Babatunde Hunpe
Babátúndé Húnpẹ (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejì oṣù kẹjọ ọdún 1963) jẹ́ Olóṣèlú ọmọ bíbí ìlú Àgbádárìgì (Badagry) ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-aṣòfin Nàìjíríà tí ó ń ṣojú ìjọba ìbílẹ̀ Àgbádárìgì (Badagry Federal Constituency) lọ́wọ́́lọ́wọ́. [1][2]
Ìgbé-ayé rẹ̀ lágbo òṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kí ó tó di ọmọ ẹgbẹ́ ilé aṣojú-ṣòfin, tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Àgbádárìgì (Badagry Federal Constituency) ó ti fìgbà kan ṣiṣẹ́ ní Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State University), ó jẹ́ Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Gómìnà-àná fún ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Aḿbọ̀dé lórí ètò àyíká lọ́dún 2015 sí 2019. Bẹ́ẹ̀ náà ó bá Babátúndé Rájí Fáṣọlá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òlùràlọ́wọ́ pàtàkì lórí àyíká nígbà ìṣèjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lọ́dún 2011 sí 2015.[3] Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ni. [4][5]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Assembly, Nigerian National (1963-08-02). "Federal Republic of Nigeria". National Assembly. Archived from the original on 2020-12-01. Retrieved 2019-11-23.
- ↑ http://badagryprime.com/nigeria-at-61-hunpe-berates-insecurity-gives-nigerians-hope/[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Contacts of Key Officers of the Ministry". Lagos State Ministry of the Environment and Water Resources - committed to sustainable environment. Archived from the original on 2019-10-24. Retrieved 2019-11-23.
- ↑ "Home". Babatunde Hunpe. 2019-10-28. Archived from the original on 2020-10-22. Retrieved 2019-11-23.
- ↑ "Why aspirants are many in Badagry - Hunpe". The Sun Nigeria. 2018-08-27. Retrieved 2019-11-23.