Adetunji Femi Fadina
Adetunji Femi Fadina ni alága ẹgbẹ́ Tourism Practitioners of Nigeria (ATPN),[1] èyí tó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Òun sì ni adarí àgbà ti ilé-iṣẹ́ Jethro Tours and Awori initiative, ó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Trade Promotion Board fún ẹ̀ka tó ń rí sí ètò ìṣòwò àti ilé-iṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[2]
Ètò ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilé-ìwé Loyola college ní Ìbàdàn ní ó ti parí ẹ̀kọ́ girama, ní ọdún 1980. Ó sì tẹ̀síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Business Administration and Management ní Samford University, láti ọdún 1981 wọ ọdún 1984.
Iṣé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adetunji ni olùdásílẹ̀ Awori Tourism Consulting firm,[3] àti Ààrẹ Association of Tourism Practitioners in Nigeria, èyí tó jẹ́ ẹgbẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìrìn-àjò àti ìgbéga àti ìdúróṣinṣin àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìrìn-àjò.[4] Òun náà sì ni olùdarí àgbà àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣé Dinat Consulting Inc.[5] Adetunji tí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí nínú iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìrìn-àjò, èyí sì hànde nínú ìṣèdásílẹ̀ ẹgbẹ́ kan tó sọ ní Jethro Tours Institute.[6]
Ní ọdún 2019, ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àṣà àti ìrìn-àjò ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, pe Adetunji láti wá sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọdọọdún wọn láti ṣègbélárúgẹ àṣà àti ètò ìrìn-àjò tó máa ń wáyé ní ìlú Abẹ́òkúta.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Now, Society (2019-09-18). "Here Is What Femi Fadina Is Up To At 42nd World Tourism Day Celebration". SocietyNow. Retrieved 2023-05-30.
- ↑ Nigeria, ATPN (2022-08-31). "Zonal Coordinators". ATPN Nigeria. Retrieved 2023-05-30.
- ↑ Nigeria, ATPN. "Awori Tourism Consulting". Association of Tourism Practitioners of Nigeria(ATPN). Retrieved 2023-05-31.
- ↑ "Awori Day Cultural Festival Gets New Date Nov 26 – THISDAYLIVE". THISDAYLIVE – Truth and Reason. 2022-10-22. Retrieved 2023-05-30.
- ↑ "Dinat Consulting Inc". Dinat Consulting Inc. Retrieved 2023-05-31.
- ↑ Now, Society (2019-09-18). "Here Is What Femi Fadina Is Up To At 42nd World Tourism Day Celebration". SocietyNow. Retrieved 2023-05-30.
- ↑ Akinyemi, Bioluwatife; Akinyemi, Bioluwatife (2022-10-23). "Awori Day Cultural Festival announces November 26 as new date". Tribune Online. Retrieved 2023-05-30.