Ìṣekúpa Abraham Lincoln

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìṣekúpa Abraham Lincoln
Ìṣekúpa ààrẹ Abraham Lincoln (Currier & Ives, 1865), lati òsì sí ọ̀tún: Major Henry Rathbone, Clara Harris, Mary Todd Lincoln, Abraham Lincoln, àti apànìyàn, John Wilkes Booth
Àtẹ̀jáde yìí ṣe àfihàn wípé Rathbone rí Booth tí ó wọ ibi tí ààrẹ wà tí ó sì ti dìde bí Booth ṣe yin ìbon. Ní tòótọ/ , Rathbone ò mọ oun tí Booth fẹ́ lọ sè ṣùgbọn o dá si lẹ́yìn tí ó yìnbọn.
LocationOrí ìtàgé Ford, Washington, D.C.
DateOṣù Kẹrin 14, 1865 (1865-04-14)
10:15 p.m. (Aago apá-ìwọoòrùn)
Weapon(s)
Death(s)Ẹyọ kan (Abraham Lincoln)
InjuredMẹ́rin
Belligerent(s)John Wilkes Booth àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀

John Wilkes Boot ṣekú pa Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Abraham Lincoln ní ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ kẹrìnlá Oṣù kẹrìnlá, Ọdún 1865, nígbà tí ó lọ wo eré Our American Cousin ní ilé ìṣeré orí ìtàgé Ford bí ogun abẹ́lé Amẹ́ríkà ṣe ń lọ sí òpin.[1] Ìpànìyàn yìí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ karún tí balógun ti ológun dìmọlú ti gúúsù Virginia, ọ̀gágun  Robert E. Lee jọ̀wọ́ ara rẹ̀  àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fún ọ̀gágun Ulysses S. Grant tí ó jẹ́ ọ̀gạ́gun pátápátá àti ti àwọn ìṣọ̀kan ológun ti Potomac. Lincoln jẹ́ ààrẹ Amẹ́ríkà àkọ́kọ́ tí àwọn agbanipa máa pa.[2] Ìgbìyanjú àkọ́kọ́ ti ṣẹlẹ̀ lórí Andrew Jackson ní bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn kí wọ́n tó pa Lincoln ní ọdún 1835, tí Lincoln fúnra rẹ̀ sí jẹ́ sábàbí ìpànìyàn tó jásí pàbó nígba tí apànìyàn kan tí a kò mọ̀ fẹ́ paá ní Oṣù kẹjọ Ọdún 1864. Ìṣekúpa Lincoln jẹ́ oun tí wọ́n gbèrò tí ó sì jẹ́ wípé ògbónta òṣèré orí ìtagé, John Wilkes Booth, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ bí ẹní mọwó ni ó ṣe iṣẹ́ láabi yìí, tí ó jẹ́ ìpàdí ààpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan fún ìdí ìṣọ̀kan.

Àwọn ẹlẹgbẹ́ Booth tí wọ́n di rìkíṣí yìí ní Lewis Powell àti David Herold, tí wọ́n yàn lati pa akọ̀wé ìlú William H. Seward àti George Atzerodt tí wọ́n fún ní iṣẹ́ lati pa Igbákejì ààrẹ Andrew Johnson. Bákan náà, kí wọ́n pa àwọn olórí mẹ́ta nínú ìjọba, Booth àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ní ìrètí lati dojú ìjà kọ ìjọba Àwọn Ìpínlẹ̀ Àṣọ̀kan Àmẹ́ríkà. Wọ́n yin Lincoln nígbọn nígbà tí ó ń wo eré ìtàgé Our American Cousin pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀  Mary Todd Lincoln ní ilé ìṣeré orí ìtàgé Ford ní Washington, D.C.. Ó kú ní agogo méje lé ìṣẹ́jú méjìdínlógún àárọ̀.[3] Ìgbìyànjú àwọn oní rìkíṣí tó kù jásí pàbó; Powell kàn ṣe Seward léṣe,  Atzerodt tí ó fẹ́ pa Johnson sì ferége.  Ètò ìsìnkú àti ìsìnkú Abraham Lincoln jẹ́ àkókò ọ̀fọ̀ fún gbogbo ìlú.

