Christie Ade Ajayi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Christie Ade Ajayi
Ọjọ́ìbíChristie Aduke Martins
13 Oṣù Kẹta 1930 (1930-03-13) (ọmọ ọdún 94)
Ile Oluji, Ìpínlẹ̀ Ondo, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Olólùfẹ́J. F. Ade Ajayi

Christie Ade Ajayi (tí a bí ní ọdún 1930) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń jà fitafita fún kíkó àwọn ọmọdé bí a ti ń kàwé láti ìgbà tí wón ti wà ní ọmọ jòjòló. Ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ní èdè Gẹ̀ẹ́sì fún àwọn ọmọdé, àwọn ìwé rẹ̀ sì jẹ́ ìwé nípa Nàìjíríà. Ó tún jẹ́ olùkọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó s jẹ́ ọmọ àwọn ẹgbẹ́ kọ̀kan tí ó ń bìkítà fún ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé.

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Christie Aduke Martins ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹta ọdún 1930 ní Ile Oluji, Ìpínlẹ̀ Òndó, Christie Ade Ajayi (tí wón tún le ko bi Ade-Ajayi) lọ sí Kudeti Girls' School ní ìlú Ibadan (tí àwọn ènìyàn wá padà mọ̀ sí St. Anne's School), lẹyìn náà, ó lọ sí United Missionary College, Ibadan níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ láti di olùkọ́.[1] Ó tún tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Froebel Institute, London[2] àti ní Institute of Education níbi tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ Diploma nínú ìmò títọ́ àwọn ọmọdé ní ọdún 1958.[1] Láàrin ọdún 1952 sí 1978, ó kọ́ àwọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé ní Nàìjíríà àti ní ilé-ìwé kan ní London, níbi tí ó ti di olórí ilé-iwé náà headmistress,[3] Ó tún tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní San Jose State University, California.[1] Ó fẹ́ J. F. Ade Ajayi ní ọdún 1956, àwọn méjèèjì sí bí ọmọ márùn-ún[4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 Henrietta C. Otokunefor, Obiageli C. Nwodo, Nigerian Female Writers: A Critical Perspective, Malthouse Press 1989, pp 99-100
  2. Philomena Osazee Esigbemi Fayose, Nigerian Children's Literature in English, AENL Educational Publishers, p70
  3. Kunle Ifaturoti, Tinu Ifaturoti, To have and to hold, NPS Educational, 1994, p250
  4. [https://www.theguardian.com/books/2014/sep/10/jf-ade-ajayi JF Ade Ajayi obituary in The Guardian, 10 Sep 2014