Abidemi Sanusi
Ìrísí
Abídèmí Sànúsí | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Èkó, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ Nàìjíríà |
Ẹ̀kọ́ | Leeds University |
Iṣẹ́ | Oǹkọ̀wé |
Notable work | Ìwé-ìtàn Aròsọ tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Eyo, ìwé-ìròyìn, Kemi's Journal, Ìwé-ìtàn, Zack's Story of Life, Love and Everything, God has daughter's too |
Abídèmí Sànúsí jẹ́ gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká oǹkọ̀wé ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí sí Ìpínlẹ̀ Èkó
Ìgbésí-ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Abídèmí Sànúsí sí ìlú Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó kàwé lórílẹ̀ èdè England ní Leeds University.
Abídèmí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn, tí ó sìn ṣiṣẹ́ ìbánimójútó ìkànnì ayélujára fún àwọn oǹkọ̀wé.
Ìwé ìtàn àròsọ Kemi's Journal tí ó kọ lọ́dún 2005 ni ìwé àpilẹ̀kọ rẹ̀ àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà ló kọ Zack's Story of Life, Love and Everythingàti God Has Daughters Too.[1] Ìwé-ìtàn-àròsọ tí ó kọ lẹ́yìn tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Eyo, tí ilé iṣẹ́ atẹ̀wé, WordAlive Publishers tẹ̀ jáde ní wọ́n yàn fún àmìn-ẹ̀yẹ tí Commonwealth Writers' Prizelọ́dún 2010.[2]
Àwọn ìwé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Eyo (2009)
- Kemi's Journal (2005)
- God Has Daughters Too' (2006)
- Zack's Story of Life, Love and Everything (2006)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Agbro Jr., Joe (2010-02-28). "Nigerian authors eye Commonwealth crown". Vintage Press Limited. Archived from the original on 2010-08-21. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Commonwealth Writers’ Prize regional winners’ shortlist announced". Commonwealth Foundation. Archived from the original on 2010-04-02. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)