Ṣíṣọ pa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìgbìyànjú Àkọ́kọ́: Ìfipá jí ààrẹ gbé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

John Wilkes Booth

Ní bíì ìparí ọdún 1860, Booth tí darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn Knights of the Golden Circle ní ìlú Baltimore.[4] Ní Oṣù kẹta Ọdún 1864, Ulysses S. Grant, tí ó jẹ́ balógún fún ìṣọ̀kan àwọn olọgun ṣetán lati fòpin sí pàṣípààrọ̀ àwọn tí wọ́n mú lójú ogun.[5] Bí ó ti lẹ̀wù kí ó burú tó, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ológun méjèèjì niwọ́n, Grant rìi wípé pàṣípààrọ̀ yìí ń jẹ́ ki ogun yìí máa gbòrò síi, tí ó ń jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun tí ó ń padà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun tí ó wà ní gúúsù máa tó. John Wilkes Booth, tí ó jẹ́ ara apa Gúúsù, tí ó sì já fáfá nínú ìsọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan ṣe ètò lati fipá jí ààrẹ gbé kí ó sì mu fún àwọn Ologun ìṣọ̀kan, títí di ìgbà tí àwọn àríwá á fi gbà láti padà sí fífi ẹlẹ́wọ̀ ṣe pàṣípààrọ̀.[6]:130–134 Booth gba ọmọṣẹ́ Samuel Arnold, George Atzerodt, David Herold, Michael O'Laughlen, Lewis Powell (tí wọ́n tún mọ̀ sí  "Lewis Paine"), àti John Surratt lati ran-án lọ́wọ́. Ìya Surratt, Mary Surratt, fi ibi tí ó ti ń ta ọtí sílẹ̀ ní  Surrattsville, Maryland, ó sì lọ sí ilé kan ní  Washington, D.C., níbi tí Booth ti ń báa lálejò. Bí ó tilẹ̀jẹ́ wípé  Booth àti Lincoln kò mọ ara wọn rí, Lincoln mọ̀ nípa Booth, ó sì ma ń fẹ́ràn lati máa wo eré rẹ̀ ní orí ìtàgé Ford. Lincoln ti wo Booth ní oríṣiríṣi eré ìtàgé tí ó ti ṣe ní orí ìtàgé Ford, pẹ̀lú ìkan tí wọ́n ń pè ní Marble Heart ní orí ìtàgé Ford ní Ọjọ́ kẹsán Oṣù kọkànlá, Ọdún 1863. Washington Chronicle pèé ni "eré tí ó rẹwà tí ó sì tí ó fún ni ní ẹ̀dùn ọkàn" tí Booth aì gba àwọn àyẹ̀wò agbohùn tí ó dára fún ipa tí ó kó nínú eré yìí́. Gẹ́gẹ́ bi ìwé  Lincoln's Sanctuary: Abraham Lincoln and the Soldiers' Home, Lincoln máa ń gbádùn eré Booth tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó sì ti fi ìwé ránṣẹ́ síi lẹ́yìn ìtàgé pé kí ó wá bá oun la ̣lejò ní Ilé funfun tí ó ń gbé kí wọ́n lè pàdé. Booth, tí ó jẹ́ agbẹ̀yìn bẹbọjẹ́ àti alami fún Ìṣọ̀kan kọ̀ lati jẹ́ ìpè ààrẹ. Booth kò fún Lincoln ní ìdí kan pàtó tí kò fi wá ṣugbọ́n ó pàpà sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wípé "Ó tẹ́mi lọ́rùn kí àwọn ènìyàn dúdú yìn mí ju kí ààrẹ yìn mí"

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Inside Lincoln's White House, òṣèré Frank Mordaunt jẹ́rí sí ìtàn yìí:

"Lincoln fẹ́ràn arákùnrin tí ó ṣekú paá. Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí o sọ fún mi lọ́jọ́kan wípé ó ní ọ̀dọ̀mọkùnrin òṣèré kan ní orí ìtàgé Ford tí ó wu ohun lati pàdé, ṣùgbọ́n òṣèré yìí kọ́ fún ìdí kan tabí òmíràn lati bá ohun lálejò ní Ilé Funfun. Òṣèré yẹn ni John Wilkes Booth." Booth ti lọ sí ibi ìwúyè Lincoln ẹ̀ẹ̀kejì ní Ọjọ́ kẹrin Oṣù kẹta Ọdún 1865, gẹ́gẹ́ bí àlejò tí àlè rẹ̀ tí ó fẹ́ fẹ́ Lucy Hale, ọmọbìrin  John P. Hale, láìpẹ́ tí ó dí aṣojú United States ní Spain. Lẹ́yìn ìgbà náà, Booth kọ ọ̀rọ̀ yìí sí ìwé ìràntí rè, "Ànfàni ńlá ni mo ní, tí ó bá wùnmí lati pa ààrẹ ní ọjọ́ ìwúyè ààrẹ!"[6]:174, 437 n. 41

