Jump to content

Akah Nnani

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Akah Nnani
Ọjọ́ìbíAkah Nnani
31 January
Port Harcourt, Rivers State
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́
  • Pampers Private School
  • Topgrade Secondary School
Iléẹ̀kọ́ gígaCovenant University
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́2014
Gbajúmọ̀ fún
Olólùfẹ́
Claire Idera (m. 2019)

Akah Nnani jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olóòtú èò lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, àti òṣìṣẹ́ orí YouTube. Ó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù àgbéléwò Banana Island Ghost, èyí tó mu kí wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún ti The AMA Awards fún òṣèrékùnrin tó dára jù, ní ọdún 2018 àti 2019. NÍ ọdún 2022, ó kópa nínú fíìmù Netflix kan, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Man of God, ẹ̀dá-ìtàn tó sì ṣe ni Samuel Obalolu.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
I had planned on becoming an actor but I wasn't confident enough and was discouraged, till Ric Hassani, talked me into auditioning for the Africa Magic Original Film "Redemption", where I got my first acting role

The Punch - [1]

Akah Nnani wá láti Ipinle Imo,[1] wọ́n sì bi ní January 31, ní Port Harcourt, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pẹ̀lú àbúrò mẹ́ta.[1] Bàbá rẹ̀ jẹ́ oṣiṣẹ́ ní Immigration office, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò.[1] Ó lọ sí ilé-ìwé Pampers Private School, ní Surulere, fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ilé-ìwé Topgrade Secondary School ló sì ti kọ́ ẹ̀kọ́ girama, ní Surulere.[1] Ó gboyè B.Sc. nínú ẹ̀kọ́ Mass Communication láti Covenant University.[1]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni àtòjọ àwọn fíìmù àgbéléwò tí Akah Nnani kópa nínú.

Ọdún Fíìmù Ojúṣe Ọ̀rọ̀
2017 Isoken Ifeayin Drama
2017 Banana Island Ghost Sergeant Drama
2017 The Royal Hibiscus Hotel Tobem Comedy
2018 Lara and the Beat G Diddy Drama
2019 Makate Must Sell
2020 Ratnik Seargent Action
2020 Omo Ghetto: The Saga Mario Gangster Comedy
2021 Ghana Jollof Romanus Comedy Drama
2021 My Village people Village Driver Comedy Drama[2]
2022 Man of God Samuel Obalolu Drama

Fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Ètò Ojúṣe Ọ̀rọ̀
2014-2015 Entertainment Splash Host TVC Entertainment
2016 One Chance Lead Role Ndani TV
2016-2017 On the Real Supporting Role EbonyiLife TV
2017 Shade Corner Host Accelerate TV
2019 Jenifa's Diary Recruited Africa Magic Showcase

Àwọn eré orí-ìtàgé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àkọ́lé Ọdún Ojúṣe Ọ̀rọ̀
Heartbeat The Musical 2016 Muson Centre

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Àmì-ẹ̀yẹ Ìsọ̀rí Ẹni tó yàn án Èsì
2017 The Future Awards Africa Prize for Acting Himself Wọ́n pèé
2018 14th Africa Movie Academy Awards Africa Movie Academy Award for Best Actor in a Supporting Role Himself / "B.I.G" Wọ́n pèé
2019 15th Africa Movie Academy Awards Wọ́n pèé

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]