Angélique Kidjo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Angélique Kidjo
Angélique Kidjo performing in Cotonou, 2017
Ọjọ́ìbíAngélique Kpasseloko Hinto Hounsinou Kandjo Manta Zogbin Kidjo[1][2][3]
Oṣù Keje 14, 1960 (1960-07-14) (ọmọ ọdún 63)
Ouidah, French Dahomey (now Benin)
Iṣẹ́
Olólùfẹ́
Jean Hébrail (m. 1987)
Àwọn ọmọ1
Websitekidjo.com
Musical career
Irú orin
Instruments
  • Vocals
Years active1982–present
Labels
Associated acts

Àdàkọ:Advert

Angélique Kpasseloko Hinto Hounsinou Kandjo Manta Zogbin Kidjo,[1][2][3] known as Angélique Kidjo (born July 14, 1960), jẹ́ gbajúmọ̀ olórin, òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò, ajìjàǹgbara ọmọbìnrin láti orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin Beninese, tí ó tún míràn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ olórin-bìnrin nípa Ìṣẹ̀wọ́ kọrin àti fídíò orin lọ́nà àrà. Lọ́dún 2007, gbajúgbajà ìwé ìròyìn àgbáyé nì, Time Magazine júwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú olórin-bìnrin nílẹ̀ Áfíríkà, "Africa's premier diva".[4]

Gbajúmọ̀ nínú àwọn orin rẹ̀ máa ń dá lórí ẹ̀yà orin tí wọ́n ń pè ní Afropop, Caribbean zouk, Congolese rumba, jazz, Orin ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, àti Latin; bẹ́ẹ̀, àwọn orin rẹ̀ máa ń dá lé àwọn olórin àtijó tí ó kúndùn láti ìgbà èwe rẹ̀, àwọn olórin bí i Bella Bellow, James Brown, Nina Simone, Aretha Franklin, Celia Cruz, Jimi Hendrix, Miriam Makeba àti Carlos Santana. Ó ti kọ àwọn ẹ̀dà orin tí olórin àtijó George Gershwin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Summertime", Ravel's Boléro, Jimi Hendrix's "Voodoo Child" àti the Rolling Stones' "Gimme Shelter", bẹ́ẹ̀ náà dára pọ̀ mọ́ Dave Matthews àti Dave Matthews Band, Kelly Price, Alicia Keys, Branford Marsalis, Ziggy Marley, Philip Glass, Peter Gabriel, Bono, Carlos Santana, John Legend, Herbie Hancock, Josh Groban, Dr John, the Kronos Quartet, Yemi Alade, Cassandra Wilson àti gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé orílẹ̀-èdè Indonesia, Anggun. Lára àwọn orin Kidjo tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni "Agolo", "We We", "Adouma", "Wombo Lombo", "Afirika", "Batonga", àti ọ̀wọ́ orin "Malaika" tirẹ̀. Àwo orin rẹ̀, Logozo ni wọ́n yàn nípò kẹtàdínlógójì nínú àwọn gbajúmọ̀ orin àlùjó tó gbajúmọ̀ jùlọ ní àgbáyé, gbajúmọ̀ ìwé-ìròyìn àgbáyé nì, Vice Magazine ló ṣe agbátẹrù rẹ̀ ní ìkànnì ayélujára wọn.[5]

Kidjo gbọ́ èdè márùn-ún ní àgbọ́dunjú, àwọn èdè náà ni: Fon, Faransé , Yorùbá, Gen (Mina), àti èdè Gẹ̀ẹ́sì.[6] Ní àwọn èdè yìí ló fi kọ àwọn orin rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà o ní àwọn àkànlò-èdè orin tìrẹ tí ó lò ní àkọ́lé orin rẹ̀ bí i "Batonga". "Malaika" jẹ́ àkọ́lé orin tí ó kọ lédè Swahili. Kidjo sáàbà máa ń kọ àwọn orin rẹ̀ ni Ìpèdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní often uses Benin's traditional Zilin àti vocalese.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 [1] Archived October 20, 2012, at the Wayback Machine.
  2. 2.0 2.1 "Africa | Time for Peace". Africatimeforpeace.com. Archived from the original on 2012-03-31. Retrieved 2012-04-03.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. 3.0 3.1 "Albums by Angélique Kidjo". Rate Your Music. Retrieved 2012-04-03. 
  4. Perry, Alex (May 23, 2007). "Redemption Song". Time. Archived from the original on June 16, 2007. https://web.archive.org/web/20070616063517/http://www.time.com/time/magazine/article/0,9171,1624366,00.html. 
  5. "The 99 Greatest Dance Albums of All Time". Thump.vice.com. 2015-07-14. Retrieved 2016-05-16. 
  6. "Angélique Kidjo - Bénin | cd mp3 concert biographie news | Afrisson". Afrisson.com (in Èdè Faransé). Archived from the original on 2020-01-14. Retrieved 2018-07-03.