Jump to content

Bob-Manuel Udokwu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bob-Manuel Udokwu
Ọjọ́ìbíBob-Manuel Obidimma Udokwu
Ogidi, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNaijiria
Iṣẹ́Òṣèré àti
Adarí eré

Bob-Manuel Obidimma Udokwu tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹrin, jẹ́ òṣèré, adarí eré, olùgbéréjáde àti olóṣèlú ọmo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1]Oun ni o gba ami-eye ti Lifetime Achievement ni odun 2014 nibi ayeye 10th Africa Movie Academy Awards.[2][3][4] Wọ́n tún yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ ti Òṣèrékùnrin amúgbálẹ́gbẹ́ tí ó peregedé jùlọ ní bi ayẹyẹ àmì-ẹ̀yẹ ti 2013 Nollywood Movies Awards fún ipa ribi ribi tí ó kó nínú eré Adésuwà.

Ìgbé ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Obidimma ní ìlú Nkwelle-Ogidi, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá "Idemmili" ní Ìpínlẹ̀ Anambra, ní orílẹ-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Igbo pẹ̀lú.

Ètò èkọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti St. Peters, tí ó wà ní Coal Camp ní Ìpínlẹ̀ Enugu, nígbà tí ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Oraukwu Grammer School ni ìpínlẹ̀ kan náà, ṣáájú kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ti ìlú Port HarcourtÌpínlẹ̀ Rivers. Ó kẹkọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Eré Oníṣe, Ó sì gboyè ẹlẹ́kejì nínú ìmọ̀ Ìṣèlú ní ilé-ẹ́̀kọ́ Fásitì ti Ìpínlẹ̀ Èkó.

Òun àti ẹbi rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú arábìnrin Cassandra Udokwu, tí wọ́n sì bímọ méjì fúnra wọn. Ó sọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ní Garvey Udokwu ní ìfisọrí ọ̀gá rẹ̀ nínú ìṣèlú Marcus Garvey.[5]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ tún wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Bob-Manuel Udokwu joins Gov Obiano’s cabinet". Vanguard (Nigeria). Retrieved 10 August 2014. 
  2. NONYE BEN-NWANKWO AND KEMI VAUGHAN (July 27, 2013). "Bob-Manuel Udokwu is not happy now". The Punch. Archived from the original on 12 August 2014. Retrieved 10 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. NKARENYI UKONU (November 18, 2012). "Ladies warn me not to pick my husband’s call again — Cassandra Udokwu". The Punch. Archived from the original on 29 November 2013. Retrieved 10 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Ayo Onikoyi (4 May 2014). "How Amaka Igwe made me a star – Bob Manuel-Udokwu". Vanguard (Nigeria). Retrieved 10 August 2014. 
  5. "Biography, Profile, Movies and Success Story of Bob Manuel Udokwu.". 30 April 2018. Archived from the original on 21 August 2018. Retrieved 24 September 2018.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)

External links[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control


Àdàkọ:Nigeria-actor-stub