Jump to content

Akpanoluo Ikpong Ikpong Ette

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Akpanoluo Ikpong Ikpong Ette
Ọjọ́ìbí23 September 1929
Akwa Ibom State, Nigeria
Aláìsí17 September 2018 (2018-09-18) (ọmọ ọdún 88)
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • educator
  • physicist
  • researcher
AwardsNigerian National Order of Merit Award

Akpanoluo Ikpong Ikpong Ette NNOM (Ọjọ́ kẹta-lé-lógún Oṣù Kẹ́sàn-án, Ọdún 1929 sí Ọjọ́ Kẹta-dín-lógún Oṣù Kẹ́sàn-án, Ọdún 2018) jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Nàìjíríà ti Físíksì àti akọ̀wé tẹ́lẹ̀ àti igbákejì ààrẹ Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìmọ̀ Sáyẹ́nsì Nàìjíríà. Ní ọdún 1991, ó jẹ́ Alákoso Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìmọ̀ Sáyẹ́nsì Nàìjíríà láti rọ́pò Ọ̀jọ̀gbọ́n Caleb Olaniyan. [1]

Ní ọdún 2003, ó gba ààmì-ẹ̀ye ẹ̀kọ́ gíga tí ó ga jùlọ ní Nàìjíríà, Àṣẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti Ẹ̀bùn Merit.[2]

Ayé Àti Ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ette ní Upenekang, láti 1944 sí 1948 ó sì lọ sí Hope Waddell Training Institution, kí ó tó kọ́ ẹ̀kọ́ físíksì ní University College, Ibadan láti ọdún 1949, ó gbóyè pẹ̀lú BSc ní ọdún 1954. Lẹ́hìn tí ó kọ́ni ní Hope Waddell Training Institution láti 1954 sí 1959, ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, PhD ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn láti ọdún 1959 sí 1966 l'ákòókò tí ó ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ kan náà. Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ní ọdún 1972.[3]

Ette kú ní ọdún 2018.[3]

  1. "Members of Council". Nigerian Academy of Science. Archived from the original on 7 July 2015. Retrieved 7 June 2015. 
  2. "Two Academics Bag 2003 Merit Award". Business HighBeam. Archived from the original on 10 July 2015. Retrieved 9 June 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. 3.0 3.1 "OBITUARY Professor Akpanoluo Ikpong Ikpong Ette, FNIP, FSAN, FAS, NNOM (23 September, 1929 - 17 September, 2018)" (PDF). Bulletin. University of Ibadan. 12 November 2018. Retrieved 9 December 2019.