Jump to content

Marcus Garvey

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Marcus Garvey
Fọ́tò Garvey ní ọdún 1924
Ọjọ́ìbí(1887-08-17)17 Oṣù Kẹjọ 1887
Saint Ann's Bay, Jamaica
Aláìsí10 June 1940(1940-06-10) (ọmọ ọdún 52)
West Kensington, London, England, United Kingdom
Iléẹ̀kọ́ gígaBirkbeck, University of London
Iṣẹ́Atẹ̀wéjáde, oníròyìn
Gbajúmọ̀ fúnActivism, black nationalism, Pan-Africanism
Olólùfẹ́
Amy Ashwood
(m. 1919; div. 1922)

Amy Jacques (m. 1922)
Àwọn ọmọ2
Parent(s)Marcus Mosiah Garvey Sr.
Sarah Anne Richards

Marcus Mosiah Garvey Jr. ONH (17 August 1887 – 10 June 1940) jẹ́ alákitiyan olóṣèlú, atẹ̀wéjáde, oníròyìn, oníṣòwò, àti ọlógbọ́n-ọ̀rọ̀ ará Jamáíkà. Òhun ló jẹ́ olùdásílẹ̀ àti Ààrẹ-Gbogbogbòò ẹgbẹ́ Universal Negro Improvement Association and African Communities League (UNIA-ACL, tó gbajúmọ̀ bíi UNIA). Ìròayé rẹ̀ sọ ọ́ di aṣeọmọorílẹ̀-èdè aláwọ̀dúdú àti Aṣe Pan-Afrikanisti, àwọn ìròayé rẹ̀ ni a mọ̀ sí Iṣe Garvey.

Wọ́n bí Garvey ní Saint Ann's Bay, Jamáíkà nibi tó ti kọ́ṣẹ́ ìtẹ̀wé nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. Ní ilú Kingston, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kó tó kò lọ sí Costa Rica, Panama, àti England fún ìgbà díẹ̀. Nigbà tó padà sí Jamáíkà, ò dá ẹgbẹ́ UNIA sílẹ̀ ní ọdún 1914. Ní ọdún 1916, ó kó lọ sí Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbẹ̀, ó dá ẹ̀ka UNIA sílẹ̀ ní àdúgbò Harlem ní ilú New YorK. Ó tẹnumọ́ ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ láàrin àwọn ará Áfríkà àti àwọn ará Áfríkà èyìn odi, ó jà láti fòpin sí ìjọba ìmúnisìn àwọn òyìnbó káàkiri ilẹ̀ Áfríkà àti fún ìṣọ̀kan olóṣèlú gbogbo ìlẹ̀ Áfríkà.Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]