Bayo Onanuga
Bayo Onanuga (ọjọ́ ìbí ogún Oṣù Kẹfà ọdún 1957) jẹ́ oníròyìn ọmọ Nàìjíríà. Ó dá ìwé ìròyìn TheNews sílẹ̀ àti pé ó jẹ́ olùdarí ti News Agency of Nigeria nípasẹ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari ní May 2016. Ṣáájú èyí, ó jẹ́ Alákòóso àti olóòtú àgbà tí PM News àti TheNEWS ìròyìn.
Ìpìlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Onanuga sí inú ìdílé apàṣẹ Anikilaya ní Ijebu Ode ní ìpínlè Ògùn. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀óbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ilé-ìwé Moslem Primary School ni Ijebu-Ode láti 1962 sí 1969. Ó sì lọ sí ilé-ìwé Muslim College Ijebu Ode, ó parí ní ọdún 1974 pẹ̀lú ipò kìní.
Lẹ́yìn ṣíṣe iṣẹ́ diẹ̀ fún ọdún kan, ó lọ sí ilé-ìwé Federal Government College ní Odogbolu fún A-Level rẹ̀ láàárín ọdún 1975 àti 1977.
Wọ́n gbà á sí ilé-ìwé gíga àpapọ̀ Yunifásítì ti Èkó ní oṣù kẹsàn-án, ọdún 1977 láti kó nípa Mass Communication. Ó ṣetán ní ọdún 1980 pẹ̀lú second class upper.
Onanuga ṣiṣẹ́ fún Practions Partners ní Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọdún 1982 ó sì darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ti Ogun State Television gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ní oṣù kẹfà, ọdún 1982.
Ní oṣù kéje, ọdún 1983, ó tẹ̀síwájú lọ sí The Guardian ní Èkó gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ akọ̀ròyìn ó sì kúrò ní déédé oṣù mẹ́tàdínlógún lẹ́yìn àtibẹ̀rẹ̀ Titbits ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
Nígbà tí ìgbìyànjú rẹ̀ kùnà, Onanuga lọ darapọ̀ mó National Concord ní oṣù kíní, ọdún 1985 gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá akọ kókó ìròyìn. Nígbà tó ya, wón darí rẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí ní African Concord magazine. Ní ọdún 1989, Onanuga jẹ́ akọ̀rọ̀yìn ìlú-sí-ìlú tí àkójọpọ̀ ìwé ìròyìn tí a dásílẹ̀ ní ìlú London. Lẹ́yìn ìgbà diẹ̀ lọ́dún náà, wón yàn án gẹ́gẹ́ bí akọ̀rọ̀yìn.
Ṣùgbón ní oṣù kẹ́rin, ọdún 1992, Onanuga kọ̀wé fiṣẹ́sílẹ̀ ní Concord lẹ́yìn tí ó ti kọ̀ láti bẹ apàṣẹ àwọn ológun, Apàṣẹ Ibrahim Babangida, lórí ìtàn-ìròyìn tó gbẹnután: Has Babangida Given Up? Ìtàn náà ni ó fà á tí àwọn apàṣẹ ológun fi ti concord group pa.
Onanuga pẹ̀lú Seye Kehinde, olórí City People Magazine, Dapo Olorunyomi atẹ̀wéjáde Premium Times, Sani Kabir, ẹni tí ó padà di Sarki of Hausawa ní Èbúté Mẹ́ta, Idowu Obasa, ẹni tó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alága ní ìjọba ìbílẹ̀ Onigbongbo ní Ìkẹjà, Babafemi Ojudu, sẹ́nátọ̀ ní Èkìtì àti Kunle Ajibade darapọ̀ láti dá TheNews Magazine sílẹ̀ ní oṣù kejì, ọdún 1993.
Lẹ́yìn tí àwọn ìjọba ológun ti ilé ìròyìn TheNEWS pa, àwọn ẹgbẹ́ yìí tún dá TEMPO magazine àti lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ wọ́n dá P.M.NEWS sílẹ̀ ní ọdún 1994.
Ìgbé ayé òṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2014, Onanuga sọ ifẹ́ ọkàn rẹ̀ láti gbé àpótí ìbò fún ipò sẹ́nátọ̀ ní ẹ̀ka ìlà-oòrùn ìpínlè Ògùn ti ìdìbò àpapọ̀ ọdún 2015 lábẹ́ ẹgbẹ́ All Progressives Congress, (APC). Nígbà ìṣèjọba ológun Sani Abacha, àwọn Security State Service dè é ní ìgbèkùn ní ìlú Èkó fún ìgbà díẹ̀ ṣùgbón ó ráyè sálọ ó sì kúrò ní orílẹ̀-èdè ó wá padà dé ní ọdún 1998 lẹ́yìn iku Abacha.