Jump to content

Bí Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ń dojú ìjà kọ COVID-19

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2020 ni àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 fìdí sọlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Èyí wáyé látipasẹ̀ arákùnrin Italy kan tí ó padà sí Nàìjíríà pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú ní ọjọ́ kẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2020.

Bí Àrùn náà ṣe tànkálẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta, Ìpínlẹ̀ Èkó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ kejì múlẹ̀ látara ọdọ́mọbìnrin kan tí ń ṣe ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ padà dé láti ilẹ̀ aláwọ̀funfun ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta.[1]

Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta, ìpínlè Èkó tún ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun mẹ́rin. [2]

Ní́ ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹta, a tún rí ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun mẹ́rin lórí àrùn COVID-19 ní Ìpínlẹ̀ Èkó. [3] [4] Lọ́jọ́ kan náà ni a gbọ́ pé arákùnrin tó mú àjàkálẹ̀ àrùn náà wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gba òmìnira lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn náà. Èyí sì já sí àṣeyọrí àkọ́kọ́ tí ìpínlẹ̀ Èkó ní lórí àrùn náà.[5][6]

Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó tún ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ méje mìíràn.[7]

Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta, ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́fà mìíràn ni ìpínlẹ̀ Èkó tún ṣàwárí.[8][9]

Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó tún ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́fà.[10] wọ́n sì tún fìdí ẹni àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ aláìsí látipasẹ̀ àrùn COVID-19 múlẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ àgbàlagbà ọmọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Suleiman Achimugu, onímọ̀ ẹ̀rọ àti ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ fún ilé iṣẹ́ Pipeline and Product Marketing, ẹnití ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìlú aláwọ̀funfun pẹ̀lú àìlera ara.[11]

Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ kan.[12]

Ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹta mìíràn.[13]

Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ méjìlá tuntun. [14].

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́jọ mìíràn.[15] Lọ́jọ́ kan náà ni gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu ṣe ìkéde lórí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Èkó tí ó ní iye ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó pọ̀ jù lọ. Àwọn ìbílẹ̀ náà ni: Etí Ọ̀sà àti Ikeja.[16]

Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ méje mìíràn.[17]

Ńi ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́sàn-án tuntun.[18]

Ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣú kẹta, ìpínlẹ̀ Èkó tún rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàlá mìíràn.[19]

Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́sàn-án mìíràn.[20][21]

Ní ọjọ́ kejì oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ méje mìíràn.[22] Lọ́jọ́ kan náà ni wọ́n ṣe ìkéde pé èèyàn mọ́kànlá lára àwọn tí ó kó àrùn náà ní ó ti bọ́ tí ó sì ti ní ìwòsàn pípé.[23]

Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kànlá mìíràn.[24]

Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kànlá mìíràn.[25][26]

Ní ọjọ́ keje oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́wàá mìíràn.[27]

Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mìíràn.[28]

Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàlá mìíràn.[29]

Ní ọjọ́ kẹwa oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́jọ mìíràn.

Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kànlá mìíràn.[30]

Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ méjì mìíràn.[31]

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kerin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàlá mìíràn.[32]

Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n mìíràn.[33] [34]Ìpínlẹ̀ Èkó kéde pé àwọn òṣìṣẹ́ wọn ti ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ojúlé tí ó tó 118,000 láàrin ọj́ọ́ méjì tí wọ́n sì rí iye àwọn ènìyàn tí ó tó 119 tí wọ́n ní àmì tí ó máa ń yọ lára àwọn tí ó ní àjàkálẹ̀ àrùn náà lára.[35]

Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kerin, ìpínlẹ̀ Èkó rí ìṣẹ̀lẹ̀ méjìdínlógún mìíràn. [36]

Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹrin, ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kàndínlógún ní a rí ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[37]

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin, ìṣẹ̀lẹ̀ méjìlélọ́gbọ̀n mìíràn ni a rí ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[38]

Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin, ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàlélógún mìíràn ni a rí ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[39]

Ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kẹrin, àádọ́rin ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun lórí àrùn Covid-19 ni a rí ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[40]

Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́kàndínlógójì mìíràn.[41]

Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹrin, ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́rìnléláàádọ́rin ni a rí ní ìpínlẹ̀ Èkó.[42]

Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣú kẹrin, ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí ìṣẹ̀lẹ̀ méjìdínlọ́gọ́rin mìíràn.[43]

Ni ojo kerinlelogun osu kerin, ọgọ́rin ìṣẹ̀lẹ̀ ni a rí ní Ipinle Èkó.[44]


Ní ọjọ́ kẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin, èjìdínlọ́tà-léní-ẹgbẹ̀fà èèyàn ni ó ní àrùn covid-19 ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Ìhà tí Ìpínlẹ̀ Èkó kọ sí Àrùn náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2020, ìpínlẹ̀ Èkó bẹ̀rẹ̀ ìsémọ́lé ní pẹrẹu.[45] Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó rọ àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ náà láti dúró sílé, ó sì rọ àwọn ilé-iṣẹ́ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan láti dáwọ́ iṣẹ́ dúró àmọ́ tí àwọn òṣìṣẹ́ bá le ṣiṣẹ́ láti ilé, wọ́n le tẹ̀ síwájú.[46] Ó tún rọ àwọn ilé-ìwé aládàáni àti ìjọba kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Kódà gbogbo ènìyàn ní gómìnà ìpínlẹ̀ náà rọ̀ láti dúró sílé. Èyí ò sì yọ ilé-ìjọsìn ti Mùsùlùmí àti Kìtẹ́ẹ́nì sẹ́yìn. Àṣẹ sì wà pé kò gbọdọ̀ sí ìpéjọ pò tó ju ogún èèyàn lọ. Yálà ní ilé-ìjọsìn, ayẹyẹ, ilé-iṣẹ́ àdáni tàbí ìpéjọ pò mìíràn lóríṣiríṣi. Àṣẹ sì wà pé ẹnikẹ́ni tí owó bá tẹ̀, á fojú ba ìjìyà tó tọ́. Ìjọba náà fi lélẹ̀ pé kò gbọdọ̀ sí ìjáde tàbí ìwọlé pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú ní ìpínlẹ̀ náà. Àwọn ọjà káàkiri ìpínlẹ̀ náà ni ó sì ní ọjọ́ tí wọ́n ń ṣí fún títa àti rírà. Àmọ́ àwọn ọlọ́jà tó ń ta nǹkan jíjẹ ni ààyè wà fún láti ṣí ṣọ́ọ̀bù wọn.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Third coronavirus case confirmed in Nigeria". TheCable. 2020-03-17. Retrieved 2020-04-06. 
  2. Toromade, Samson (2020-03-18). "Nigeria confirms 5 new cases of coronavirus". Pulse Nigeria. Retrieved 2020-04-06. 
  3. Obinna, Chioma (2020-03-19). "LASG Confirms 4 more new cases of COVID-19". Vanguard News. Retrieved 2020-04-06. 
  4. "Nigeria's coronavirus cases rises to 12 with four new confirmations". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2020-03-19. Archived from the original on 2020-06-22. Retrieved 2020-04-06. 
  5. Published (2015-12-15). "Italian who brought coronavirus to Nigeria now negative – Lagos". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-06. 
  6. "UPDATED: Lagos discharges Italian who brought coronavirus to Nigeria". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-04-06. 
  7. "Nigeria records 10 new positive cases of COVID-19". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2020-03-21. Retrieved 2020-04-06. 
  8. "Coronavirus: Nigeria now has 26 Confirmed cases - NCDC". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2020-03-22. Retrieved 2020-04-06. 
  9. "BREAKING: COVID-19: NCDC confirms one new case in FCT". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2020-03-22. Retrieved 2020-04-06. 
  10. "Nigeria's coronavirus cases now 40 on Monday night". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2020-03-23. Archived from the original on 2020-03-24. Retrieved 2020-04-07. 
  11. "Achimugu, ex-PPMC boss identified as Nigeria's first coronavirus death". P.M. News. 2020-03-23. Retrieved 2020-04-07. 
  12. "Nigeria coronavirus cases rise to 44". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-04-07. 
  13. Published (2015-12-15). "Coronavirus cases hit 51 in Nigeria". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  14. "14 New Cases Of COVID-19 Confirmed In Nigeria". Channels Television. 2020-03-26. Retrieved 2020-04-07. 
  15. Published (2015-12-15). "Nigeria’s coronavirus cases hit 81 as NCDC announces 11 new cases". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  16. Published (2015-12-15). "Ikeja, Eti-Osa top coronavirus cases in Lagos". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  17. "COVID-19: Nigeria’s cases hit 97  – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2020-04-07. 
