN 9783527607495. Archived from the original on 2017-09-08. https://web.archive.org/web/20170908213935/https://books.google.com/books?id=FjKfqkaKkAAC&pg=PA505. 
  5. Kane, Brigid M. (2008) (in en). HIV/AIDS Treatment Drugs. Infobase Publishing. p. 56. ISBN 9781438102078. Archived from the original on 2017-09-08. https://web.archive.org/web/20170908213935/https://books.google.com/books?id=RFNVvStUJlkC&pg=PA56. 
  6. Crimmins, M. T.; King, B. W. (1996). "An Efficient Asymmetric Approach to Carbocyclic Nucleosides: Asymmetric Synthesis of 1592U89, a Potent Inhibitor of HIV Reverse Transcriptase". The Journal of Organic Chemistry 61 (13): 4192–4193. doi:10.1021/jo960708p. PMID 11667311.