Diamond Ring (fíìmù ọdún 1998)
Diamond Ring | |
---|---|
Fáìlì:Diamond ring poster.jpeg | |
Adarí | Tade Ogidan |
Olùgbékalẹ̀ | Tade Ogidan |
Òǹkọ̀wé | Tade Ogidan |
Àwọn òṣèré | Bukky Ajayi Bimbo Akintola Tunji Bamishigbin Liz Benson Richard Mofe-Damijo |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | O.J. Productions OGD Pictures |
Déètì àgbéjáde |
|
Àkókò | 96 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English Language |
Diamond RIng jẹ́ fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó jáde ní ọdún 1988, èyí tí Tade Ogidan darí. Lára àwọn òṣèré tó kópa nínú fíìmù náà ni Richard Mofe Damijo, Teju Babyface, Sola Sobowale àti Bukky Ajayi.[1] Fíìmù yìí ní apá kìíní àti apá kejì.[2]
Àhunpọ̀ ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Diamond Ring jẹ́ ìtàn tó dá lórí àríyànjiyàn láàárín ẹ̀mí Mrs. Gladys àti àwọn mọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Chidi, ìyẹn XG. Chidi tó jẹ́ akẹ́kọ̀ó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga fẹ́ fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó tọ́ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn kan, èyí ló mú kí àwọn òbí rẹ̀, ìyẹn Chief àti Mrs. Ijeoma Dike lọ jalè. Wọ́n lọ jí òrùka olówó iyebíye lára òkú Mrs. Gladys. Èyí lówá mú kí ẹ̀mí Mrs. Gladys máa da Chidi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láàmú. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kú ní ẹyọkọ̀ọ̀kan. Àìsàn burúkú kan gbé Vhidi dè, tí wọn ò rí ìwòsàn sí. Ọ̀nà láti wá ìwòsàn fun ní wọ́n ń bá kiri, kí wọ́n tó mọ̀ pé wọ́n gbọdọ̀ dá òrùka olówó iyebíye tí wọ́n jí lára òkú Mrs. Gladys. [3] [4] [5]
Ìṣàgbéjáde
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n ṣàpejúwe Diamond Ring gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n ṣe dáadáa. [5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ 5.0 5.1 Alamu, Olagoke (2010-12-01). NARRATIVE AND STYLE IN NIGERIAN (NOLLYWOOD) FILMS. https://repository.kulib.kyoto-u.ac.jp/dspace/handle/2433/139277. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name ":0" defined multiple times with different content