Ayẹyẹ ọdún Ọdunde
Odunde Festival | |
---|---|
Odunde Festival celebrated in Southwest Center City in Philadelphia | |
Observed by | Philadelphia, Pennsylvania, USA |
Type | Cultural, commercial |
Date | Second Sunday in June |
2023 date | [[June Àdàkọ:Weekday in month]] |
2024 date | [[June Àdàkọ:Weekday in month]] |
2025 date | [[June Àdàkọ:Weekday in month]] |
Ayẹyẹ ọdún Odunde jẹ́ ayẹyẹ tí wọ́n máa ń fi ọjọ́ kan ṣe, ní ọ̀pọ̀ ìgbà wọn a máa ṣé ní ààrin ọjà fún ìfẹ́ àwọn ènìyàn Áfíríkà àti ti Amẹ́ríkà, àti àwọn tí wọ́n ń bẹ lókè Oya. A le tọpa ọdún yìí lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí wọ́n ń bẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sí ayẹyẹ ìsàmì ọdún tuntun, gẹgẹ bí ó ti wà nínú kọ́jọ́dá àwọn Yorùbá, èyí tí ó sáábà máa ń bọ́ sí ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù òkudù (June). Wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí ní: Grays Ferry Avenue àti South Street ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní ìlú Philadelphia àti Pennsylvania.
Ruth Arthur àti Lois Fernandez ni wọ́n jẹ́ olùfilélẹ̀ ayẹyẹ ọdún Odunde. Ruth dágbére fún ayé ní ẹni ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64) ní ọdún 1997. Nígbà tí Lois dágbére fún ayé ní ẹni ọmọ ọdún ọ́kànlélọ́gọ́rin (81) ní ọdún 2017.
Ìtàn nípa ọdún yìí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ayẹyẹ ọdún Odunde bẹ̀rẹ̀ ní Philadelphia ní ọdún 1975. Lois Fernandez àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ruth Arthur ni wọ́n ṣe ètò ayẹyẹ ọdún Ọdunde àkọ́kọ́. Ó wáyé nínú oṣù kẹrin, ọdún 1975,[1][2] gẹ́gẹ́ bí ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun. [1] Àfojúsùn wọ́n ni láti mú kí ìṣọ̀kan ó wà nínú ìlú, àti láti polongo fún aráyé rí nípa àṣà àti ìṣe àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfíríkà. [3] The festival began with $100 from neighborhood donations.[4]
Ọdún yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ayẹyẹ tí ó tóbi jù tí àwọn ẹ̀yà Áfíríkà tí wọ́n ń bẹ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà máa ń ṣe. Wọ́n máa ń ṣe é nínú oṣù kẹfà. Ọdún yìí máa ń kó gbogbo àwọn ẹ̀yà Áfíríkà papọ̀ káàkiri gbogbo àgbáyé, pẹ̀lú àwọn ti Áfíríkà, Brazil, àti àwọn ìletò tí wọ́n sún mọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. [5] Ní ìbámu pẹ̀lú bí WXPN ti sọ, "... bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ètùtù tí ó kó gbogbo àwọn ènìyàn sínú lọ sí odò Schuylkill, wọ́n yóò ṣe ayẹyẹ ọdún yìí láti agogo mẹ́wàá òwúrọ̀ (10 a.m.) títí di agogo mẹ́jọ àṣálẹ́ (8 p.m.), gbígbé ọjọ́ náà ga pẹ̀lú onírúurú aṣọ, oúnjẹ àwọn Áfíríkà, àti ètò ìpàtẹ iṣẹ́ ọnà tí wọ́n gbé wa káàkiri gbogbo àgbáyé."[6]
Wọn kò ṣe ayẹyẹ ọdún yìí ní ọdún 2020.
-
Odunde Festival 2013 on Grays Ferry Avenue
See also
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Harris, Christina Afia. "ODUNDE Festival". The Encyclopedia of Greater Philadelphia. Retrieved 15 March 2018.
- ↑ Mazenko, Elizabeth (June 7, 2013). "Odunde Festival closes the streets for its 38th anniversary". WXPN. http://thekey.xpn.org/2013/06/07/odunde-festival-closes-the-streets-for-its-38th-anniversary/. Retrieved 14 March 2018.
- ↑ Hunter, Marcus Anthony (2013). Black citymakers: how the Philadelphia negro changed urban America. Oxford: Oxford University Press. pp. 170, 196–202. ISBN 9780199948130. https://books.google.com/books?id=TMHcDciM3kMC&pg=PA196. Retrieved 14 March 2018.
- ↑ Gregg, Cherri (May 13, 2013). "Oshunbumi Fernandez, Caring Through Culture and Odunde 365". CBS Philly. http://philadelphia.cbslocal.com/2013/05/13/oshunbumi-fernandez-caring-through-culture-and-odunde-365/.
- ↑ Jenkins, Kristina (June 6, 2013). "Our Guide To The Odunde Festival, Set To Bring A Celebration Of African-American Culture To South Street West This Sunday, June 9". UWISHUNU Philadelphia. http://www.uwishunu.com/2013/06/our-guide-to-the-odunde-festival-set-to-bring-a-celebration-of-african-american-culture-to-south-street-west-this-sunday-june-9/.
- ↑ Mazenko, Elizabeth (June 7, 2013). "Odunde Festival closes the streets for its 38th anniversary". WXPN. http://thekey.xpn.org/2013/06/07/odunde-festival-closes-the-streets-for-its-38th-anniversary/.
External links
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ODUNDE365 Official festival website