Adetola Juyitan
Adetola Juyitan | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Adetola Juyitan Lagos state |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | |
Iṣẹ́ | Social entrepreneur |
Gbajúmọ̀ fún | President of Junior Chamber International Nigeria |
Adetola Juyitan jẹ́ Oníṣòwò àwùjo tí orílẹ̀-èdè Nàijíríà, Alákòso ti Glitz Group of companies ati Àare fún Junior Chamber International ní odún 2019.
Ìgbésí ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Juyitan jẹ́ omo Ìpínlẹ̀ Òndó ṣùgbọ́n a bíi ni ìlú Èkó, ó jẹ́ àkọ́bí nínú àwọn ọmọ márun. O kẹ́kọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìṣirò láti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìpínlẹ̀ Èkìtì, ó sì gba Oyè olúwa ti Ìsàkóso Ìṣòwò láti Ilé-ẹ̀kọ̀ gíga Lincoln, California, ni ilu Amẹ́ríkà.
Ní odún 2004, Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé ìfowópamọ́ Zenith gẹ́gẹ́ bíi ágùnbánirọ̀, ó sìń gba ìgbéga ipò títí di oṣù Kẹsan ọdún 2013 nígbàtí ó darapọ̀ mọ́ ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ fún Áfíríkà (United Bank for Africa) gẹ́gẹ́ bíi Olùṣàkóso Ìṣòwò, lẹ́hìnna ló kúrò ní odún 2015 láti ṣètò ilé-iṣẹ́ tirẹ́ tí à pè ní Glitz Occasions Nigeria Limited .
A yàn ń gẹ́gẹ́ bíi Alákoso Junior Chamber International ti orílẹ̀-èdè Nàijíríà ní ọdún 2019.