De General
Joshua Sunday, tí orúkọ gbajúgbajà rẹ̀ ń jẹ́ De General, jẹ́ apanilẹ́rìn-ín ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Nígbà kan, ó díbọ́ bí aṣiwèrè kó ba lè fún àwọn ènìyàn tó bá ràn án lọ́wọ́ lówó.
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Apanilẹ́rìn-ín náà ń rí owó látara ṣíṣàgbéjáde fọ́nrán lórí Facebook àti YouTube. Ó mú Jackie Chan gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe rẹ̀, nítorí ó jẹ́ jagun-jagun tó máa ń lo àwọn eré ìjagun fi pani lẹ́rìn-ín.[3]
Àríyànjiyàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn àjo-tó -ń-rí-sí-oògùn-olóró, ìyẹn National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) ti fìgbà kan fipá mú De General fún ẹ̀sùn pé ó ní ìpìn nínú oògùn olóró, wọ́n sì tì í mọ́lé fún ọ̀sẹ̀ kan.[4] Wọ́n dá a lẹ́jọ́ ní Ilé-ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀, adájọ́ tó sì ṣe ẹjọ́ náà ni Daniel Osiagor. Adájọ́ náà sọ pé kò jẹ̀ bí, wọ́n kọ̀ fà á létí ni, wọn ò dá a lẹ́jọ́ tàbí ran lọ sẹ́wọ̀n.[5]
Lẹ́yìn tí wọ́n tú u sílẹ̀, De General ṣe ìkéde pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rí àwon oògùn olóró nínú ilé òun, òun kò mu oògun olóró rárá. Pé iṣẹ́ apanilẹ́rìn-ín ni òun ń ṣe.[6][7]
Àwọn ènìyàn ò fi tayọ̀tayọ̀ gba ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí. Ọ̀kan lára àwọn tó sọ̀rọ̀ ni BasketMouth, tó ní wọ́n kọ̀ ń ṣe owó-orí báṣubàṣu ni.[8] Bákan náà, àwọn àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ̀-ọmọnìyàn, ìyẹn Human Rights Writers Association of Nigeria bu ẹnu àté lu NDLEA fún ẹ̀gbin tí wọ́n kó bá apanilẹ́rìn-ín náà, nígbà tí wọ́n sì fi Abba Kyari tó jẹ́ ògbóǹtarìgì a-mu-oògùn-olóró sílẹ̀.[9] Mr. Macaroni náà bu ẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n ṣe hùwà sí De General nígbà tí wọ́n mú u.[10]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Online comedy is more lucrative than it seems — De General". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-11-26. Archived from the original on 2022-12-07. Retrieved 2022-12-07.
- ↑ "Why I disguise as mad man to bless people, by De General The Nation Newspaper" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-05-21. Retrieved 2022-12-07.
- ↑ "Online comedy is more lucrative than it seems — De General". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-11-26. Archived from the original on 2022-12-07. Retrieved 2022-12-07.
- ↑ "De General spends one week in NDLEA custody, awaits trial in 'drug' case". TheCable Lifestyle (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-19. Retrieved 2022-12-07.
- ↑ Online, Tribune (2022-01-25). "Drug trafficking: Court convicts comedian De General, asks him to 'go and sin no more'". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-07.
- ↑ Olowolagba, Fikayo (2022-01-26). "I'm not a drug trafficker - Comedian De General speaks after release". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-07.
- ↑ Online, The Eagle (2022-01-26). "I'm not a drug dealer - Instagram comedian, De General -". The Eagle Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-07.
- ↑ "Arresting De General, a waste of taxpayers' money, says comedian Basketmouth". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-12. Retrieved 2022-12-07.
- ↑ "It's unfair for NDLEA to spare Abba Kyari, parade De General, Zinoleesky". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-28. Retrieved 2022-12-07.
- ↑ "Mr Macaroni reacts to comedian Iam Degeneral's arrest - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-12-07.