Bar Beach, Lagos

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kẹtẹkẹtẹ ní ori Bar Beach, 2019

Bar Beach jẹ eti Okun Atlantiki lẹba okun ti Eko, ti o wa ni Victoria Island . Fun akoko kan, o jẹ eti okun tí o lokiki julọ ni Naijiria paapaa nigbati ipinle Eko jẹ olu-ilu orilẹ-ede naa.

Laarin ọdun 1970 si awọn ọdun 1990: ibi ipa àwon odaran[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lati ibẹrẹ awọn ọdun 1970s si odun 1980s lakoko ijọba ologun, Bar Beach jẹ ibi tí àwon ologun ti ún pa awon odaran ti won ti dajó fun . [1] O jẹ ibi ti àwon ènìyàn ti le wo awon isele yìí ni gba un gba . [2] [3]

Ipaniyan ni gba un gba àkókó tí o selè ni Nàìjíríà waye ni Bar Beach ni ọdun 1971. Àwon ologun pa Babatunde Folorunsho, fun ole jija. [4] Awọn tókù ti won pa ni Joseph Ilobo, Williams Alders Oyazimo, ati Lawrence Anini ati Dokita Oyenusi ni awọn 90s. [5]

Bar Beach, Lagos, 2013

Awọn ọdun 1980 si 2000: Ikun omi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fun ọpọlọpọ ọdun, Bar Beach n kún kojá etí rè tí o si un yabo àwon ayika, èyi mú adanu opolopo èmi àti dúkìá wá [6] [7] Ni ọpọlọpọ igba, wón ma ún ti ọna Ahmadu Bello, opopona ti o sunmọ awọn okun náà pa. [8]

2000-orundun lati mu: Eko Atlantic[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni ọdun 2003, won mú àbá wá láti kó ìlú si eti okun Atlantic. Yoo wa lori ìbi ti àún pè niBar Beach tẹlẹ. A o si si nii Eko Atlantic City, ibè ma wa fun igbé àti fun ojà tita, yo si ma je square meter tó tó milionu mewa

Ni 2008, won bèrè si un ko ìlú náà. [9]

Ótún le ka eyi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ibeno Beach

Awọn itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]