Aláàfin Ọ̀rọ̀mpọ̀tọ̀
Orompoto/Oronpoto | |
---|---|
Iṣẹ́ | Alaafin of Oyo |
Orompoto (tí wọ́n tún máa ń kọ bí i Oronpoto)[1] fìgbà kan jẹ́ Aláàfin ti ìlú Ọ̀yọ́.[2][3][4][5] Ìlú tó darí nígbà náà wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn àti apá Àríwá mọ́ Ààrin-gbùgùn ilẹ̀ Nàìjíríà.[6]
Ìtàn rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Orompoto ní àbúrò Aláàfin Eguguojo tó wà lórí oyè kí òun tó jọba.[7]Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó máa jẹ oyè aláàfin ti ìlú Ọ̀yọ́ lásìko náà, tó sì tún jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó máa jẹ oyè Yeyeori.[8] Orompoto gun orí oyè nítorí kò sí ọkùnrin kankan nínú ìdílé wọn tó máa gorí oyè lásìkò náà. [9] Ó rí sí bí wọ́n ṣe lé àwọn Nupe kúrò ní Ọ̀yọ́ ní ọdún 1555.[8] Orompoto jọba ní sẹ́ńtúrì kẹrìndínlógún.[10][11]
Orompto jẹ́ ọba kejì tó máa jọba ní olú-ìlú tuntun, tí ó wà ní Igboho.[12] Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu kan fi lélẹ̀ pé ó di ọkùnrin kí ó tó gotí oyè.[12]
Orompoto máa ń lo ẹṣin nígbà kugbà tó bá fẹ́ lọ jagun, èyí tí ìtàn fi lélẹ̀ pé ójọgún lọ́wọ́ Borgu.[13] Ó mọ ẹsìn gùn dáradára, ó sì ní àwọn ẹs̀ọ́ tó máa ń gba àṣẹ́ lọ́wọ́ Èso ikoyi.[14] Ó jẹ́ jagunjagun tó mọ ogun jà, ó sì bá wọn jagun pẹ̀lú àwọn ará Illayi. Lásìkò tih ó ń jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó pàdánù Balógun mẹ́tà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, oyè Balógun sì ni wọ́n ń pè ní Gbonkas ní ìlú Ọ̀yọ́.
Aláàfin Ajíbòyèdé ló jẹ Aláàfin lẹ́yìn rẹ̀.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Harry George Judge; Robert Blake (1988). World history, Volume 1 (Volumes 3-4 of Oxford illustrated encyclopedia). Oxford University Press (University of Michigan). p. 266. ISBN 9780198691358. https://books.google.com/books?id=OokYAAAAIAAJ&q=oronpoto.
- ↑ Toyin Falola; Ann Genova (2006). The Yoruba in Transition: History, Values, and Modernity. Carolina Academic Press (University of Michigan). p. 427. ISBN 9781594601347. https://books.google.com/books?id=YFt0AAAAMAAJ&q=orompoto.
- ↑ Jean Comaroff, John L. Comaroff (1993). Modernity and Its Malcontents: Ritual and Power in Postcolonial Africa. University of Chicago Press. p. 63. ISBN 978-0-226-1143-92. https://books.google.com/books?id=bT_Da35lFvoC&q=Orompoto+alaafin+of+Oyo&pg=PA63.
- ↑ Oyeronke Olajubu (2003). Women in the Yoruba Religious Sphere (McGill Studies in the History of Religions). SUNY Press. p. 89. ISBN 9780791458860. https://books.google.com/books?id=RTGnPAB4puAC&pg=PA89.
- ↑ Kulwant Rai Gupta (2006). Studies in World Affairs, Volume 1. Atlantic Publishers & Dist. p. 101. ISBN 9788126904952. https://books.google.com/books?id=Hw9uf7sRKtIC&q=orompoto+female&pg=PA101.
- ↑ "Chronology of Oyo Kingdom's Alaafins". Odua Voice. Archived from the original on February 25, 2018. Retrieved February 23, 2018.
- ↑ Oyèrónkẹ́ Oyěwùmí (2005). African Gender Studies: A Reader. Springer. p. 178. ISBN 9781137090096. https://books.google.com/books?id=RlUBDgAAQBAJ&pg=PA179.
- ↑ 8.0 8.1 Toyin Falola; Ann Genova (2006). The Yoruba in Transition: History, Values, and Modernity. Carolina Academic Press (University of Michigan). p. 427. ISBN 9781594601347. https://books.google.com/books?id=YFt0AAAAMAAJ&q=orompoto.
- ↑ J. Lorand Matory (2005). Sex and the Empire That Is No More: Gender and the Politics of Metaphor in Oyo Yoruba Religion (Berghahn Series). Berghahn Books. p. 84. ISBN 9781571813077. https://books.google.com/books?id=Jfe9BAAAQBAJ&pg=PA84.
- ↑ "Chronology of Oyo Kingdom's Alaafins". Odua Voice. Archived from the original on February 25, 2018. Retrieved February 23, 2018.
- ↑ Basil Davidson (2014). West Africa Before the Colonial Era: A History to 1850. Routledge. p. 114. ISBN 9781317882657. https://books.google.com/books?id=4SEiBQAAQBAJ&pg=PA114.
- ↑ 12.0 12.1 Matory, James Lorand (2005). Sex and the empire that is no more : gender and the politics of metaphor in Oyo Yoruba religion. Berghahn Books. ISBN 1571813071. OCLC 910195474.
- ↑ Samuel Johnson, Obadiah Johnson. The History of the Yorubas, From the Earliest of Times to the Beginning of the British Protectorate. p. 161.
- ↑ Harry George Judge; Robert Blake (1988). World history, Volume 1 (Volumes 3-4 of Oxford illustrated encyclopedia). Oxford University Press (University of Michigan). p. 266. ISBN 9780198691358. https://books.google.com/books?id=OokYAAAAIAAJ&q=oronpoto.