Àwòrán yìí (òkè) tí Lincoln ti ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n yàn-an gẹ́gẹ́ bí ààrẹ́ ní ìgbà kejì jẹ́ àwòràn kan ṣoṣo tí a mọ̀ tí ó jẹ/ ti ayẹyẹ yìí. Lincoln dúró sí àárín, pẹ̀lú ìwé lọ́wọ́. John Wilkes Booth ṣe é rí nínú àwòrán yìí, lókè lọ́wọ́ ààrín (Funfun, Ààrẹ tó já fáfá). Àwòrán kejì ṣe àfihàn Lincoln àti Booth nínú àwòrán tí ó wà lókè.

Ní Ọjọ́ kẹtàdínlógún Oṣù kẹta Ọdún 1865, Booth sọ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé Lincoln máa wá wo eré ìtagé, Still Waters Run Deep, ní Ìlé Ìwòsàn Olófun ti Campbel. Ó kó àwọn ọkùnrin wọ̀nyí jọ sí ilé oúnjẹ kan lẹ́ba ìlú, ní ìgbìyànjú lati dá ọ̀kọ̀ tíó gbé ààrẹ lọ́nà tí ó bá ń padá bọ̀ lati ilé ìwòsàn. Ṣùgbọ́n Lincoln padà mọ̀ wípé ààrẹ kò lọ wo eré ìtàgé. Kàkà kí ó lọ, ó lọ sí ayẹyẹ ní Ilé Ìturà orilẹ̀ èdè wọn, ní ibi tí àwọn ológun ti 142nd Indiana Infantry ti ṣe àfikalẹ̀ Gómìnà Oliver Morton pẹ̀lú àsíá ogun ìṣọ̀kan.[6]:185 Booth ń gbé ní ilé ìtura yìí, tí ó sìlè ní ànfàní lati pa Lincoln tí Booth kò bá lọ sí ilé ìwòsàn.[6]:185–6, 439 n. 17[7]:25 Níbáyí, Ìṣọ̀kan ti ń yapa. Ní Ọjọ́ kẹta Oṣù kẹrin, Richmond, Virginia, Ìpínlẹ̀ Ìṣọ̀kan, bọ́ sọ́wọ́ àwọn ológun àpapọ̀. Ní Ọjọ́ kẹsán Oṣù kẹrin, Ọdún 1865, àwọn ológun àríwá Virginia, àwọn ológú ìṣọ̀kan gangan, jọ̀wọ́ ara wọn fún Àwọn ológun ti Potomac ní Appomattox Court House. Ààrẹ Ìṣọ̀kan, Jefferson Davis,  àti ijọba rẹ̀ tokú bá ẹsẹ̀ wọn sọ̀rọ̀. Àwọn ará Gúúsù tókù gbà fọ́lọ́run, ṣùgbọ́n Booth dúró lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀.[8]:728

Ìdí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní Ọjọ́ kọkànlá Oṣù kẹrin Ọdún 1865, ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Lee jọ̀wọ́ ara wọn fún ológun U.S lábẹ́ àkóso Ulysses S. Grant, Booth attended a speech ní Ìlé funfun tí Lincoln fọwọ́ sí ìtúsílẹ̀ àwọn ẹrú ti tẹ́lẹ̀. Inú bí Booth, ó sì ṣetán ṣekú paá o sọ fún  Lewis Powell:

[7]:6

Àwọn ìfura Lincoln[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lincoln ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ Ilé funfun ní Ọjọ́ kẹfà Oṣù kẹta Ọdún 1865. Àwòrán Lincoln tí a mọ̀ pé ó mọ́ jù rèé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló gbà wípé Lincoln mọ̀ wípé àwọn agbanipa má a pa oun.[9]

Gẹ́gẹ́ bí Ward Hill Lamon, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Lincoln àti olùkọ̀tàn nípa ìgbésíayé, ni ọjọ́ mẹta kí wọ́n tó pa Lincoln, Lincoln jíròrò pẹ̀lú Lamon àti àwọn tókù nípa àlá tí ó lá, ó sọ pé:

