Jump to content

Babatunde Hunpe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Babátúndé Húnpẹ)
Babátúndé Húnpẹ

Babátúndé Húnpẹ (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejì oṣù kẹjọ ọdún 1963) jẹ́ Olóṣèlú ọmọ bíbí ìlú Àgbádárìgì (Badagry) ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-aṣòfin Nàìjíríà tí ó ń ṣojú ìjọba ìbílẹ̀ Àgbádárìgì (Badagry Federal Constituency) lọ́wọ́́lọ́wọ́. [1][2]

Ìgbé-ayé rẹ̀ lágbo òṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí ó tó di ọmọ ẹgbẹ́ ilé aṣojú-ṣòfin, tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Àgbádárìgì (Badagry Federal Constituency) ó ti fìgbà kan ṣiṣẹ́ ní Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State University), ó jẹ́ Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Gómìnà-àná fún ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Aḿbọ̀dé lórí ètò àyíká lọ́dún 2015 sí 2019. Bẹ́ẹ̀ náà ó bá Babátúndé Rájí Fáṣọlá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òlùràlọ́wọ́ pàtàkì lórí àyíká nígbà ìṣèjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lọ́dún 2011 sí 2015.[3] Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ni. [4][5]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Assembly, Nigerian National (1963-08-02). "Federal Republic of Nigeria". National Assembly. Archived from the original on 2020-12-01. Retrieved 2019-11-23. 
  2. http://badagryprime.com/nigeria-at-61-hunpe-berates-insecurity-gives-nigerians-hope/[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "Contacts of Key Officers of the Ministry". Lagos State Ministry of the Environment and Water Resources - committed to sustainable environment. Archived from the original on 2019-10-24. Retrieved 2019-11-23. 
  4. "Home". Babatunde Hunpe. 2019-10-28. Archived from the original on 2020-10-22. Retrieved 2019-11-23. 
  5. "Why aspirants are many in Badagry - Hunpe". The Sun Nigeria. 2018-08-27. Retrieved 2019-11-23.