Candido Da Rocha
Ìrísí
Candido Joao Da Rocha ( 1860 - 1959)[1][2] jẹ́ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó jẹ́ onílẹ̀, ayanilówó tí ó n Water House tó wà ní àdùgbò von Kakawa , Lagos Island, Lagos, tí ó tun ni ilé ìtura Bonanza tí ó wà ní Ìlú Èkó. Da Rocha jẹ́ ọmọ bíbí iléṣà, tí wọ́n bí sí inú ebí Joao Esan Da Rocha, tí ó jẹ́ ẹrú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀;[3] bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wà nígbà tí wọ́n kóo lẹ́rú ní ọdún 1840 tí wọ́n sì bí Candido sí Bahia agbègbè kan ní orílẹ̀ èdè Brazil.[4]