Chika Oduah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chika Oduah
Chika Oduah in 2016. Credit: Silvia Varela
Ọjọ́ìbíChikaodinaka Sandra Oduah
(1986-03-14)Oṣù Kẹta 14, 1986
Ogbaru, Anambra State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian, American
Iléẹ̀kọ́ gíga
Iṣẹ́Journalist
Ìgbà iṣẹ́2010–present
Websitechika-oduah.com

Chikaodinaka Sandra Oduah tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún 1986 jẹ́ akọ̀ròyìn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìlú America tí ó sì jẹ́ olóòtú ìròyìn lórí afẹ́fẹ́, akọ̀wé, ayàwòrán.[1][2][3][4] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ CNN Multichoice African Journalists Award ní ọdún 2016. Látàrí ipa tó kó lórí ìròyìn àwọn ọmọ Chibok tí Boko Haram gbé pamọ́. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akọ̀ròyìn lágbàáyé láti lọ sí ìlú náà ni apá Àríwá - ìlà oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Akitiyan rẹ̀ náà ló mu gba àmì-ẹ̀yẹ ti Trust Women Journalist of the Year láti ọwọ́ Thomson Reuters Foundation ní ọdún 2014.[5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-èkó rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀yà Igbo ni Oduah ti wá. Òun ló dàgbà jù lọ láàárín ọmọ méje tí àwọn òbí rẹ̀ bí. A bí sínú ìdílé onígbàgbọ́ ti Dr. Emmanuel àti Mercy Oduah ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún 1986 ní Ogbaru nílùú Anambra State.[6] Ó sì tẹ̀lé àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjì tí wọ́n kúrò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti lọ sí Metro Atlanta ní United States.[7] Ó dára pọ̀ mọ́ ìwé-ìròyìn VOX nígbà tí ó wà nílé ìwé.

Ní ọdún 2004, Oduah ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Center for Pan-Asian Community ServicesDoraville, Georgia níbi tí ó ti ń kọ́ àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n sá àsálà fún ẹ̀mí wọn láti Sudan, Afghanistan, Liberia, Iraq, Bosnia, Rwanda àti South Sudan. Láàárín ọdún 2004 sí 2008, ó lọ sí Georgia State University níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa fíìmù, anthropology àti broadcast journalism tí ó sì ti gboyè Bachelor of arts degree nínú Anthropology àti Bachelor of arts degree kejì nínú telecommunications. Nígbà tó wà ní Georgia State University, òun ni igbákejì ààrẹ fún University's chapter of the Society for Professional Journalists. Ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Medill School of Journalism nígbà kan rí níbi tó ti gboyè Master of Science degree lọ́dún 2010 lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ lórí Broadcast journalism.[8]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 2009, ó ṣiṣẹ́ ayàwòrán nílùú Atlanta ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akàròyìn lórí afẹ́fẹ́ àti olóòtú agbétò sórí afẹ́fẹ́ fún K24Nairobi, Kenya níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ fún Jeff Koinange lọ́dún 2010. Ó tún ṣiṣẹ́ fún National Broadcasting Corporation àti Sahara Reporters gẹ́gẹ́ bíi akọ̀ròyìn.[9][10]

Oduah padà sórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2012, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọ̀ròyìn àti agbéròyìnjáde lórí afẹ́fẹ́ tí ó dá dúró fún Al Jazeera.[11] Ó tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú CNN àti Associated Press. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó jẹ́ akọ̀ròyìn fún Voice of America àti English language channel fún France 24.[12] Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ pẹ̀lú ìlúmọ̀ọ́ká olórin D’Banj fún Sahara TV jẹ́ èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn wò tí ó sì bí èrò lóríṣiríri.[13] Wọ́n tí ṣàgbéjáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ Chika Oduah sí orí ẹ̀rọ ìgbéròyìnjáde lóríṣiríri bíi New York Times, The Guardian, Al Jazeera, The Daily Beast, CNN àti The Huffington Post.[14][15][16]

Ní ọdún 2014, Oduah di ìlúmọ̀ọ́ká látàrí iṣẹ́ tó ṣe lórí àwọn ọmọ Chibok tí wọ́n gbé pa mọ́, èyí sì mu gba àmì-ẹ̀yẹ ti Trust Women fún Journalist of The Year Award láti ọwọ́ Thomson Reuters Foundation.[17] Ọkàn lára àwọn àgbéjáde iṣẹ́ rẹ̀ lórí The Atlantic tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ In the Land of Nigeria's Kidnapped Girls ló mu gba àmì-ẹ̀yẹ Livingston Awards for Young Journalists lọ́dún 2015.[18]

Ààtò àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òun ló gba àmì-ẹ̀yẹ African Story Challenge award lọ́dún 2015 láti ọwọ́ African Media Initiative àti International Center for Journalists látàrí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ìtànkálẹ̀ májèlé ní Nàìjíríà. Èyí náà ló bí àmì-ẹ̀yẹ Dow Technology & Innovation Reporting Award ní CNN MultiChoice African Journalist Awards lọ́dún 2016.[19] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹta ọdún 2016, ó wà lára àwọn obìnrin tí YNaija kà kún ọgọ́rùn-ún obìnrin tí ayé wọn wunni.[20][21][22]

