Akinola Maja
Oloye Akinola Maja, M.D jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, oníṣòwò, onínúrere àti olóṣèlú ẹni tí ó jẹ́ ààrẹ fún ẹ̀ka àwọn ọ̀dọ́ ti ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigeria Youth Movement) láti ọdún 1944 sí ọdún 1951. Lẹ́hìnná àn ni ó wá di ààrẹ fún Ẹgbẹ́ Ọmọ Oduduwa ní ọdún 1953.[1]
Chief Akinola Maja M.D. | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Sope Akinola Pearce Lagos |
Aláìsí | 1976 |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Doctor, businessman, politician |
Olólùfẹ́ | Comfort Obasa Maja |
Parent(s) | James Adaramaja Pearce (father) |
Àwọn olùbátan | Lola Maja (granddaughter) |
Oloye Maja jẹ oyè ti Bàbá Èkó àti Jagunmólú ti Orílé-Ìjàyè.
Gẹ́gẹ́ bí i akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn òyìnbó, Maja kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè ní ọdún 1981 láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Edinburgh. University of Edinburgh. Ó dúró ní orílẹ̀-èdè aláwọ̀funfun fún ọdún mẹ́ta kí ó tó darí padà wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1921. Ó ṣiṣẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba amúnisìn kí ó tó di wípé ó lọ dá ilé-ìwòsàn ti ara rẹ̀ sílẹ̀.
Ìgbésí Ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Akinola Maja ní a bí ní Sope Akinola Pearce. Orúkọ bàbá rẹ a ma a jẹ́ James Adaramaja Pearce. Iṣẹ́ gbẹ́nọ̀gbẹ́nọ̀ ni bàbá rẹ n ṣe nígbà tí ìyá rẹ jẹ oníṣòwò búrẹ́dì. Òpópónà Breadfruit (Breadfruit Street) ní Èkó tí ó jẹ́ ibi abínibí rẹ ni wọ́n sọ ní orúkọ yi nítorí iṣẹ́ tí ìyá rẹ ń ṣe. Àwọn mọ̀lẹ́bí Pearces wá láti agbègbè Saro.
Bàbá Maja kú ní ọ̀dọ́. Ikú bàbá rẹ yi ló mú kí wọ́n mu Maja gẹ́gẹ́ bí i ọmọ tí ó gbọ́dọ̀ ní ẹ̀kọ́ tí ó ga jùlọ láti lè tọ́jú ìdílé tí ó kù lẹ́yìn. Ìyá rẹ ṣe ìtọ́jú owó tí ó tó láti rán án Maja lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ní òkè òkun. Lẹ́hìn èyí ni Maja gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Scotland.
Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé Maja ní ọdún 1918, nígbàtí àwọn òyìnbó aláwọ̀funfun kẹ́gàn rẹ nítorí ẹ̀yà tí ó ti wá. Maja ti tayọ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ nínú ẹ̀kọ́ tí ó fi yẹ láti pé kí ó gba ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bi i akẹ́kọ̀ọ́ tí ó peregedé jùlọ níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀gboyè. Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ àti àwọn àlejò tí ó ṣe àbẹ̀wò láti rí i wípé akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ṣe dáradára jùlọ ní ọdún na jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Látàrí àṣìpè orúkọ ìdílé rẹ, wọ́n dá Maja dúró láti lọ ṣe àtúnyẹ̀wò tí yíò fìdí rẹ múlẹ̀ pé ní òtítọ́ Maja ni ó gba ẹ̀bùn yí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn èsì ẹ̀kọ́ rẹ. Bí Maja ṣe ṣàkíyèsi àwọn ẹ̀tanú tí ó wáyé látàrí pé akẹ́kọ̀ọ́ aláwọ̀ dúdú ni ó gba ẹ̀bùn ní àárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, ó pinnu láti kọ orúkọ àjèjì ìdílé rẹ sílẹ̀ tí ó sì ge orúkọ àárín ti ìdílé bàbá tí ó bí bàbá rẹ kúrú láti Adaramaja sí Maja. Maja tún ṣe ìbúra pé kò sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ tí yíò ní orúkọ-ìdílé tí kì í ṣe ti ilẹ̀ Nàìjíríà. Àṣà yí jẹ́ èyí tí àwọn ẹbí Maja lọ́kùnrin ṣi n tẹ̀lé títí di òní.
Lẹ́hìn tí ó padà dé sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò ìjọba amúnisìn (Colonial Nigeria), Maja ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní ilé-iṣẹ́ ọba. Fún àìní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ìrètí ti iṣẹ́ yi yio fun un, Maja lọ láti dá ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ò rẹyìn sí ìlú Èkó.[2]
Ní ọdún 1933, Maja jẹ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ National ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (National Bank of Nigeria) pẹ̀lú àwọn ènìyàn bi i T. A Doherty, Olatunde Johnson àti Hamzat Subair.[3] Ilé ìfowópamọ́ yi jẹ ilé-iṣẹ́ Áfíríkà tí ó dára tí ó sì ní ìbáṣepọ̀ tí ó dánmọ́rán pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group. Lára àwọn tí wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ yi ni wọ́n somọ́ ẹ̀ká àwọn ọ̀dọ́ ti ilẹ̀ Nàìjíríà. National Youth Movement, tí ó fi jẹ́ wípé lẹ́yìn ò rẹyìn ni wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ iṣẹ́ títẹ ìròyìn èyí tí i ṣe akéde tí ìwé ìròyìn Daily Service newspaper. Ìwé ìròyìn Daily Service bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i agbẹnusọ fún ẹ̀ka àwọn ọ̀dọ́ ti ilẹ̀ Nàìjíríà. Ní àárín ọdún mẹ́wàá tí ó sáájú ìgbòmìníra ilẹ̀ Nàìjíríà, Maja ṣe àṣeyọrí oríṣiríṣi nínú okòòwò ṣíṣe. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950, Maja pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sule Gbadamosi láti dá ilé-iṣẹ́ okòòwò ceramic sílẹ̀ ní Ikorodu. Maja tún jẹ́ olùdarí ilé-iṣẹ́ National Investment properties, èyí tí ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group ń lò gẹ́gẹ́ bí i orísun òwò fún ìpolongo ìbò
Maja ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú olóyè Comfort Obasa Maja, ẹni tí í ṣe ọmọbìnrin ọmọ ọba Orisadipe Obasa. Olóyè Obasa Maja jẹ́ Erelú Kuti ti ìlú Èkó. Oyè yí ló sọ ọ́ di yèyé ọba ti ìjọba ìlú Èkó.
Maja ní ọmọ mẹ́rin. Àwọn ẹbí Maja gbé ní Garber Square, ọ̀kan nínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ́sì alájà méjì àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Ní báyì í ibùgbé e wọn jẹ́ òpópónà kan tí ó ṣe pàtàkì ní ìlú Èkó nítorí pàtàkì ìtàn rẹ. Dọ́kítà Oladipo Maja, tí í ṣe ọmọ rẹ jẹ́ ìlú mọ̀ọ́ká dọ́kítà àti onínúrere, ẹni tí ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé ìwòsàn Maja fún ìwòsàn àrùn ojú. Apákan ilé ìwòsàn yí ni ó gba àwọn akọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ oníṣègùn oníṣẹ́ abẹ ojú láti má a ṣe iṣẹ́ abẹ lọ́fẹ̀ ẹ́ fún àwọn afọ́jú àti àwọn tí àrùn ojú ń bájà.
Maja di oloogbe ni odun 1976 ni eni odun mejidinlaadorun un.