Bọ́sẹ̀ Ogulu
Bọ́sẹ̀ Ogulu Jẹ́ onímò, olùṣòwò ati alámòójútó ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó bójú tó iṣẹ́ orin fún gbajú-gbajà olórin takadúfé Burna Boy tí ó tún jẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni gbogbo ènìyàn mò sí Mama Burna.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ogulu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ lámèyítọ́ olórin ilẹ̀ [[Nàìjírí] tẹ́lẹ̀, ìyẹn Benson Idonije, tí òun náà tún jẹ́ alámòójútó iṣẹ́ orin fún ìlú-mòọ́ká olórín ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Fẹlá Kútì. Ogulu kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.a nínú ìmọ̀ èdè àgbáyé (foreign languages) àti ìwé ẹ̀rí kejì (Masters of Arts) nínú ìmọ̀ ìṣògbufọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì Port Harcourt. O ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ògbufọ̀ fún ilé-iṣẹ́ okòwò ti apá ìwọ̀ Oòrun ilẹ̀ Afíríkà. Ó gbọ́nèdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Jamaní Italy ati èdè Yorùbá dúnjú-dunjú. [1][2] Ó dá ilé-ẹ́kọ́ kan tí ó pè ní She then ran a language school called Language Bridges, where she organized cultural immersion trips for over 1,800 young people. [3] Ó jẹ́ olùkọ́ ède Faransé fún ọdún díẹ̀ ní Yunifásitì Port Harcourt, tí ó sì fẹ̀yìn tì ní ọdún 2018. [4]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ogulu ni ó ń ṣàmójútó iṣẹ́ oein ọmọ rẹ̀ Damini tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ Burna Boy ati ọmọ rẹ̀ obìnrin tí ó ń lo orúkọ rẹ̀ Nissi. Ó ṣe amójútó iṣẹ́ Burna Boy títí di ọdún 2017, èyí tí ó mu gba ìnagijẹ Mama[5][6]
Àwọn amì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó ti gba amì-ẹ̀yẹ fún ọmọ rẹ̀ Burna Boy ní ibi orísirísi ayẹyẹ bíi: All Africa Music Awards, The Headies àti MTV Europe Music Award.[7] Nígbà tí ó gbọ́ wípé ọmọ rẹ̀ Búrna Boy ti gba amì-ẹ̀yẹ ti MTV fún ọ̀kọrin tó peregedé jùlọ ní ọdún 2019, inú rẹ̀ dùn, ó sì fi tayọ̀ tayọ̀ dá ayẹyẹ náà dúró láti sọ̀rọ̀ .[8] Nígba tí Burna Boy gba amì-ẹ̀yẹ mẹ́rin ní ibi ayẹyẹ Soundcity MVP Awards Festival ní ọdún 2018, Ogulu ló lọ gba àmì-ẹ̀yẹ náà lórúkọ ọmọ rẹ̀, èyí sì fa òpọ̀lọpọ̀ awuye-wuye ní orí awọn ìkanì ìbánidọ́rẹ́ gbogbo pàá pàá jùlọ àkòrí "Expect more madness" tí wọ́n fi sí orí Ìtàkùn ayélujára lórí ọ̀rọ̀ náà. [6] Níbi ayẹyẹ amì-ẹ̀yẹ BET Awards ti ọdún 2019 ní ìlú California, Ogulu náà ló tún gba amì-ẹ̀yẹ ní orúkọ ọmọ rẹ̀, tí ó sì bá awọn èn pàá pàá jùlọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Afíríkà tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà wípé: "you were Africans before you became anything else" tí awọn ènìyan sì gbóríyìn fun fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ yí. [9][10] Bósẹ̀ Ogulu ni aláṣe àti olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Spaceship Collective [1], tí ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìgbórinjáde. Àti ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wé ti Spaceship Publishing. [11]
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọ̀gbẹ́ni Samuel Ogulu fún ọgbọ̀n ọdún, Ọlọ́run sì fi awọn ọmọ mẹ́ta Damini, Ronami, àti Nissi Ogulu jínkí wọn. [12]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Ogunnaike, Lola (4 March 2020). "Burna Boy Is Trying to Wake Up Africa" (in en). GQ. https://www.gq.com/story/burna-boy-african-king-profile. Retrieved 2 May 2020.
- ↑ Kotto, Rolyvan (31 March 2020). "Burna Boy révèle pourquoi il préfère que sa mère soit son manager" (in fr-FR). Life. Archived from the original on 10 November 2020. https://web.archive.org/web/20201110130559/https://lifemag-ci.com/burna-boy-revele-pourquoi-il-prefere-que-sa-mere-soit-son-manager/. Retrieved 2 May 2020.
- ↑ "Bose Ogulu (Mama Burna)". 100women.okayafrica.com. Archived from the original on 2020-09-30. Retrieved 2020-11-10.
- ↑ Okoruwa, Samuel. "Facts About Burna Boy’s Mom: Bose Ogulu". Reterdeen. Retrieved 2 August 2019.
- ↑ "Title of new album and other Burna Boy's revelations in Twitter Q&A". Pulse Nigeria. 31 March 2020. Archived from the original on 4 April 2020. Retrieved 2 May 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 6.0 6.1 Durosomo, Damola (29 March 2019). "The Internet Doesn't Know Mama Burna At All". OkayAfrica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 May 2020. Retrieved 2 May 2020. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Burna Boy absent at coronation as Africa's artiste of the year - P.M. News". PM News Nigeria. 24 November 2019. https://www.pmnewsnigeria.com/2019/11/24/burna-boy-absent-at-coronation-as-africas-artiste-of-the-year/. Retrieved 2 May 2020.
- ↑ Ekechukwu, Ferdinand (9 November 2019). "Burna Boy Relishes MTV EMA Trophy". THISDAYLIVE. https://www.thisdaylive.com/index.php/2019/11/09/burna-boy-relishes-mtv-ema-trophy/. Retrieved 2 May 2020.
- ↑ "Remember you were Africans before you became anything else, Burna Boy’s mum gives epic speech at BET Awards". Punch Nigeria. 24 June 2019. https://punchng.com/remember-you-were-africans-before-you-became-anything-else-burna-boys-mum-gives-epic-speech-at-bet-awards/. Retrieved 2 May 2020.
- ↑ Duerden, Nick (19 July 2019). "How Burna Boy Became Nigeria's Surprise Success Story". Billboard. https://www.billboard.com/articles/columns/hip-hop/8520544/burna-boy-african-giant-interview. Retrieved 2 May 2020.
- ↑ Obinna, Emelike. "A look at Spaceship Collective; a rising indegenous record label". Business Day. Retrieved 4 September 2020.
- ↑ Ikeji, Linda. "Burna Boy's parents, Samuel and Bose Ogulu celebrate 30th wedding anniversary". Lindaikejisblog.com. Retrieved 2 September 2020.