Jump to content

Calamus erectus

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Calamus erectus, tí wọ́n tún máa ń pè ní viagra palm tí orúkọ ìbílẹ̀ rẹ̀ tún jẹ́ tynriew, tara, àti zhi li sheng teng, jẹ́ èso olódòdó nínú ìdílé Arecaceae.[1] Erectus túnmọ̀ sí ìwà ọ̀gbìn náà láti dàgbà sókè yàtọ̀ sí àwọn èyí tó má ń lọ́ mọ́ nǹkan, tàbí mọ́ igi mìíràn, bí i ẹ̀yà Calamus.

Calamus erectus wọ́pọ̀ láàárín àwọn India àti Nepal apá Ìlà-oòrùn sí Àríwá Laos àti apá Gúúsù China. Tí India jẹ́ ìbílẹ̀ sí àwọn ará ìpínlẹ̀ Arunachal Pradesh, Mizoram, Sikkim, Assam, West Bengal, Manipur, àti Meghalaya Tí China dẹ̀ jẹ́ ìbílẹ̀ sí àwọnYunnan. Wọ́n ti mu wọ United States. Ó máa ń dàgbà ní igbó kìjikìji tàbí ní orí-òkè. Ó sì tún máa ǹ wù ní Tista àti aṣálẹ̀ Rangit, ní apá Ìwọ̀-oòrùn Bengal àti Sikkim.[1]

Calamus erectus jẹ́ ọ̀pẹ tó ga. Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀yà Calamus èyí tó kù, kò kì í so mọ́ igi mìíràn, ó máa ń ga ní, bí i mítà mẹ́ta sí 3 meters (9.8 feet) ní ìwọ̀n gíga. Ẹ̀ka rẹ̀ ò lágbára púpọ̀, ó ga tó ìwọ̀n 6 meters (20 feet) ní fífẹ̀ àti 5 centimeters (2.0 inches) ní àárín.

Èso náà ní vitamin C, vitamin A, vitamin E, calcium, magnesium, àti phosphorus.[2]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Calamus erectus - Palmpedia - Palm Grower's Guide". www.palmpedia.net. Retrieved 5 March 2021. 
  2. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named India