Fẹlá Kútì
Fẹlá Kútì | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Olúfẹlá Olúṣẹ́gun Olúdọ̀tun Ransome-Kútì |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | Fela Anikulapo Kuti Fela Ransome-Kuti |
Ọjọ́ìbí | Ábẹ́òkúta Nigeria | 15 Oṣù Kẹ̀wá 1938
Aláìsí | 2 August 1997 | (ọmọ ọdún 58)
Irú orin | Afrobeat, Highlife |
Occupation(s) | Singer-songwriter, instrumentalist, activist |
Instruments | Saxophone, vocals, keyboards, trumpet, guitar, drums |
Years active | 1958–1997 |
Labels | Barclay/PolyGram, MCA/Universal, Celluloid, EMI Nigeria, JVC, Wrasse, Shanachie, Knitting Factory |
Associated acts | Africa '70, Egypt '80, Koola Lobitos, Nigeria '70, Hugh Masekela, Ginger Baker, Tony Allen, Fẹ́mi Kútì, Ṣeun Kútì, Roy Ayers, Lester Bowie |
Website | felaproject.net |
Fẹlá Aníkúlápó Kútì (orúkọ ìbí Olúfẹlá Olúṣégun Olúdọ̀tun Ransome-Kútì, October 15, 1938 - August 2, 1997) tàbí Fẹlá jẹ́ olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó tún jẹ́ adìjà-gbara fún àwọn ọmọ orílè- èdè Nàìjíríà; ó sì tún ma ń kọ orin. Wón mọ̀ó ṣí ẹni tí ó ò síwájú orin àwọn aláwọ̀ dúdú. Orúkọ mìíràn tí won a máa pe Felá ni "Abàmì Èdá."
Fẹlá Kútì jẹ́ ọmọ adìjà-gbara fún ètó àwọn obìnrin, Ìyá ààfin Fúnmiláyò Ransome Kútì. Ní ìgbà tí ó dé láti ìlú òyìnbó, orin rè kan tí ó ń jẹ́ "Africa '70" jáde ní ọdún 1970. Ní ọdún yì í ni ó fi orin rè bá àwọn ìjọba alágbádá tó wà ní'pò wì i.[3] Ní ọdún yìí náà ni ó dá "Kàlàkútà Republic Commune" sí'lè, tí ó sì yo ara álà rè kúrò láàrín ín àwon tó ní'fèé sí ìjọba alágbádá. Ìjọ "Commune" yìí padà dárú ní ọdún un 1977 ní'gbà tí wón dá'ná sun-ún. Láti ìgbà tí Felá Kútì ti di olóògbé ni omo rè, Fémi Kútì, ti kó gbogbo orin rè jo s'ójú kan.
Ìbèrè ayé e rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Olúfelá Olúségun Olúdòtun Ransome-Kútì ni wón bí ní ọdún un 1938, ní ojó karùndínlógún Oşù Òwàrà (October 15) sí ìlú u Abẹ́òkúta, ní ìpínlè Ògùn, ní orílè-èdè Nàìjíríà. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé adìjà-gbara fún ètọ̀ àwọn obìnrin ni ìyá a rè, Olóyè Fúnmiláyò Ransome-Kútì, tí bàbá rè ṣì jẹ́ Olùşó Àgùntàn ti ìjọ Ańglícàń, olùkó-àgbà àti ààrẹ fún gbogbo Olùkó. Àwọn ọmọ ìyá rè ni Béèkó Ransome-Kùi àti Olíkóyè Ransome-Kútì, Dókítà ìlúmòóká Dókítà. Fẹlá tún tan mó Ọ̀jọ̀gbón Wolé Sóyínká, ẹni tí ó jẹ́ eni àkókó ní ilè aláwọ̀ dúdú tí ó gba Èbùn Iyì Lítírésò (Nobel Prize in Literature).
Kútì lọ sí ilé ìwé girama ti ìlú u Abẹ́òkúta. Ní ọdún 1958, ó lọ sí òkè òkun lọ ka èkó ìmò ìşègùn. Şùgbón, ó padà lọ sí ilé ìwé èkó orin kan tí wón ń pè ní Trinity College of Music. Kàkàkí ni ó fẹ́ràn láti máa fi kọ orin. Ní'gbà tí ó wà l'óhùn ún, ó dá egbé orin ti tirè sí'lè, tí ó ń jé "Koola Lobitos", tí wón ń ko "jazz" àti "highlife". Ní ọdún 1960, Felá fẹ́ ìyàwó o rè tí orúko rè ń jé Rèmílékún Kútì, eni tí ó sì bí ọmọ méta fun; orúko won a sì má a jé Fémi, Yemí àti Solá. Ní odún 1963, Kútì padà sí Nàìjíríà l'ẹ́yìn ìgbà tí ó ti gba òmìnira; ó sì ń kó egbé orin rè káàkiri.
Ní ọdún 1967, Kútì lọ sí Orílè Èdè Ghánà láti lọ wá ònà mìíràn bí yó ò ti mà a pe orin re. Ònà ìpè orin mììràn ti è yì í wá ni "Afrobeat", ìyẹn tí ń ṣe àpapọ̀ "highlife", "fun", "jazz", "salsa", "calypso" àti orin ìjìnlè ilẹ̀ Yorùbá.
