Chinyere Kalu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chinyere Kalu
Ọjọ́ìbíNàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Commercial pilot

Chinyere Kalu, MFR (orúkọ àbísọ rẹ̀ ni Onyenucheya) jẹ́ obìnrin ọmọ orílẹ̀-edè Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti di awakọ̀ èrò ojú òfuurufú àti obínrin àkọ́kọ́ láti wa ọkọ̀ ojú Òfurufú ní orílẹ̀-ede Nàìjíríà.[1]

Ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó jẹ́ ọmọ bíbí Akwete, ijoba ìbílẹ̀ ìwọ oòrùn Ukwa ní Ìpínlẹ̀ Ábíá, ìwọ oòrùn Nàìjíríà, Kalu dàgbà lábé ìtọ́jú ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwọn òbí rẹ̀ yapa. Àwòkọ́se aunti rẹ̀ lówò tí ó fi wọ inú isẹ́ wíwà ọkọ̀ ojú òfuurufú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mọ aunti rẹ̀ fún lílọ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn.[2][3] Ó lọ sí ilé-ìwé Anglican Girls Grammar School, Yaba, Ìpínlẹ̀ Èkó fún ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀,[4] kí ó tó kọ́ nípa wíwà ọkọ̀ ojú òfuurufú ti aládàáni àti fún àwọn èrò ní ọdún 1978 ní ilé-ìwé Nigerian College of Aviation Technology, Zaria.[5] Ó padà tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú si ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé fún ẹ̀kọ́ ìmò ojú òfuurufú ní Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan àti ní Orílẹ̀ èdè Amerika kí ó tó gba ìwé ẹrí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi awakọ̀ ojú òfuurufú ní ọjọ́ ogún oṣù karùn-ún ọdún 1981, ní ilé-ìwé Nigerian College of Aviation Technology.[6]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Ben, Agande (1 December 2012). "Dangerous Flight: I flew plane with water in the engine – Chinyere Kalu, first female commercial pilot". Vanguard Nigeria. http://www.vanguardngr.com/2012/12/dangerous-flight-i-flew-plane-with-water-in-the-engine-chinyere-Kalu-first-female-commercial-pilot/. 
  2. "Captain Chinyere Kalu; Meet The First Nigeria Female Pilot" (in en-US). Information Nigeria. 7 March 2017. http://www.informationng.com/2017/03/captain-chinyere-Kalu-meet-first-nigeria-female-pilot.html. 
  3. Jo, Daniel (2017). Captain Chinyere Kalu; Meet The First Nigeria Female Pilot. 
  4. "I'm happy not sacrificing my family for career — Chinyere Kalu". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-10-11. Retrieved 2022-03-06. 
  5. "First Women: First Nigerian Woman Pilot". woman.ng. 18 June 2015. Archived from the original on 13 February 2017. Retrieved 13 February 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. N. Nik Onyechi (1989). Nigeria's book of firsts: a handbook on pioneer Nigerian citizens, institutions, and events. Nigeriana Publications. ISBN 9789782839992. https://books.google.com/books?id=l9JBAAAAYAAJ.