Ayò ọlọ́pọ́n

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Equipment and initial setup of the Ayoayo game

Ayò ọlọ́pọ́n jẹ́ eré ìdárayá ìbílẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ láàrín Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ayò yí fẹ́ fara pẹ́ Oware tí ó tan kálẹ̀ de orílẹ̀-èdè Amerika, láti ibi òwò-ẹrú. [1]


Ó jẹ́ ọ̀kàn lára àwọn eré àbáláyé. Títa ni à ń ta ayò títa èyí ló bí ìpèdè eré là á fi ọmọ ayò ṣe. Eré pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ni ayò. Èso sẹ́yò ni wọ́n fi ń ṣe ọmọ ayò, ó máa ń dán bọ́rọ́bọ́rọ́. Àwọn gbẹ́nà-gbẹ̀nà ni wọ́n ń gbẹ́ ọpọ́n ayò. tọkùnrin - tobìnrin ló ń ta ayò.  Àwọn àgbàlagbà ni wọ́n ń sábà máa ń ta ayò

Eré Ayò máa ń jẹ́ kí èèyàn ronú jinlẹ̀, ó ń kọ́ni ni sùúrù, àforítì àti ìfaradà. Ó ń pa ìrònú rẹ̀, Ibùdó ìròyìn ni ìdí ayò.

Àwọn Ayò tí ó jọ Ayò ọlọ́pọ́n[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ́pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ayò tí ó jẹ́ eré ìdárayá ìbílẹ̀ tí ó ní òfin bí ti àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ Afíríkà tókù bi Endodoi tí àwọn ẹ̀yà Maasai tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan ní orílẹ̀-èdè Kenya àti Tanzania ń ta. [2]


Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Ayo Olopon; The Game of the Intellectual (An African Board Game)". Scorum.com. 2018-08-02. Retrieved 2020-01-03. 
  2. Tolu (2019-05-10). "NIGERIAN LOCAL GAME: AYO OLOPON". EveryEvery (in Èdè Bosnia). Retrieved 2020-01-03.