Ní ọdún 2018, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Percy Qoboza Award, èyí tó jẹ́ àmì-ẹ̀yẹ ọdọọdún tí The National Association of Black Journalists ní United States máa ń fún àwọn akọ̀ròyìn tó tayọ tó sì ní ẹ̀mí Percy Qoboza.[23][24][25]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Chika Oduah: Freelance Journalist Profile". paydesk. Retrieved 2020-05-03. 
  2. Courtney McLarnon (5 June 2015). "Our Interview of the Month with Chika Oduah". Make Every Woman Count. Retrieved 15 March 2016. 
  3. Sarda, Juan (5 March 2016). "Una mujer contra Boko Haram" (in Spanish). El Mundo. http://www.elmundo.es/yodona/2016/03/05/56d719d346163f79118b45b0.html. Retrieved 10 March 2016. 
  4. Chika Oduah (30 June 2015). "A Close Encounter With Boko Haram". New York Times (Zhu Ping). http://mobile.nytimes.com/2015/07/01/opinion/a-close-encounter-with-boko-haram.html?_r=0&referer=. Retrieved 10 March 2016. 
  5. Walstrom, Stephanie (5 May 2015). "Award Winner Chika Oduah on women, technology and "demystifying" Africa". ONE Campaign. Archived from the original on 10 March 2016. https://web.archive.org/web/20160310170551/http://www.one.org/international/blog/award-winner-chika-oduah-on-women-technology-and-demystifying-africa/. Retrieved 3 March 2016. 
  6. PeoplePill (1986-03-14). "Chika Oduah: Nigerian journalist - Biography and Life". PeoplePill. Retrieved 2020-05-03. 
  7. Nkem-Eneanya, Jennifer (2 April 2013). "Chika Oduah: The Journalist and Writer Extraordinaire Is Live On Konnect Africa!!!". Konnect Africa. Retrieved 24 March 2016. 
  8. Goldsmith, Belinda (18 November 2014). "PROFILE-Nigeria journalist puts faces to girls kidnapped by Boko Haram". Thomson Reuters Foundation. Archived from the original on 12 March 2016. https://web.archive.org/web/20160312092547/http://news.trust.org//item/20141118182901-lwhyc/?source=leadCarousel. Retrieved 3 March 2016. 
  9. "Chika Oduah". HuffPost. 2017-07-19. Retrieved 2020-05-03. 
  10. "Chika Oduah". IWMF. Retrieved 2020-05-03. 
  11. Seyhan, Eda (2013-10-12). "Chika Oduah". Al Jazeera. Retrieved 2020-05-03. 
  12. Ochieng, Akinyi (31 May 2015). "Behind the headlines with Chika Oduah". Ayiba Magazine. Archived from the original on 8 March 2016. https://web.archive.org/web/20160308084842/http://ayibamagazine.com/behind-the-headlines-with-chika-oduah/. Retrieved 4 March 2016. 
  13. "BN Bytes: Grilling or Interview? You Decide. Check Out D’banj on SaharaReportersTV". BellaNaija. 19 February 2012. Retrieved 15 March 2016. 
  14. "Nigeria - A Fractured Giant?". The Huffington Post. 15 October 2014. http://m.huffpost.com/us/entry/5979166. Retrieved 4 March 2016. 
  15. "Chibok: the village that lost its daughters to Boko Haram". The Guardian (Chibok). 15 May 2014. https://www.theguardian.com/world/2014/may/15/chibok-nigeria-200-kidnapped-schoolgirls-boko-haram. Retrieved 4 March 2016. 
  16. "Nigerian journalist who met escaped girls speaks out". Global Journalist. 2014-12-22. Archived from the original on 2020-08-08. Retrieved 2020-05-03. 
  17. Oduah, Chika (2014-05-21). "In the Land of Nigeria’s Kidnapped Girls". The Atlantic. Retrieved 2020-05-03. 
  18. Oduah, Chika (21 May 2014). "In the Land of Nigeria's Kidnapped Girls". The Atlantic. Retrieved 10 March 2016. 
  19. CNN International (2015-12-09). "CNN Journalist Award: 2016". Africa.cnnjournalistaward.com. Archived from the original on 2017-01-16. Retrieved 2017-02-09. 
  20. Salihu, Idoko (19 December 2016). "Winners of Future Awards Africa 2016 named". Premium Times. https://www.premiumtimesng.com/arts-entertainment/naija-fashion/218400-winners-future-awards-africa-2016-named.html. Retrieved 15 January 2017. 
  21. "21 winners emerge in The Future Awards Africa". The Guardian. 20 December 2016. http://guardian.ng/news/21-winners-emerge-in-the-future-awards-africa/. Retrieved 15 January 2017. 
  22. N, Emeka (8 March 2016). "‘Arunma Oteh, Tara Fela-Durotoye, Yasmine Belo-Osagie & more. These are Nigeria’s 100 Most Inspiring Women – #YWomen100 #LLA100Women". YNaija. http://ynaija.com/nigeria-100-women-inspiring-influential/. Retrieved 9 March 2016. 
  23. "Past Special Honors Recipients - National Association of Black Journalists". www.nabj.org. Retrieved 2019-03-10. 
  24. "Chika Oduah – Foreign Policy". Foreign Policy – the Global Magazine of News and Ideas. 1970-01-01. Retrieved 2020-05-03. 
  25. Ochieng, Akinyi (2015-05-31). "Behind the Headlines with Chika Oduah". Ayiba Magazine. Archived from the original on 2016-03-08. Retrieved 2020-05-03.