Aisha Abubakar Abdulwahab
Ìrísí
Aisha Abubakar Abdulwahab | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ọdún 1971 |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà |
Gbajúmọ̀ fún | proposing novel research to study tuberculosis |
Àwọn ọmọ | Méjì |
Dr. Aisha Abubakar Abdulwahab (tí a bí ní ọdún 1971) jẹ́ ọlọ́pá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí UNESCO fún ní ẹ̀bùn owó láti ṣe ìwádìí nípa ààrùn ikó ààrùn Tuberculosis.
Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Aisha Abubakar Abdulwahab ní ọdún 1971 ó sì dara pọ̀ mọ́ egbé ọlọ́pá Nàìjíríà ní ọdún 1995. Ó ní àmì ẹyẹ nínú ìmò veterinary science.[1]
Ní ọdún 2005, UNESCO fun ní ẹ̀bùn owó fún àbá rẹ̀ láti fi DNA wádìí ǹkan tó pa ààrùn tuberculosis tó ń pa ènìyàn lára àti èyí tó ń pa màlúù lára. Ó ní pé tó n bá gba omi lára ènìyàn àti lára màlúù, òun le mọ bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń kọ́ àìsàn nípa mí mu omi oyàn màálù tí wọn kò tí sè.[2] UNESCO fun ní ẹ̀bùn owó náà láti parí ìwádìí rẹ̀ ní Yunifásitì tí ó bá fẹ́. Adbulwahab ní ọkọ àti ọmọ méjì.[1]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Female cop bags UNESCO award Archived 2016-03-04 at the Wayback Machine., 2005, OnlineNigeria, Retrieved 8 February 2016
- ↑ Science needs women, UNESCO.org, Retrieved 9 February 2016