Jump to content

Ahmed Marafa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ahmed Marafa
Speaker of the Niger State House of Assembly

Ahmed Mohammed Marafa jẹ́ olóṣèlú orílẹ̀ Nàìjíríà Nigeria, ẹni tí wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ́ bíi abẹnugan kẹjọ ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti Ìpínlẹ̀ Náíjà (Niger State) ní ọdún 2015. Wọ́n dìbò yan Marafa sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti Ìpínlẹ̀ láti agbègbè Chanchaga nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ọlọ́wọ̀ (All Progressives Congress). Bashir Lokogoma ẹni tí ó ń ṣojú ẹkùn-ìdìbò Wushishi ni ó dábàá yíyàn án sí ipò abẹnugan tí Bako Alfa ẹni tí ó ṣojú ẹkùn-ìdìbò àríwá Bida sì kejì àbá náà.[1][2][3] Lẹ́yìn tí ó búra ìyàn sípò, Ó ní òun yóò ṣe àgbékalẹ̀ àwọn òfin tí ó ní láárí tí yóò gbé ipò àwọn ènìyàn.

Ní oṣù kọkànlá ọdún 2015, wọ́n dìbò yan Marafa gẹ́gẹ́ bíi Alága ìgbìmò àwọn abẹnugan tí wọ́n ń bẹ ní ẹkùn àríwá orílẹ̀ Nàìjíríà, èyí tí ó kó àwọn abẹnugan ilé ìgbìmọ aṣòfin Ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlógún jọ.[4][5] Lásìkò ètò ìdìbò ọdún 2019, àwọn ọ̀dọ́ fi Marafa ṣe ẹlẹ́yà nípasẹ̀ orin tí wọ́n ń kọ 'ìgbà kan péré' sí i. Orin náà túmọ̀ sí pé wọn kò ṣe àtìlẹ́yìn fún àtúndì ìbò rẹ̀ fún ìgbà kejì ní ilé ìgbìmọ̀ àwọn aṣòfin Ìpínlẹ̀ náà. Àwọn ọ̀dọ́ mẹrin tí wọ́n lọ́wọ́ sí ìwà yìí ni ọwọ́ òfin tẹ̀ tí wọ́n sì fi ojú wọn ba ilé-ẹjọ́ Májísíréètì lórí ẹ̀sùn mẹ́ta tí wọ́n fi kàn wọ́n, ẹ̀sùn ìkóra ẹni jọ hùwà àìda, fífi ìnira kan ni, àti ìwà ìkà.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Niger Assembly elects Marafa as Speaker - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-06-09. Retrieved 2020-06-13. 
  2. "Niger State Speaker, Rt. Hon. Marafa Ahmed commends the House For Outstanding Performance". Nigerian Voice. Retrieved 2020-06-13. 
  3. "Niger State Speaker tasks youths on skills acquisition". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-03-26. Retrieved 2020-06-13. 
  4. Blueprint (2015-11-30). "Northern speakers' forum elects Marafa as new chair" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-13. 
  5. Kwaran, Independent. "Niger Speaker Emerges Chair, Northern Speakers Forum | fresh news and views" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-06-13. Retrieved 2020-06-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)

Àdàkọ:Nigeria-politician-stub