Bí Fẹlá ṣe jà fún ètó ará ìlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bí Felá ti ṣe ń ṣe ìjà-n-gbara, bẹ́èni wón ń fì pamó sí àgó ọlópàá. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá fi èhónú hàn ni wón maá mu lọ sí àtìmólé, béè náa ni wón a má a fi ìyà je àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ rè. Felá Kútì jé adìjà-gbara fún ètó ọ ará ìlú tí tí ó fi di olóògbé. Kútì a máa dojú kọ ìjọba Nàìjíríà fún gbogbo ìwà ìbàjé tí wọn wù sí àwọn ará ìlú tí wón fi wón sí ipò. Felá jé kí wón mọ̀ pé àwọn òyìnbó ni wón dá rògbòdìyàn sí ìlú Nàìjíríà. Felá tún jé kí wón mọ àwọn ìwà ìbàjé kan tí ó wà láàárín in àwọn aláwọ̀ dúdú: bí i kí a máa gba àbètẹ́lẹ̀, kí a má ṣe òótó, kí a máa se ojúkòkòrò , kí a máa da ìbò rú, kí a máa gbé'ni pa, kí a máa se jàgídí-jàgan àti bẹ́èbéẹ̀ lọ.
Ipa tí o fi í lè
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé Felá Kútì jẹ́ akínkanjú, tí o fi orin rè tún ìlú ṣe. Ayẹyẹ ọdọọdún kan sì wà, tí wón ń pè ní "Felabration" láti fi máa ṣe ìrántí olóògbé Felá Kútì gégé bí i eni orin rè wuyì l'áwùjọ.
Ní ọdún 1999, Universal Music France, ní abé e ìdarí i Francis Kertekian, gbé áábóòmù ọgóójì ó lé márùn ún (àrùn-dín-láàdóta) ti Felá jáde. Bẹ́è sì tún ni Felá tún gba oríyìn àti àmì ìpegedé l'ókè òkun.
Olórin kan tí wón ń pè ní Bìlál láti orílè-èdè Amẹ́ríká tún orin Felá ṣe ní Ọdún 1997 tí ó sì pe àkólé e rè ní "Sorrow, Tears and Blood".
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2007 ni eré orí ìtàgé kan tí àkọólé rè ń jé "The Visitor" (Àlejò) tí arákùnrin kan tó ń jé Thomas McCarthy darí jáde. Eré yì í ṣe àfihan an òjògbón kan tí orúko rè ń jé Richard Jekins, eni tí ó fé gbó orin kan tí àkólé rè ń jẹ́ "djembe" tí ó kó láti ọ̀dọ̀ arákùnrin kan tí a ń pè ní Haaz Sleiman eni tí ó wá láti orílè-èdè Syria. Haaz Sleiman sì sọ fún ọ̀jọ̀gbón yìí pe kò sí bí òun şe lè gbó àgbóyé orin àwon aláwò dúdú àyàfi tí òun bá kókó gbó orin Fẹlá. Nínú eré yìí náà ni wón ti ṣe àfihàn orin Felá méjì kan tí àkólé e won ń jẹ́ "Open and Close" àti "Jẹ́ n wí tèmi".
Nígbà ayé e rẹ̀, oríşiríşi nnkan ló fi lé'lẹ̀. Bẹ́è náà ni wón fun ní oríṣiríṣi èbùn tó pọ̀ já-n-ti-rẹrẹ. Wón sì tún fà á ka'lè ni èèmọkànlá gégé bí i ẹni tó yẹ látì gba èbùn ìpegede títayọ nínú işé orin kíkọ.
Àwọn àṣàyàn orin tí ó kọ sílẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]"Felá Felá Felá" jáde ní ọ̀dún 1969, Live! (1971)
"Rọ̀fọ̀rọ̀fọ̀" jadé ńì ọ̀dún 1972
"Shakará" ní ọ̀dún 1973
"Open & Close" ní odún 1971
"Afrodisiac" jáde ní odún 1973
"Gentleman" jáde ní odún 1973
"Confusion" jáde ní odún 1975
"Expensive Shit" jáde ní odún 1975
"He Miss Road" jáde ní odún 1975
"Water No Get Enemy" jáde ní odún 1975
J.J.D. (Johnny Just Drop!!) (1977)
"Zombie" jáde ní odún 1977
"Stalemate" náà jáde ní odún 1977
"No Agreement" jáde ní odún 1977
"Sorrow, Tears and Blood" jáde ní odún 1977
"Shuffering and Shmiling" jáde ní odún 1978
"Black President" jáde ní odún 1981
"Original Sufferhead" jáde ní odún 1981
"Unknown Soldier" jáde ní odún 1981
"Army Arrangement" jáde ní odún 1985
"Beasts of No Nation" jáde ní odún 1989
"Confusion Break Bones" jáde ní odún 1990; àti béèbéè lọ.
Ere Orinkipo nipa Fela:Atilẹjade iṣelọpọ Broadway ti Fela!
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Felá jé olórin tó dá-ń-gá-jí-á, nítorí náà àwon olórin jà-n-kàn-jà-n-kàn bí i Shawn “Jay-Z” Carter dara pò pèlú u Will Smith àti ìyàwó o rè, Jada Pinkett Smith láti şe işé àkànşe orin àti eré orí ìtàgé láti owó Eugene O'Neill tí wón pe àkólé e rè ní Felá, láti bu olá fún un.