Adunni Ade

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adunni Ade(Adewale)
Adunni at the AMVCA 2020
Ọjọ́ìbíAdunni Adewale
7 Oṣù Kẹfà 1976 (1976-06-07) (ọmọ ọdún 47)
Queens, New York, U.S.A.
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
American
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Kentucky
Iṣẹ́Actress, Model
Ìgbà iṣẹ́2006–present
Olólùfẹ́Nil
Àwọn ọmọ2

Adunni Ade (tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún 1976) jẹ́ òṣèré àti aláwòṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2]Adunni Ade je okan gbogi lara awon omo egbe osere amohun maworan ni ere ori itage ti yoruba.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ àti ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Adunni ní agbèègbè ti Ayaba, ìlú Niu Yoki (Queens, New York), ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìyá rẹ wá láti orílẹ̀-èdè Jẹmani(Germany), bàbá rẹ sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Yoruba láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Èkó àti Amẹ́ríkà ni wọ́n ti tọ́ Adunni dàgbà. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ipinle Eko àti ní Ipinle Ogun. Bàbá rẹ tí ó jẹ́ oníṣòwò pàtàkì tí ó sì fi Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ibùgbé ṣe àtìlẹyìn fun un láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ ìṣirò ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ó gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìṣirò láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Kenturky ní ọdún 2008.

Iṣẹ́ tí ó yàn laayo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adunni ṣe iṣẹ́ ní ẹ̀ka ilé gbígbé àti ìṣédúró ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí ó tó di wípé ó yẹ̀bá lọ sí ilé iṣẹ́ ìdánilárayá. Adunni dáwọ́lé iṣẹ́ àṣà àti àwòṣe èyí tí ó mú un fi ara hàn nínú "America's Next Top Model". Nígbàtí ó padà wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó kó ipa àkọ́kọ́ pẹ̀lú àwọn òṣèré Nollywood nínú fiimu èdè Yoruba tí àkòrí rẹ jẹ́ "ìwọ tàbí Èmi" ní ọdún 2013. Adunni tún ti kópa nínú àwọn sinimá oríṣiríṣi ní ède Yoruba àti ní ède Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú àwọn orin fídíò fún Sound Sultan àti Ice Prince.[3][4] Ó gba àmì ẹ̀yẹ ti Stella láti ọwọ́ Nigerian Institute of Journalism fún akitiyan rẹ̀ lórí i gbígbé àṣà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ga.[5] Ní ọdún 2017, ó di aṣojú ìyàsọ́tọ̀ fún OUD Majestic.[6]

Ìgbésí ayé rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adunni bí ọmọ ọkùrin méjì. Orúkọ wọn ni D'Marion àti Ayden. Ó sọ wípé lẹ́yìn tí òun ti ṣe ìpinnu tí ó nira láti yà pẹ̀lú bàbá wọn, òun yí ò tẹ̀síwájú láti jẹ́ òbí ànìkànjọ̀kan.[7][8][9]

Filmography rẹ tí a yàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fiimu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Iwo tabi emi (You or I) (2013)[10][11]
  • What's Within (2014)
  • 2nd Honeymoon (2014)
  • Head Gone (2015)
  • So in Love. (2015)
  • Schemers (2016)
  • Diary of a Lagos Girl (2016)
  • Diary of a Lagos girl (2016)
  • For The Wrong Reasons (2016)
  • It's Her Day (2016) Earned her the nomination for Best Supporting Actress in Africa's biggest Movie Awards, AMVCA in 2017. She also won Best Supporting Actress Award at the Lagos Film Festival for the movie.
  • The Blogger's Wife (2017)
  • Guyn Man (2017)
  • Boss of All Bosses (2018)
  • The Vendor (2018)
  • House Of Contention (2019)
Tẹlifisiọnu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Behind the Cloud
  • Babatunde Diaries
  • Jenifa's Diary Season 2
  • Sons of the caliphate Season 2

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "I'm a sucker for Love". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics. 2015-02-20. Retrieved 2020-10-05. 
  2. "Nollywood Actress Adunni Ade Reveals Nationality, Says Marriage Not In Her Agenda". NaijaGists.com. 2016-09-10. Retrieved 2020-10-05. 
  3. "I was extremely nervous in my first movie – Adunni Ade, actress". The Sun Nigeria. 2017-09-17. Retrieved 2020-10-05. 
  4. "'Why I debuted in Saidi Balogun's You and I' -Adunni Adewale". Encomium Magazine. 2020-10-04. Retrieved 2020-10-05. 
  5. "ADUNNI ADE APPRECIATES NIJ STUDENTS". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Bosnia). 2017-05-26. Retrieved 2020-10-05. 
  6. Tw (2017-09-19). "Adunni Ade and Bolanle Ninolowo Unveil The #OUDMAJSETICINSPIREMAGIC Ad Campaign For Oud Majestic Luxury Perfume Store". TW Magazine Website. Archived from the original on 2018-01-24. Retrieved 2020-10-05.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "Check out Actress Adunni Ade and her Adorable Two Sons". Nigeria Films. Retrieved 2020-10-05. 
  8. "I'm a sucker for Love". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2015-02-20. Retrieved 2020-10-05. 
  9. "Entertainment News - All Entertainment & Celeb News". Legit.ng - Nigeria news. 2020-10-05. Retrieved 2020-10-05. 
  10. "8 things you should know about Adunni Ade". The Pulse. http://www.pulse.ng/entertainment/movies/adunni-ade-8-things-you-should-know-about-actress-id5122254.html. Retrieved January 22, 2018. 
  11. "I'm Proud Of My Yoruba Background – Actress, Adunni". Naij. Archived from the original on July 24, 2018. https://web.archive.org/web/20180724032510/https://www.naija.ng/57882.html. Retrieved January 22, 2018.