  18. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria reports 14 new coronavirus cases, total now 111". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  19. Published (2015-12-15). "COVID-19 cases rise to 131 in Nigeria". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  20. Published (2015-12-15). "Nigeria records 12 new COVID-19 cases, total now 151". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  21. Published (2015-12-15). "Nigeria records 23 new cases of COVID-19, total now 174". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  22. Published (2015-12-15). "Nigeria records 10 new coronavirus cases in Lagos, Abuja". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  23. Published (2015-12-15). "Coronavirus: 11 patients recover, discharged in Lagos". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  24. "BREAKING: Nigeria records six new cases of COVID-19". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2020-04-03. Retrieved 2020-04-07. 
  25. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria records 10 new cases of coronavirus, total now 224". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  26. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria records eight new COVID-19 cases, total now 232". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-07. 
  27. "Nigeria records 16 new COVID-19 cases, total now 254". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-04-09. 
  28. Royal, David (2020-04-08). "Nigeria records 22 new cases of COVID-19, as total rises to 276". Vanguard News. Retrieved 2020-04-09. 
  29. Published (2015-12-15). "Nigeria records 14 new COVID-19 cases, total now 288". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-10. 
  30. Published (2015-12-15). "UPDATED: 10 dead as Nigeria’s coronavirus cases rise to 318". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-14. 
  31. Published (2015-12-15). "Nigeria records five new coronavirus cases, total now 323". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-14. 
  32. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria records 20 new COVID-19 cases, total now 343". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-14. 
  33. "UPDATED: Nigeria’s coronavirus cases now 362 after 19 test positive – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2020-04-17. 
  34. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria records 11 new coronavirus cases in Lagos, total now 373". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-17. 
  35. "After Visiting 118,000 Households, We Identified 119 Persons With COVID-19 Symptoms –Lagos Government". Sahara Reporters. 2020-04-14. Retrieved 2020-04-17. 
  36. Published (2015-12-15). "UPDATED: 12 dead as Nigeria’s coronavirus cases rise to 407". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-17. 
  37. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria records 35 new coronavirus cases, total now 442". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-17. 
  38. Published (2015-12-15). "UPDATED: 17 dead as Nigeria’s coronavirus cases jump to 493". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-17. 
  39. Published (2015-12-15). "Nigeria records 19 deaths as coronavirus cases hit 542". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-20. 
  40. Published (2015-12-15). "21 dead as coronavirus spreads to 21 states, Abuja". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-20. 
  41. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria records 117 new coronavirus cases, total now 782". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-22. 
  42. Published (2015-12-15). "UPDATED: 28 dead as Nigeria’s coronavirus cases rise to 873". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-23. 
  43. "Nigeria records 108 new COVID-19 cases, total now 981". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-04-24. 
  44. Published (2015-12-15). "UPDATED: Nigeria’s coronavirus cases pass 1000, death toll now 32". Punch Newspapers. Retrieved 2020-04-25. 
  45. "Nigeria imposes lockdown in cities of Lagos and Abuja to curb coronavirus". France 24. 2020-03-29. Retrieved 2020-04-25. 
  46. "How Nigeria is faring nearly two weeks into COVID-19 lockdown". The Africa Report.com. 2020-04-10. Retrieved 2020-04-25.