Charlotte Ọlájùmọ̀kẹ́ Ọbasá
Oloori Charlotte Ọlájùmọ̀kẹ́ Ọbasá | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ọjọ́ keje oṣù kìíní ọdún 1874 Èkó |
Aláìsí | December 23, 1953 Èkó | (ọmọ ọdún 79)
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Orúkọ míràn | Charlotte Blaize |
Iṣẹ́ | Afowóṣàánú |
Gbajúmọ̀ fún | Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ awakọ̀, Anfani Bus Service |
Olólùfẹ́ | Ọmọba Òrìṣàdípẹ̀ Ọbasá |
Àwọn ọmọ | 5 |
Àwọn olùbátan | Kòfowórọlá Adémọ́lá |
Charlotte Ọlájùmọ̀kẹ́ Ọbasá tí orúkọ abilékọ rẹ̀ ń jẹ́ Blaize, ní wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù kìíní ọdún 1874, tí ó sìn kú lọ́jọ́ kẹtàlélógún ọdún 1953 jẹ́ gbajúmọ̀ Afowóṣàánú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ bíbí pàràkòyí oníṣòwò R.B. Blaize àti ìyàwó rẹ̀ tí ó jẹ́ oníwòsàn Òrìṣàdípẹ̀ Ọbasá.
Ìgbé-ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Charlotte Ọlájùmọ̀kẹ́ Ọbasá jẹ́ ọmọ Saro tí wọ́n bí sí ìdílé gbajúmọ̀ òṣèlú àti ọlọ́rọ̀, Richard Beale Blaize, àti aya rẹ̀, Emily Cole Blaize. O lo ìgbà èwe rẹ̀ ni ìlú Èkó, níbi tí bàbá rẹ̀ ti jẹ́ olùdásílẹ̀ ìwé-ìròyìn tí wọ́n pè ní The Lagos Times and Gold Coast Colony Advertiser àti The Lagos Weekly Times.[1] Ó kàwé gidi gan-an. Ó kọ́kọ́ kàwé ní ilé-ìwé Anglican Girls' School ní Èkó,lẹ́yìn náà, ó sọdá lọ kàwé sí i lókè òkun lórílẹ̀-èdè England [2]
Lọ́dún 1902, ó fẹ́ Ọmọba Sàró, Ọmọba Òrìṣàdípẹ̀ Obasá. Odidi ilé tuntun ni bàbá rẹ̀ fi fún wọn ní ẹ̀bùn ìgbéyàwó. Ọmọ márùn-ún ni wọ́n bí fún ara wọn. [3]
Ó jẹ́ ìbátan Kòfowórọlá Adémọ́lá [4] Ọlájùmọ̀kẹ́ jẹ́ oníṣòwò àti pàràkòyí afowóṣàánú tó ṣáájú ìjà fún ẹ̀tọ́ àti ìkàwé ọmọ obìnrin. Nítorí akitiyan rẹ̀ ni wọ́n fi dá ilé-ìwé àwọn obìnrin tí wọ́n pè ní Lagos School for Girls tí ó wà di Wesleyan Girls' High School silẹ lọ́dún 1907, lórí ilẹ̀ tí ó yá wọn. Lọ́dún 1913, ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ awakọ̀ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní ìlú Èkó tí ó pè ní Anfani Bus Service, nígbà náà, ó ní ọkọ̀ Àjàgbé mẹ́ta, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ taasí mẹ́ta àti ọkọ̀ èrò, bọ́ọ̀sì mẹ́fà kí ó tó di ọdún 1915.[5]
Lọ́dún 1914,ó wà lára àwọn tí wọ́n dá ẹgbẹ́ Ògbóni ìgbàlódé Reformed Ogboni Fraternity sílẹ̀. Òun ni ó kọ́kọ́ joyè Ìyá Àbíyè nínú ẹgbẹ́ náà lọ́dún kan náà.[6]
Ó tà téru nípàá lọ́dún 1953.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Olajumoke Obasa: The Selfless Social-Worker who established first bus service in Lagos to ease pain of commuters". Neusroom.com. Retrieved October 28, 2020.
- ↑ Akintola 1992, p. 86.
- ↑ Akintola 1992, p. 82.
- ↑ George 2014, p. 1898.
- ↑ Schoonmaker 2003, p. 13.
- ↑ Akintola, Akinbowale (1992), The Reformed Ogboni Fraternity (R.O.F.): The Origins and Interpretation of Its Doctrines and Symbolism, pp. 9 and 10
- ↑ Akintola 1992, pp. 85 and 86.