Bennet Omalu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bennet Omalu
Omalu in 2016
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹ̀sán 30, 1968 (1968-09-30) (ọmọ ọdún 55)[1]
Enugwu Ukwu, Anambra State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigeria
United States
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Nigeria, Nsukka (MBBS, 1990)
University of Pittsburgh Graduate School of Public Health
(MPH, Epidemiology, 2004)
Carnegie Mellon University
(MBA, 2008)
Iṣẹ́Medical doctor, forensic pathologist, professor, medical examiner
Gbajúmọ̀ fúnResearch into chronic traumatic encephalopathy in American football players[2]
Notable workTruth Doesn't Have a Side: My Alarming Discovery About the Danger of Contact Sports
Olólùfẹ́Prema Mutiso
Àwọn ọmọ2
Websitebennetomalu.com

Bennet Ifeakandu Omalu (ọjọ́ìbí September 30, 1968[1]) ni oníṣègùn, onímọ̀ ìwadí àìsàn ikú-aláìsí, àti onímọ̀ àìsàn iṣan-ìkanra ọmọ Nàìjíríà Amẹ́ríkà tó kọ́kọ́ já ọgbọ́n àti ẹni tó kọ́kọ́ kọ ìwé ìwádìí lórí àìsàn inú-opọlọ ìforígbá léraléra (CTE) ní àrin àwọn agbábọ́ọ̀lù Amẹ́ríkàn futúbọ̀lù nígbà tó ún siṣẹ́ ní Ilé-iṣẹ́ Iwádìí Ikú-aláìsí fún ìjọba ìbílẹ̀ Allegheny CountyPittsburgh.[2]

Omalu níbi tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní wounded warrior batallion

Lẹ́yìn náà ó ṣiṣẹ́ bíi oníwadìí àgbà àìsàn ikú-aláìsí fún ìjọba ìbílẹ̀ San Joaquin County, California, ó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní University of California, Davis, ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ áìsàn ikú-aláìsí àti ògùn iṣẹ́ yàrá-ìdánwò.[3]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Omalu ní ìlú Nnokwa, ní ìjọba ìbílẹ̀ Idemili South, Ìpínlẹ̀ AnambraNàìjíríà ní ọjọ́ 30 Oṣù Kẹsan ọdún 1968,[1] ìkẹfà nínú àwọn ọmọ méje. Wọ́n bíi nígbà Ogun Abẹ́lé Nàìjíríà, èyí jẹ́ kí àwọn ẹbí rẹ̀ ó sá kúrò ní ilé wọn ní abà Enugu-Ukwu. Wọ́n padà sí ilé wọn ní ọdún kejì lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bí Omalu.[4] Aránsọ ni ìyá rẹ̀, bẹ́ ẹ̀ sì ni bábá rẹ̀ siṣẹ́ iṣẹ́-ẹ̀rọ ìwá àlùmọ́nì, ó sì tún jẹ́ olórí àwùjọ ní Enugu-Ukwu. Orúkọ ìdílè wọn, Omalu, ni orúkọ sókí fún Onyemalukwube, tó túmọ̀ sí "ẹni tó mọ̀ ló ún sọ̀rọ̀."[4]

Ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Omalu bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nígbà tó di ọmọ ọdún mẹ́ta, ó sì wọlé ìdánwò sí Federal Government College Enugu fún ilé-ẹ̀kọ́ àgbà rẹ̀. Ó bọ́ sí ilé-ẹ̀kọ́ ìwòsàn nígbà tó dí ọmọ ọdún 16 ní Yunifásítì ilẹ̀ Nàìjíríà, Nsukka. Nígbà tó parí níbẹ̀ pẹ̀lú ìwé-ẹ̀rì ìwòsàn àti ìwé-ẹ̀rí iṣẹ́-abẹ (MBBS) ní June ọdún 1990, ó ṣe ìparí akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwòsàn, àti ìṣẹ́ ìránwọ́ bíi dókítà fún ọdún mẹ́ta ní ìlú Jos. Nítorí rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà lẹ́yìn tí ìjọba ológun Ibrahim Babangida fagilé ìdìbòyan ààrẹMoshood Abiola wọlé ní 1993,[4] Omalu bẹ̀rẹ̀ síní wá ànfàní fún iṣẹ́ ọmọwé ní Amẹ́ríkà. Omalu kó lọ sí ilú Seattle, ní Ipinle Washington ní 1994 láti ẹ̀kọ́ lórí ìmọ̀ àjákálẹ̀-àrùnUniversity of Washington. Ní ọdún 1995, ó kúrò ní Seattle, ó sì kó lọ sí Ìlú New York, ibẹ̀ ló ti dara mọ́ Harlem Hospital Center ti Columbia University fún ètò ẹ̀kọ́ ìṣiṣẹ́ ìwòsàn lórí ìmọ̀ àìsàn inú-ara àti àìsàn ilé-ìwòsàn.

