Jump to content

Abuja F.C.

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Abuja FC
Full nameAbuja Football Club
Nickname(s)The Buffalos
Founded1998 (as Buffalo F.C.)
GroundOld Parade Ground Abuja, Nigeria
(Capacity: 5,000)
ChairmanAbdulrahaman Abdulrazaq
ManagerSuleiman Abubakar
LeagueNigeria Nationwide League
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Home colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Away colours

Abuja FC jẹ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá-jẹun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó ń díje ni abala ìdíje Nigeria Nationwide League. Wọ́n dá ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá yìí sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kano, kí wọ́n tó darí rẹ̀ sí Olú ìlú Nàìjíríà, Àbújá. Wọ́n máa ń lo pápá ìṣeré Old Parade Ground gẹ́gẹ́ bí gbọ̀ngàn ìdíje nílé wọ́n.

Ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀ Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olùkọ́ èdè Faransé kan tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Luc Lagouche ló dá ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá yìí sílẹ̀ lọ́dún 1998 nílé ẹ̀kọ́ èdè Faransé ní ìlú Kano. Buffalo FC ni orúkọ tí ó fún un ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá yìí ni abala àwọn ìdíje Àgbábuta kéréje, Abuja FC gba ìgbéga sí abala ìdíje tó ga.[1] [2]

Buffalo FC dèrò olú ìlú Nàìjíríà, Àbújá lọ́dún 2006,wọ́n sìn yí orúkọ rẹ̀ padà sí Àbújá FC, lẹ́yìn tí ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí ó ń gbógun ti ìwà ìkówó jẹ EFCC bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe onígbọ̀wọ́ fún wọn. Wọn gbìyànjú púpò nínú ìdíje abala tí wọ́n wà nígbà náà pẹ̀lú àmìn ìfẹ́ ẹ̀yẹ méjì léraléra (Federal Capital Territory Cups)

Àbújá FC gba ìgbéga sí ìdíje Àgbábuta bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá àgbà Nigeria Premier League nígbà tí wọ́n pegedé ni ipò kejì nínú ìdíje Àgbábuta bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá ipele kìíní Division 1A.[3]

Àwọn Àṣeyọrí wọn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
2002
2003
  • Wọ́n gbé ipò kejì ní Professional Division 1A Runners-up: 1
2008

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Abuja FC - Club profile". Transfermarkt (in Èdè Jámánì). Retrieved 2020-02-04. 
  2. "Abuja Metro FC". Abuja Metro FC. 2012-02-02. Archived from the original on 2020-02-04. Retrieved 2020-02-04. 
  3. "SoccerWiki.org". Soccer Wiki for the fans, by the fans. Retrieved 2020-02-04. 



Àdàkọ:Nigeria-footyclub-stub