Bola Are

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bola Are
Ọjọ́ìbí(1954-10-01)1 Oṣù Kẹ̀wá 1954
Erio, Ìpínlẹ̀ Ekiti, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Olórin ẹ̀sìn kìrìtẹ́ẹ́nì
Ìgbà iṣẹ́1977–ó ń lọ

Bola Are, wọ́n bi ní ọjọ́ kínní, oṣù kẹ̀wá, ọdún 1954. Ó jẹ́ olórin ẹ̀sìn kìrìtẹ́ẹ́nì ti orílèdè Nàìjíríà, àti pé ó ti jẹ́ adarí ẹgbẹ́ àwọn olorín ẹ̀sìn kìrìtẹ́ẹ́nì ti Nàìjíríà rí.[1][2]

Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ Ayé Rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bi Bola ní ọjọ́ kínní, oṣù kẹ̀wá, ọdún 1954, ní Erio, ìlú ìwọ̀-oòrùn ìjọba agbègbè Ekiti, ti Ìpínlẹ̀ Èkìtì, gúúsù-mọ́-ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ ni alàgbà Babayomi àti ìyá rẹ̀ T.A Babayomi, tí wọ́n ń ṣe ọmọ ilẹ̀ Erio-Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Nàìjíríà.[3] Àwọn wòólì mẹ́rin pàtàkì ni ó tọ́ Bola ní ìjọ Apósítólíkì(CAC)- Apostle Ayodele Babalola, Prophet Babajide, Prophet Akande àti Prophet T.O. Obadare.[4]

Ìwé-kíkà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Ìjọ Apósítólíkì(CAC) ilú tí wọ́n bi sí, ni Are ti kàwé alákọ́bẹ̀rẹ̀, tí ó sì ka ìwé ẹ̀kọ́ girama ní ilé-ìwé Girama Ìjọ Apósítólíkì ní Efon Alaye ní ìlú Ekiti, ó tún tẹ̀ síwájú láti gba ìwé-ẹ̀rí ní ẹ̀kọ́ Ìṣirò-tó-rọ̀-mọ́-gbígba-ìnáwó-sílẹ̀ ní politẹ́kínììkì-Ìbàdàn. Ní oṣù kèje, ọdún 1985, ní St. John's University, Àrẹ gba oyè ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí ó ga jùlọ(phD) ní ẹ̀kọ́ orin.[5]

Mọ Ẹbí Àrẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1977, ni Bola fẹ́ olóògbé J.O Are, tí Ọlọ́run bùkún wọn pẹ̀lú àwon ọmọ. Akorin àti olórin ni àwọn ọmọ Bola. Ní ọj̀ọ karùn-ún oṣù kẹ̀wa, ọdún 2013, Àrẹ ṣe ayẹyẹ ogójì ọdún láyé.

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ọmọ ọdún méjì ni Are ti ń kọrin, o ti mọ̀ pé òun ma sin Olúwa lái èwe rẹ̀, èyí sì ni ìlépa rẹ̀. Ọjọ́ díẹ̀ síwájú kí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àkọ́kọ́ rẹ̀ tó dé ni àwọn òbí Are sọ fun pé, ó ti ń kọrin, èyí jẹ́ kí ó ma rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ẹni tó ní ẹ̀bùn orin atọ̀run wá. Láti ìgbà tí Are ti yan orin kíkọ láàyò, ó ṣẹ̀da egbẹ́ orin, tí ò pè ní Bola and Her Spiritual Singers ní ọjọ́ ẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà, ọdún 19733. Ní oṣù kẹ̀jọ, ọdún1973, Are gbé awo-orin àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde Baba Ku Ise.[6] Ní 2014, Are ti gbé awo orin tó kọjá àádọ́rin iye lọ jáde.

Àwọn Awo-Orin(1965-2000)[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Divine Praise of the King Of Kings – 1965
  • Ajaga Babiloni Wooo – 1967
  • Anointed Praise 2 – 1970
  • Bola Are Live – 1971
  • Agbara Esu Ko Da Nibiti Jesu Gbe Njoba – 1971
  • Homage 1 – 1974
  • Halleluyah Jesus Lives – 1974
  • Adura Owuro – 1977
  • Baba Kuse – 1977
  • Anointed Praise 1 – 1979
  • Jesus Is Coming Back, Be Ready! – 1981
  • Bibo Jesu Leekeji – 1988
  • Gbongbo Idile Jesse – 1991
  • Homage 2 (Tribute To Apostle T.O Obadare) – 1995
  • Lion Of Judah – 1995
  • Oore Ofe – 1998
  • Power In Praise – 2000
  • Apostle Joseph Ayodele Babalola – 2000

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Tade Makinde. "Bola Are marks 40 years on stage To dedicate cds to Obadare". tribune.com.ng. Archived from the original on 28 February 2015. Retrieved 28 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Gospel artistes that made 2014 memorable". Vanguard News. Retrieved 28 February 2015. 
  3. "EVANG. BOLA ARE SHARES THE STORY OF HER MUSIC CAREER". globalexcellenceonline.com. Archived from the original on 27 February 2015. Retrieved 28 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Bola Are Archives". xclusivehits.com Download Latest Gospel Music And Nigerian Gospel Song. 1954-10-01. Retrieved 2022-05-22. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  5. "Bola Are". Last.fm. Retrieved 28 February 2015. 
  6. Evangelist Bola Aare - OnlineNigeria.com Archived February 27, 2015, at the Wayback Machine.