Kó tó ṣe ẹ̀kọ́ ìṣíṣẹ́ ìwòsàn, ó gba ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bíi onímọ́ ìwádìí àìsàn ikú-aláìsí lábẹ́ Cyril Wecht tó jẹ́ alámọ̀ràn ìwádìí ikú-aláìsí pàtàkì ní Allegheny County ní Pittsburgh. Ní bẹ̀ ni Omalu tí bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ràn ìmọ̀ àìsàn isàn-ìkanra.

Omalu gba ìwé-ẹ̀rí ẹ̀kọ́ gíga àti ìwé-ẹ̀rí àṣẹ méje [5], ó tún gba ìwé-ẹ̀rí ìkẹ́gbẹ́ nínú ìmọ̀ àìsàn àti ìmọ̀ àìsàn isan-ìkanra pẹ̀lú University of Pittsburgh ní ọdún 2000 àti 2002, ìwé-ẹ̀rí gíga nínú ìlera árá ìgboro (master of public health, MPH) nínú ìmọ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ní ọdún 2004 láti University of Pittsburgh Graduate School of Public Health, àti master of business administration (MBA) láti Tepper School of BusinessCarnegie Mellon University ní ọdún 2008.[6][7]

Omalu di ọ̀gá olùgbèyẹ́wò òkú fún San Joaquin County, California láti ọdún 2007 títí di ìgbà tó jọ̀wọ́iṣẹ́ ní ọdún 2017 lẹ́yìn ìgbà tó fẹ̀sùn kan ṣẹ̀rífì agbègbè náà, tó tún jẹ́ olùgbèyẹ́wò òkú ibẹ̀, pé oún kọ wọ́ bọ ìwádìí àwọn ikú tó ṣẹlẹ̀ láti ba à dá àbò bo àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n pa àwọn ènìyàn.[8]

Omalu ni ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Àìsàn àti Ìwòsàn Ilé-àdánwò ní University of California, Davis.[7]

Ìwadìí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

CTE[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìyẹ̀wò òkú Mike Webster, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù Amẹ́ríkan Fuútbọ̀l tẹ́lẹ̀, tí Omalu ṣe ní ọdún 2002 ló fa ìtún gbéjáde àkíyèsí ìṣòro isan-ìkanra tó wá pẹ̀lú ìpalára orí léraléra tí wọ́n ún pè ní àìsàn inú-opọlọ ìforígbá léraléra, tàbí CTE, tí wọ́n ti ṣe ìjúwe rẹ̀ tẹ́lẹ̀ láàrin àwọn ajẹ̀ṣẹ́[9] àti àwọn oníṣẹ́ eré-ìdárayá míràn. Webster ti ṣe aláìsí lójijì lẹ́yìn iye ọdún tó ti ìyà ti jẹ́ nítorí ìfàsẹ́yìn òye àti làákàyè, ìbòsí, ìdàrú ìwàinú, ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn, ìlòkulò ògùn olóró, àti ìgbìyànjú láti pa ara ẹni. Bótilẹ̀jẹ́pé ọpọlọ Webster dà bíi pé kò ní ìsòro nígbà tí wọ́n yẹ òkú rẹ̀ wò, Omalu pinu láti fi owó ara rẹ̀ dá ṣe ìgbéyẹ̀wò ìsàn-ẹran ọpọlọ Webster.[10] Ó fura pé àisàn ọpọlọ bá Webster jà, nítorípé ó fi agbárí gbá léraléra, bí ó ti ún ṣẹlẹ̀ sí àwọn ajẹ̀sẹ́. Nípa lílo aró àkànṣe, Omalu rí protéìnì tau gbàngbà tó dì jọ nínú ọpọlọ Webster, tó ún kópa lórí ìwàinú, ìtara, àti àkóso làákàyè lọ́nà kannáà tí ìdìpọ̀ protéìnì beta-amyloid ṣe ún fa àrùn Alzheimer.[10]

