Aderonke Kale
Aderonke Kale jẹ́ Dókítà ọpọlọ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ológun Nàìjíríà, òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di majo general ẹgbẹ́ ọmọ ológun Nàìjíríà. Ó wà lára àwọn adarí Nigerian Army Medical Corps.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Aderonke Kale kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní kọ́lẹ́jì Yunifásitì tí ó padà di Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Lẹ́yìn náà, Kale tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ ọpọlọ ní Yunifásitì ti London. Awòkọ́se Òjògbón Thomas Adeoye Lambo, ẹni tí ó jẹ́ Dókítà ọpọlọ àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ Áfríkà ni Kale wò kí ó tó fi pinu pé òun fẹ́ di Dókítá ọpọlọ.[1] Ó ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní Britain kí ó tó padà sí Nàìjíríà ní odún 1971.[2]
Ní ọdún 1972, ó dara pọ̀ ẹgbẹ́ ológun Nàìjíríà. Èyí jẹ́ òun tí kò wọ́pọ̀ láàrin àwọn obìnrin ní ìgbà náà, pàápàá jùlọ láàrin àwọn obìnrin tí ọwọ́ wọn ti lọ òkè lẹ́nu iṣẹ́ wọn.[2] Ó padà di Majo General nínú iṣẹ́ ológun tí ó tó fẹ̀híntì ní ọdún 1997.
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Aderonke Kale ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1959. Bàbá Kale jẹ́ onímọ̀ ògùn òyìnbó, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ olùkọ́, àwọn méjèèjì sa ipá wọn láti ri wípé Kale ni ẹ̀kọ́ tó dájú. Kale lọ ilé-ìwé primari ní Èkó àti Zaria kí ó tó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní St. Anne's School, Ibadan àti Abeokuta Grammar School.[3][4][5]
Ọmọ ẹ̀yà Yorùbá ni Aderonke.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Amodeni, Adunni (2018-06-04). "Retro: Inspiring story of Nigeria's first female Army General Aderonke Kale, she retired in 1996". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-07-29.
- ↑ 2.0 2.1 "DAWN COMMISSION || General Aderonke Kale (rtd) – Nigeria's First Lady Army General". dawncommission.org. Archived from the original on 2019-07-29. Retrieved 2019-07-29.
- ↑ Smith, Bonnie G. (2008) (in en). The Oxford Encyclopedia of Women in World History. Oxford University Press. p. 342. ISBN 9780195148909. https://books.google.com/books?id=EFI7tr9XK6EC.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedconnect3
- ↑ "Celebration Of Achievement Is Not Tribalism" (in en). Nigerian Voice. 14 August 2015. https://www.thenigerianvoice.com/news/188013/celebration-of-achievement-is-not-tribalism.html. Retrieved 29 November 2017.