Ní bi ọjọ́ kẹwá sẹ́yìn, mo fẹ̀yìntì. Mo ti dìde, ti mo sì ń dúro de iṣé kan tí ó ṣe pàtàkì ní iwájú ìtà. N kò ba má tiẹ̀ pẹ́ lórí ibùsùn ṣùgbọ́n ó rẹ̀mí. Kòpẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní lá àlá. Ó jọ́ pé o ní ṣe ọ̀rọ̀ ikú kan nípa mi. Mò ń gbọ́ igbe ọ̀fọ̀ tí ó dàbí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń su ẹkún. Mo ròpé mo fi ibùsùn mi sílẹ̀ tí mo sì sọ kalẹ̀. Mò ń gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ yìí ṣugbọ́n n kò rí àwọn tí ó ń ṣọ̀fọ̀ náà. Mo ti yàrá kan boị́ sí ibìkan; n kò rí ẹ̀dá alàyè kan, ṣùgbọn ariwo ẹkún ọ̀fọ̀ yìí kò dúró. Mo rí ina ní gbogbo àwọn yàrá, gbogbo àwọn oun tí mo ri kò ṣàjèjì sí mi; ṣùgbọ́n níbo ni àwọn tí ó ń sunkún bi pé àyà wọn ń já yìí wà? Kò yémi, ó sì yàmí lẹ́nu. Kí ló lè fa gbogbo eléyí? Mo pinu latí ṣèwádi ohun ìjayà yìí, mò ń rin kiri títí tí mo fi dé yàrá ìlà oòrùn, tí mo wọ̀.

Mo bá oun ìyanu níbẹ̀. Níwájú mi, mo rí pẹpẹ kan tí wọ́n tẹ́ òkú sí tí wọ́n sì fi aṣọ wé. Àwọn ológun dúró ti òkú náàbi pé wọ́n ń ṣọ; ọ̀pò. ènìyàn sì dúró tí wọ́n yọjú wo òkú náà tọ̀fọ̀tọ̀fọ̀, tí wọ́n sì bòó lójú, tí ẹkún sì ń rọ̀ bí òjò
'talókú ní ilé funfun?' Mo bèrè lọ́wọ́ ìkan lára àwọn ológun tó dúro 'Ààrẹ' ni ìdáhùn rẹ̀; 'àwọn agbanipa ló paá.' Ariwo kan kàn tamíjí ni lójú àlà. N kò lè sùn mọ́ lálẹ́ ọjọ́ náà; bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé à;lá lásán ni, ó ń bàmí lọ́kàn jẹ́ láti ìgbà yen.[10]

Ní ọjọ́ tí wọ́n ṣekú pa, Lincoln sọ fún olùṣọ́ni rẹ̀, William H. Crook, pé ó ti to bi ẹ̀ẹ̀meta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí oun ti n lá àlá pé àwọn agbanipa pa oun. Crook gba Lincoln ní ìmọ̀ràn pé kí ó má lọ wo eré ìtàgé ní Ford ní alẹ́ ọjọ́ náà, ṣùgbọ́n Lincoln sọ pé oun ti ṣèlérí fún ìyàwó oun wípé wọn yìó jọ lọ.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Good Friday, 1865: Lincoln's Last Day" Archived 2017-08-23 at the Wayback Machine..
  2. "Lincoln Shot at Ford's Theater". 
  3. Richard A. R. Fraser, MD (February–March 1995). "How Did Lincoln Die?". American Heritage 46 (1). http://www.americanheritage.com/content/how-did-lincoln-die?page=show. 
  4. Bob Brewer Shadow of the Sentinel, p. 67, Simon & Schuster, 2003 ISBN 978-0-7432-1968-6
  5. "Prisoner exchange".
  6. 6.0 6.1 6.2 6.3 Kauffman, Michael W. (2004).
  7. 7.0 7.1 Swanson, James.
  8. Goodwin, Doris Kearns.
  9. The Diary of Gideon Welles; The History Channel Publishings, Chapter XXVI, April 14, 1865
  10. p. 116–117 of Recollections of Abraham Lincoln 1847–1865 by Ward Hill Lamon (Lincoln, University of Nebraska Press, 1999).

Ìwé àkàsíwájú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]