Pẹ̀lú àwọn alábàásiṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ áisàn ní University of Pittsburgh, Omalu kọ ìwé ìwadìí rẹ̀ jáde nínú ìwe ìwadìí sáyẹ́nsì Neurosurgery ní ọdún 2005 nínú áyọkà tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, "Chronic Traumatic Encephalopathy in a National Football League Player". Nínú àyọkà yìí, Omalu tọrọ fún ìgbékà pí pọ̀ si lórí àrún náà: "A ṣe ẹ̀sùn àkọ́kọ́ tí à mọ̀ ṣí nú ìwé yìí nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbàjẹ́ isan-ìkanra ìgbà pípẹ́ nínú agbábọ́ọ̀lù NFL tó ti fẹ̀yìntì, tó ní ìbámu mọ́ àìsàn inú-agbárí ìfarapa léraléra (CTE). Ẹ̀sùn yìí pe àkíyèsí sí àìsàn yìí tí kò tíì jẹ́ gbígbé kà dáadáa láàrin àwọn oníṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù, tí a kò sì mọ́ iye méèló nínú wọn ni ó ni." (We herein report the first documented case of long-term neurodegenerative changes in a retired professional NFL player consistent with chronic traumatic encephalopathy (CTE). This case draws attention to a disease that remains inadequately studied in the cohort of professional football players, with unknown true prevalence rates."[11] Omalu gbàgbọ́ pé àwọn dókítà National Football League (NFL) yíò "dunnú" láti káá, à ti pé ìwádìí rẹ̀ yíò jẹ́ kí wọn ó wá "ojúùtú sí ìsòro náà."[10]

Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 "About Bennet Omalu" Archived 2019-01-06 at the Wayback Machine., Bennet Omalu Foundation website.
  2. 2.0 2.1 Laskas, Jeanne Marie (24 November 2015). "The Doctor the NFL Tried to Silence". The Wall Street Journal. Archived from the original on 25 November 2015. Retrieved 25 November 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Dr. Who Inspired Will Smith Film Speaks At UC Davis Commencement". Patch Media. Retrieved 5 November 2019. 
  4. 4.0 4.1 4.2 Laskas, Jeanne Marie (2015-11-24). Concussion. Random House Trade Paperbacks. ISBN 9780812987577. 
  5. [1]
  6. "CV: Bennet Omalu", UC Davis Medical Center
  7. 7.0 7.1 "Bennet Omalu, M.D., M.B.A., MPH, CPE, DABP-AP, CP, FP, NP". University of California, Davis Department of Pathology and Laboratory Medicine. Retrieved 1 September 2015. 
  8. Small, Julie (December 4, 2017). "Autopsy Doctor Resigns, Says Sheriff Overrode Death Findings to Protect Officers". KQED. https://ww2.kqed.org/news/2017/12/04/autopsy-doctors-sheriff-overrode-death-findings-to-protect-law-enforcement/. 
  9. Sabharwal RK, Sanchetee PC, Sethi PK, Dhamija RM. Chronic traumatic encephalopathy in boxers. J Assoc Physicians India. 1987 Aug;35(8):571-3.
  10. 10.0 10.1 10.2 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :3
  11. Omalu, Bennet I.; DeKosky, Steven T.; Minster, Ryan L.; Kamboh, M. Ilyas; Hamilton, Ronald L.; Wecht, Cyril H. (2005-07-01). "Chronic traumatic encephalopathy in a National Football League player". Neurosurgery 57 (1): 128–134; discussion 128–134. doi:10.1227/01.neu.0000163407.92769.ed. ISSN 1524-4040. PMID 15987548.