Amina Titi Atiku-Abubakar

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Amina Titi Atiku-Abubakar
Second Lady of Nigeria
In role
29 May 1999 – 29 May 2007
Vice PresidentAtiku Abubakar
First LadyStella Obasanjo
AsíwájúMrs. Akhigbe
Arọ́pòPatience Jonathan
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Titilayo Albert

6 Oṣù Kẹfà 1951 (1951-06-06) (ọmọ ọdún 72)
Ilesha, Southern Region, British Nigeria (now Ilesha, Osun State, Nigeria)
(Àwọn) olólùfẹ́
Atiku Abubakar (m. 1971)
Alma materKaduna Polytechnic

Amina Titilayo Atiku-Abubakar jé òkan lara awon ìyàwó Atiku Abubakar, èni to jé ígbákejì ààre orílè-èdè Nàìjirià teleri.[1] Ó jé oluja feto àwon obinrin àti omodé, oun ni olùdásílè àjo Women Trafficking and Child Labour Eradication Foundation(WOTCLEF).[2] Oun ni ojé obinrin ekeji(Second lady) tí Nàìjirià láti May 29, 1999 sí May 29, 2007

Àárò ayé àti èkó rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Amina sí idile Kristeni, idile Albert to jé idile kan ní ìlú Ilesa, ìpínlè Osun.[3] Ó dagba ní ìlú Eko, ó sì lo ilé-ìwé primari rè ní Lafiagi, ìpinlè Eko kotodipe o lo si St. Mary's Iwo ti ìpínlè Osun fún ìwé Sekondir rè tótó di 1969.[4] Ní 1971, Titi fé Atiku-Abubakar kotodipe ó tèsíwájú ìwé rè ni polytechnic ti Kaduna.[5] O le so ede Òyìnbó, Yoruba àti Hausa dada, o yí pada láti Kristeni di musulumi.[6]

Isé rè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Titi sisé gegebi olukoni polytechnic ti Kaduna.[4]

Nígbà tí o lo sí Rome láti tèsíwájú ìwé rè ni 1986 àti 1987, ó rí òpòlopò omobinrin Nàìjirià nigboro ibè. Nígbà tí o se iwadi, o ri wipe òpòlopò awon omobinrin náà nse Àsèyí láti mú owo wa fún àwon ogabinrin wón,[4] ní òpòlopò ìgbà, àwon ògá àwon omobinrin yìí kò ún sanwo fún won. O tún ri pé wón titan òpòlopò obinrin lo sí Italy nipase síse ileri isé fún won loke okun. Èyí mú kí Titi se ileri pé òun ma fi gbogbo òun tobagba láti koju rè.

WOTCLEF àti NAPTIP[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní odun 1999, nígbà tí oko rè, Atiku Abubakar di ígbákejì Ààré Nàìjíríà, o bèrè ikede àti ipolongo láti dá fifi agbara mú ènìyàn se asewo dúró àti láti da jiji ènìyàn gbé dúró.

Èyí ló mú kí ó dá Women Trafficking and Child Labour Eradication Foundation(WOTCLEF) àti National Agency for Prohibition of Trafficking in Persons.

Àwon Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Report, Agency (2018-11-18). "How I met, married Atiku - Titi Abubakar". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-05-29. 
  2. "Women Trafficking and Child Labour Eradication Foundation (WOTCLEF)". The Communication Initiative Network. 2011-03-21. Retrieved 2022-05-29. 
  3. The News. Independent Communications Network Limited. 2002. https://books.google.com/books?id=pj8uAQAAIAAJ. Retrieved 2022-05-29. 
  4. 4.0 4.1 4.2 "Hajiya Titi Abubakar: Working to restore human dignity". weekend.peoplesdailyng.com. 2017-08-23. Archived from the original on 2017-08-23. Retrieved 2022-05-29.  Unknown parameter |url-status= ignored (help) Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "weekend.peoplesdailyng.com 2017" defined multiple times with different content
  5. Onukaba, A.O. (2006). Atiku: The Story of Atiku Abubakar. Africana Legacy Press. https://books.google.com/books?id=0p8uAQAAIAAJ. Retrieved 2022-05-29. 
  6. Emerole, J. (2002). Amazing Crusade: Media Portrait of the Titi Atiku Abubakar War Against Human Trafficking. Amazing Crusade: Media Portrait of the Titi Atiku Abubakar War Against Human Trafficking. https://books.google.com/books?id=hnGLAAAAIAAJ. Retrieved 2022-05-29.